Oní Márúwá tó dá N15M padà kọ ìyàwó mẹ́rin tí wọ́n fun ní Kano

Oríṣun àwòrán, @abdullahayofel/daily trust
Awakọ kẹkẹ maruwa to da miliọnu marundinlogun naira to ri he ninu ọkọ rẹ pada fun ẹni to ni, Auwalu Salisu, ti kọ iyawo mẹrin ti ẹgbẹ afọmọfọkọ kan fun un nipinlẹ Kano.
Ẹgbẹ naa ni awọn bun ọdọkunrin ẹni ọidun mejilelogun ọhun ni awọn obinrin naa lati fi ẹmi imoore han si un dodo to ṣe nipa dida owo naa pada.
Alhaji Mukhtar Inuwa, to jẹ alaga ẹgbẹ afọmọfọkọ naa sọ lori ẹro redio kan pe oun bun ọdọkunrin naa ni odidi obinrin mẹrin, ninu eyii ti ọmọ oun meji wa lara wọn.
Amọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC, Auwalu sọ pe iyawo kọ ni ọrọ oun kan bayii, bi ko ṣe bi oun ṣe maa pada sile ẹkọ.
O ni “Mo gbọ nipa ẹbun naa bi ọpọ eeyan ṣe n sọ kaakiri amọ idahun mi lọwọ yii ni pe iyawo kọ ni ọrọ mi kan bayii.”
“Mo fẹ pada sile ẹkọ, ki n kọkọ pari ẹkọ mi na ki n to maa ronu nipa ọrọ iyawo.”
Ṣaaju ni oniṣowo ọmọ ilẹ Chad kan ti bẹ ilu Kano wo lati ra ọja ti Auwalu si gbe lọ si ọja Bata.
Asiko ti Auwalu gbe oniṣowo naa ni oniṣowo ọhun gbagbe obitibiti owo naa sinu kẹkẹ Maruwa rẹ.
Wayi o, lati igba to ti da owo naa pada fun ọkunrin ọhun ni Auwalu ti di olorukọ rere lawujọ, ti ọpọ ọmọ Naijiria si n kan saara si i fun ododo ati iwa ọmọluabi rẹ.
Ẹgbẹ́ afọmọfọ́kọ fẹ́ fún ọkùnrin oní Márúwá tó dá N15M padà ní Ìyàwó mẹ́rin fún ìdúpẹ́

Oríṣun àwòrán, DailyTrust
Ẹgbẹ afomọfọkọ nipinlẹ Kano, ti ọpọ mọ si Mai Dalilin Aure, ni o fẹ fun ọkunrin oni maruwa to da milọnu mẹdogun naira pada fun eeyan kan to gba rẹ sinu maruwa rẹ ni obinrin mẹrin ko fi ṣe aya.
Ti a ko ba gbagbe, Auwalu Saliu, ẹni ọdun mejilelogun lo di ilu mọka lẹyin to ri milọnu mẹdogun naira pẹlu owo ilẹ okere CFA, to si dapa fun ẹni to ni, to wa lati orilẹede Chad.
Lati igba naa ni ọpọ ti n kan sara si ọdọmọkunrin yii, to si n gba ọpọlọpọ ẹbun lọwọ ijọba, ẹgbẹ ati awọn eeyan mi to wu lori.
Lati le fi ẹmi imore han si ọkunrin yii, ẹgbẹ afọmọfọkọ yii pinnu pe awọn naa yoo fun ni iyawo mẹrin, ti yoo si nawọ mu eyi to wa hu ninu awọn mẹwaa ti wọn ba gbe kalẹ.
Lasiko to n ileeṣẹ iroyin Freedom sọrọ nipinlẹ Kano, Alaga ẹgbẹ naa, Alhaji Mukhatar Inuwa Yakasai ni ọmọ oun obinrin meji lo wa lara obinrin mẹwaa ti seto fun ọkunrin naa.
Yakasai ni iwa inu re ti ọkunrin naa lo jẹ ki awọn fẹ da laare.
“Ọkunrin ni iwa Anọbi Muhammad, o ṣe finu tọ. Idi ti a fi fẹ da lọla re.
“Ninu obinrin mẹwaa ti yoo ti mu mẹrin. Meji wọn jẹ ọmọ ti mo bi.”
‘’Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń sọ fún mi pé mi ò lè lówó mọ́ láyé lẹ́yìn tí mo dá N15m èrò tí mo gbé padà’’

Oríṣun àwòrán, Auwal
Auwal Salisu to da miliọnu mẹẹdogun ti ero kan gbagbe sinu kẹkẹ Marwa rẹ ti sọ pe ni ṣe lawọn ọrẹ oun sọrọ s’oun pe owo o le lowo mọ laye tori oun da owo naa pada.
Auwal ni wọn sọ foun pe oun ti padanu anfaani kan ṣoṣo ti oun ni laye lati di ọlọla.
Ọpọ eeyan lo ti sọrọ lori iṣẹlẹ yii to waye ni opin ọsẹ to lọ niluu Kano.
Ọgunlọgọ eeyan lo gboṣuba rabandẹ fun Auwal pe o ṣe olootọ ati ẹni to ṣe e mu yangan lawujọ pẹlu bi o ti da owo naa pada, bo tilẹ jẹ pe awọn kan gbagbọ pe ni ṣe lo yẹ ki Auwal fi owo naa ṣe ara rindin.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Auwal ni ibẹru Ọlọrun ti oun ati idile oun ni lo jẹ ki oun da owo naa pada tori ko si ounjẹ nile awọn lasiko naa.
Bo tilẹ jẹ pe Auwal ati ẹbi rẹ wa ninu aini, mama rẹ sọ fun un pe ki o lọ wa ẹni to lowo naa ri ki o si da owo ọhun pada.
Ẹgbẹrun lọna irinwo ni oniṣowo orilẹede Chad to ni owo naa fun un lẹyin to da owo yii pada tan.
Amọ, ninu ifọrọwerọ ti o ṣẹṣẹ ṣe pẹlu iwe iroyin Daily Trust, Auwal ni ni ṣe lawọn ọrẹ oun n sọ pe oun ti ya were pẹlu bi oun ṣe da owo naa pada.
Auwal ni ‘’ọpọ awọn ọrọ mi ni wọn si n binu si mi tori mo da owo naa pada.
Ṣugbọn ni temi, mo ti ṣe ohun ti ọkan mi ni ki n ṣe, ẹri ọkan mi si dami lare.
Wọn ni mi o mọ ohun ti mo n ṣe wi pe mi o le lowo mọ laye.
Mo kan dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ọpọ eeyan lo wa mi wale lati wa ki mi ku oriire atawọn obi mi lori iwa rere ti mo hu.’’
‘’Kò sí oúnjẹ nílé wa nígbà tí èrò kan gbàgbé N15m sínú kẹ̀kẹ́ Marwa mi ṣùgbọ́n...’’

Oríṣun àwòrán, @Awuil
Iwa lẹwa ọmọ eniyan gẹgẹ bi Yoruba ṣe maa n wi.
ọpọ eeyan nipinlẹ Kano lo si n gbe oṣuba rabandẹ fun awakẹkẹ Marwa kan, Auwal Salisu to da miliọnu mẹẹdogun owo naira ti ero kan gbagbe sinu kẹkẹ rẹ pada.
Ọkunrin oniṣowo kan, Alhaji Ibrahim Barka to lọ si Kano lati ra awọn nkan nibi ti Auwal ti gbe e lati agbegbe Badawa niluu Kano lọ si ọjọ Bata.
Miliọnu mẹwaa owo CFA ati miliọnu mẹta din diẹ lo wa lara Auwal nigba ti o wọ kẹkẹ Auwal.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Auwal ni ibẹru Ọlọrun ti oun ati idile oun ni lo jẹ ki oun da owo naa pada tori ko si ounjẹ nile awọn lasiko naa.
O ni oun ko gbe ero miiran lẹyin ti Barka sọkalẹ ninu kẹkẹ oun.
Auwal ni niṣe loun lọ duro si ibikan lati nun kẹkẹ oun nun ki oun ri owo naa.
‘’Mo sare lọ si ibi ti ero to ni owo naa ti sọkalẹ, amọ, mi o ba nibẹ mọ.
Lẹyin naa ni mo gbe owo yii lọ si ile, lọjọ Abamẹta ni mo gbọ ikede lori redio Arewa pe ẹni to ni owo naa ti n wa a.
Lọgan ni mo gbe owo naa lọ si ileeṣẹ redio yii pe ki wọn ba mi gbe owo naa fun ẹni to lowo,’’ Auwal lo sọ bẹẹ.
Mallama Hadiza Mohammed to jẹ iya Auwal sọ fun BBC pe garri aadọjọ naira(N150) ati kuli kuli aadọta naira(N50) ni ounjẹ ti gbogbo idile awọn lọjọ naa tori awọn ko ni ounjẹ nile.
Hadiza ni ibẹru Ọlọrun ni ko jẹ kawọn kọwọ bọ owo naa tori kii ṣe awọn lo ni owo naa.
O fikun ọrọ rẹ pe Auwal ọmọ oun ni ẹkọ ile lo jẹ ki o huwa bayẹn, bi bẹẹ kọọ, ko ba ma da owo naa pada.
Obinrin naa dupẹ lọwọ ẹlẹyinju aanu to fi baagi raisi mẹta ta ẹbi awọn lọrẹ lati igba Auwal ti da owo naa pada.

Oríṣun àwòrán, @Awuil
Auwal ni tiẹ sọ pe ohun to wu oun lọkan ni lati pada sile ẹkọ tori iwe kẹta nile ẹkọ girama loun ti duro tẹlẹ.
O ni ẹlẹyinju aanu kan ti sọ pe oun yoo ran oun ló si ile ẹkọ pada.
Kẹkẹ ti Auwal n wa gan an kii ṣe tiẹ, ọrẹ rẹ lo ni kẹkẹ naa.
Auwal tun sọ pe irọ nla ni iroyin tawọn eeyan kan n gbe kiri lori ayelujara pe awọn eeyan nla kan ti fun oun nile, kẹkẹ atawọn nkan mii.

Oríṣun àwòrán, @Awuil
O ni ọkunrin to ni owo naa lo bun oun ni ẹgbẹrun lọna irinwo naira(N400,000) ninu owo ti oun da pada.
Ẹbi oniṣowo orilẹede Chad to ni owo naa, Musa Hassan dupẹ lọwọ Auwal lori bi o ti da owo ọhun pada.
Hassan ni ohun Auwal ṣe tumọ si pe eeyan rere ko le tan laye laelae.
O ni ẹbi Auwal ko tiẹ lounjẹ nile nigba to ri owo yii eleyii to tumọ si pe ọmó to gba ẹkọ nii ṣe.
Hassan pẹlu omije loju sọ pe oun ati ẹgbọn oun ro pe owo naa tilọ lẹyin to gbagbe rẹ sinu kẹkẹ.















