Ẹ̀mí bọ́́, dúkìá ṣòfò lẹ́́yìn tí ìjà ilẹ̀ bẹ́ sílẹ̀ láàrín ìlú Ilobu àti Ifon ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun kede lọjọ Isẹgun pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi kan lori ikọlu to waye ni agbagbe Okanala, ni ijọba ibilẹ Irepodun lọjọ Aiku ọsẹ yii.
Oloogbe Ibrahim Kudus ni awọn agbebọn yinbọn pa lasiko ti ṣe ikọlu si ile rẹ, ti wọn si tun gbe si ninu ọkọ ayọkẹlẹ, ti wọn si dana sun.
Ileeṣẹ BBC News Yoruba ṣe abẹwo si awọn ilu mejeeji lati mọ ohun to sokunfa ija to gba ẹmi eeyan kan, ti ọpọlọpọ dukia si ṣofo.
Ọmọọba Akinjide Adelaja, akọwe ẹgbẹ ọmọ ilu Ifon, salaye pe ibẹẹrẹ ọrọ ni pe awọn ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria fẹ gbe akanṣe isẹ wa si ilu, ti wọn si lọ ba Ọba ilu ilobu sugbọn ori ilẹ ilu Ifon ni wọn pese fun awọn ologun lati ṣe isẹ akanṣe wọn.

“Ori ilẹ awọn ara ifororo ni awọn ara ilobu pese fun awọn ologun lai sọ fun wọn tẹlẹ pe ibẹ ni wọn gbe isẹ akanṣe si.
“Nigba ti a ri awọn eeyan ni bẹ a kesi ileeṣẹ ologun pe o yẹ ki wọn bere lọwọ oloju ki wọn to ṣe yii.
“Awa ati ileeṣẹ ologun ti n fi ọrọ ye ara wa, a fi bi awọn ara ilu Ilobu ṣe gba sori, ti ọrọ kabakungbe si bẹrẹ, ti wọn si fẹ dori itan kodo, eyi lo ba awọn ifon ninu jẹ.”
Awọn ilu Ifon ni parọ mọ wa pe ileeṣẹ ologun fẹ gba ilẹ lọwọ wọn- Ọtun Ijagun Ilobu
Amofin Ogunsola, Ọtun Jagun Ilu Ilobu ba ileeṣẹ BBC News sọrọ pe awọn ilu Ifon n parọ mọ Ilu Ilobu pe ọmọ wọn, iyẹn Ọga ologun lorilẹede Naijiria, Taoreed Lagbaja ko ọmọ ologun wa lati wa gba ilẹ lọwọ wọn.
“Ọmọ wa Ọga ologun ko ti wa si Ilu Ilobu lati igba ti di ọga ologun, irọ ti wọn pa mọ wa yii ba lọkan jẹ.
“Ilẹ ti wọn sọ yii gan ko ki n ṣe ilẹ ilu Ifon, ilẹ ilu Ilobu lo jẹ, awọn ti wọn dako sibẹ, Ọba ilu ilobu lo fi wọn si bẹ.
“Ọdun 1917 ti ni ija yii ti bẹrẹ lati aye ijọba oyinbo, ti Captain Woss si wa ọna abayọ si ija sugbọn Ọba OIufọn Banke Osa Akinyioye, lọdun 1945 yi adehun pada to si bọ si ori ilẹ Ilobu, ti Ọba ilu Ilubo si pe wọn lẹjọ.”
Ọrọ lẹnu awọn agba oye mejeeji, ẹ wo fọnran yii.













