Tinubu kì í ṣe ààrẹ Áfíríkà àkọ́kọ́ tó lu aago n'íléeṣẹ́ okòwò Amẹ́ríkà NASDAQ, iléeṣẹ́ ààrẹ tọrọ àforíjìn

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale/Facebook
Ileeṣẹ aarẹ Naijiria ti tọrọ aforijin lori iroyin kan to gbe jade pe Bola Tinubu ni aarẹ akọkọ lati ilẹ Afirika ti yoo lu agogo nileeṣẹ okowo Amẹrika, NASDAQ to wa niluu New York.
Ni ọjọ Iṣẹgun ni oludamọran pataki si aarẹ, Ajuri Ngelale sọ pe Tinubu ni aarẹ ilẹ Afirika akọkọ ti yoo ṣe iru rẹ.
Amọ, akosilẹ fihan pe aarẹ Tanzania tẹlẹ ri, Jakaya Kiwete, lu aago naa ni NASDAQ lọdun 2011.
Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti, Ngelale ni ileeṣẹ aarẹ kabamọ iroyin to kọkọ fi sita pe Tinubu lo kọkọ lu aago nileeṣẹ Amẹrika ọhun.
O ṣalaye pe ohun ti ẹnikan to mọ nipa ileeṣẹ okowo naa sọ fawọn lawọn tẹ lee.
Ngelale sọ pe ‘’a ti wa ri pe Tinubu kọ ni aarẹ akọkọ lati ilẹ Amẹrika ti yoo kọkọ ṣe iruẹ.
Ipade awọn olori orilẹede ajọ iṣokan agbaye, UNO ni ti Tinubu lọ ṣe lorilẹede Amẹrika to fi lo anfaani naa de ileeṣẹ okowo NASDAQ niluu New York.








