Lọ́ọ̀tọ́ ni mo máa ń tètè bínú, tí mo sì ń ja ẹ̀ṣẹ́, ṣùgbọ́n mi ò kí ń ja ìjà ìgboro – Black Tito
Obinrin to yan iṣẹ ẹṣẹ jija laayo, Oluwole Bolatito Ebunoluwa, ti awọn ololufẹ rẹ mọ si ‘Black Tito’ ti ṣalaye fun BBC pe kii ṣe ọmọ ita nikan lo n ṣe iṣẹ naa gẹgẹ bii ero awọn eeyan.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọpọ awọn ti okiki wọn ti kan kaakiri agbaye nidi iṣẹ naa kii ṣe ọmọ ita.
O ni “Bariga ni wọn bi mi si, Bariga ni mo dagba si.”
“Awọn eeyan ma n sọ pe ọmọ ipata lo maa n ja ẹṣẹ ni tootọ, amọ awa kii ṣe ọmọ ipata o, ọmọ ti wọn bi nile ire, to si gbọ ẹkọ, oun ni awa.”
“Pupọ ninu awọn olowo yẹn lo maa ro pe ọmọ ita lo wa nidi ẹṣẹ, ṣugbọn kii ṣe ọmọ ita lo wa nidi ẹṣẹ.”
“Mayweather kii ṣe ọmọ ita, Anthony Josua kii ṣe ọmọ ita, Claressa Shields kii ṣe ọmọ ita, pupọ ninu wọn kii ṣe ọmọ ita....”

Oríṣun àwòrán, bbc
“Mama mi ko kọkọ fẹ ki n ja ẹṣẹ”
Bolatito ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe oun jẹ ẹni to maa n binu, oun kii ja ija igboro gẹgẹ bii ẹni to n ja ẹṣẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o ni mama oun ko kọkọ fẹ ki oun yan iṣẹ naa laayo latari irufẹ ẹni ti oun jẹ ṣaaju, amọ lẹyin ti oun bẹrẹ si n ja ẹṣẹ, oun kii binu mọ.

Oríṣun àwòrán, bbc
“A o kii n lo ogun oloro, akọṣẹmọṣẹ ni wa”
Ni ti oogu oloro lilo, Bolatito sọ pe oun kii ṣe bẹẹ.
O ni “Ki iṣan wa le le, awa kii lo oogun, idanilẹkọ ni a maa n ṣe ni gbogbo igba.”
“A o kii lo oogun, bẹe ni a o ki n gbe ogun oloro.”
Lẹyin naa lo pari ọrọ ọrọ rẹ pẹlu amọran pe ki awọn obi maṣẹ dẹkun ọmọ wọn obinrin to ba nifẹ si ẹṣẹ jija.



