Kí ló ń fa gbas-gbos láàrín Olowo ìlú Owo àti Ojomo Oluda Ijebu-Owo lásìkò ọdún Igogo?

Oríṣun àwòrán, bbc
Kabiyesi Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, Ọba Ajibade Gbadegesin Ogunoye kẹta ti ni gbogbo aaye to yẹ ki oun ti ṣe adura ni oun yoo de lonii lai yọ ọkan silẹ.
Ẹni to jẹ akọwe si Ọlọwọ, Oloye Amos Aladeseye, ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba ṣe e lalaye pe ko si ohunkohun to n da ọba naa duro lati de gbogbo aaye to yẹ ko de loni nitori pe aṣa ati iṣe ilu Ọwọ to rọ mọ ọdun igogo lati igba iwaṣẹ ni ki Ọlọwọ o de awọn aaye kan lati ṣe adura.
Oloye naa lo n fesi si iwadi BBC Yoruba lori idi ti kabiyesi Ọjọmọ-lúdà ti ilu Ijebu-Owo ko fi ko ipa to yẹ ki o ko ninu ọdun igogo lọdun yii.
Aladeseye ni “a ko si ninu Ọba Ọjọmọ lati le mọ idi to fi ni oun ko nii kopa ninu ọdun igogo mọ.
“Lati ọdun kẹta sẹyin lo ti kọ lati ko ipa to yẹ ki o ko ni bi ko ṣe yọju si aafin Olowo, amọ eyi ko da Olowo duro lati lọ ṣe awọn adura to yẹ ki o ṣe nilu Ijebu-Owo nitori pe Olowo lo tẹ ilu naa do.
“A ko ṣe ọdun igogo lọdun to kọja nitori iṣẹlẹ iṣekupani to waye ninu ijọ aguda nilu Owo.
“O waa jẹ ohun iyalẹnu lọdun yii, ni nkan bi ọsẹ mẹta sẹyin, baa ṣe gbọ wipe Ojomo kọ iwe si ijọba ipinlẹ Ondo ki wọn wi fun Olowo ko ma ṣe wa silu Ijebu-Owo lasiko ọdun igogo, leyi to jẹ ohun ti ko dara to.
“Ipo Olowo gẹgẹ bii ẹni to tẹ gbogbo ilẹ Owo do fun-un laaye lati lọ ibikibi ti o ba wu u ati pe Olowo lo n fun Ojomo ni ọpa aṣẹ ko too di pe o gba agbega latọwọ ijọba.

Oríṣun àwòrán, bbc
“Amọ loni, Olowo yoo de awọn aaye mẹta to yẹ ki o ti ṣe adura nilu naa loni, to fimọ iwaju aafin Ojomo, ile Ajike to jẹ ọmọ Olowo ati aaye kan laarin ọja ilu naa.
“Bo tilẹ jẹ pe wọn ti mọ odi yi aaye ti Olowo yoo ti ṣe adura ninu ọja ilu Ijebu-Owo, a ti ri oniṣẹ mẹta lati ilu naa to waa wi fun Olowo pe wọn yoo ṣi ilẹkun odi naa fun-un.”
Oloye Aladeseye fi kun pe gbogbo eto ọun ni yoo lo ni irọwọ-rọsẹ lonii ni bii kabiyesi Olowo ṣe korira iWar janduku leyi to mu ki o beere fun aabo to daju latọwọ ijoba ti wọn si ti pin awọn ẹṣọ aabo kaakiri gbogbo ilu.
Kíni ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú?
Ni nkan bii ọsẹ mẹrin sẹyin ni iroyin gba ori ẹrọ ayeluja pe Kabiyesi Ojomoluda tilu Ijebu-Owo, Ọba Kofoworola Oladoyinbo, kọwe si gomina ipinlẹ Ondo ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ pe ki ijọba paa laṣẹ fun Olowo atawọn eyan rẹ lati jinna silu Ijebu-Owo ninu eto ọdun igogo nitori awọn ko ni nkankan ṣe pẹlu ọdun naa.
Ninu iwe ọun ni ọba naa ti wi pe “mo fẹẹ pe akiyesi ijọba si atẹjade eto ọdun igogo ti awọn ara ilu Owo ṣe ti wọn si fi orukọ mi si lai beere ati lai gba aṣe lọwọ mi leyi ti mo ri bii igbiyanju lati da omi alaafia ijọba ibilẹ Owo ru.
“Bo tilẹ jẹ pe mo ki wọn ku oriire ọdun, mo rọ ijọba ki o pawọn laṣẹ lati ṣe ọdun ọun niwọnba aaye to wa labẹ Olowo ti ko de ilu Ijebu-Owo rara.
“Ilu wa jẹ ololufẹ alaafia to si jẹ ọkan lara awọn ilu mẹsan to wa nijọba ibilẹ Owo.
“A ti ri oun ti laasigbo le da silẹ laarin ilu meji, paapaa julọ ohun to ṣẹlẹ nilu Ikare laipẹ, ti a ko si fẹ ki iru rẹ ṣẹlẹ nilu wa.”
Iwe yi lo fa awuyewuye lọtun losi ko too dipe Oba Ojomo waa jade lori ẹrọ ibaradọrẹ facebook lati sọrọ gbe iwe ọun lẹyin.
Irinkerido akọroyin BBC News Yoruba kaakiri ilu Owo fihan pe awọn agbofinro loriṣiriṣi lo waa kaakiri ilu Owo ati Ijebu-Owo lati le pese abo ki wọn si dena rukerudo to le jẹyọ nibi abẹwo Olowo silu Ijebu-Owo.
Ǹjẹ́ ẹ̀yin ti gbọ́ nípa ọdún Igogo níbi tí ọkùnrin ti máa ń múra bí obìnrin?

Ọdun Igogo jẹ ọkan lara ọdun ibilẹ to gbajumọ julọ nipinlẹ Ondo ati ni iwọ-oorun-guusu orilẹ ede Naijiria.
Ọdun Igogo ti wọn bẹrẹ rẹ ni ẹgbẹta ọdun o le diẹ sẹyin, ni wọn n ṣe ni iranti ayaba kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Oronsen.
Ọrọnṣẹn ni wọn juwe rẹ gẹgẹ bi alagbara obinrin to si jẹ aayo ọkọ rẹ, Ọba Rẹ̀nrẹ̀ngẹnjẹ̀n, ẹni to jẹ ogboju ọdẹ ati jagunjagun.
Ọrọnṣen ni o sa kuro laafin lẹyin ti awọn orogun rẹ ṣe awọn eewọ mẹta to ni oun ko gbọdọ foju ri lakoko ti ọkọ wọn lọ jagun.
Itan fi ye wa pe nibi igbiyanju lati wa arẹwa yii ko si lee pada si aafin lo ti wi fun awọn to n wa a pe oun ko le pada si aafin pẹlu wọn mọ nitori oun ti pari iṣẹ toun waa ṣe nibẹ.
Wọn ni ko too di pe obinrin alagbara naa poora mọ wọn loju lo wi fun wọn pe ki wọn maa ṣe ọdun naa ni iranti oun, ti oun yoo si maa wa pẹlu wọn ninu ẹmi.




Lati igba naa di oni, ọdun naa lo n gbajumọ sii lojoojumọ tawọn ero si maa n waa woo lati origun mẹrẹrin agbaye.
Orukọ ti wọn pe ọdun naa loni lo jẹyọ latara pe agogo nikan ni wọn maa n lu lakoko ọdun naa leyii to mu ki wọn maa pee ni ọdun agogo ki awọn eeyan o too yii pada si ọdun Igogo.
Lakoko ọdun ọhun, Ọba Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, awọn ijoye rẹ, ati gbogbo ọkunrin to ba fẹẹ kopa to jọju ninu ọdun naa ni yoo wọ aṣọ bi obinrin ti wọn yoo si dirun bi obinrin.
Ọdun ọhun ti wọn n ṣe fun ọjọ mẹtadinlogun lo ni oriṣiriṣi eto bii iwọde awọn gende ọkunrin pẹlu atori lọwọ ti wọn pe ni ayóóyoò, ijakadi awọn ọdọ laafin (ùjà ugbáma), ọjọ kan laarin ọdun ti kabiyesi yoo wọ inu ọja (ùgbátẹ), jijo kabiyesi kaakiri awọn oriko kan laarin ilu ati awọn nkan meremere miran.















