Iná sọ níléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe ike ní ìpínlẹ̀ Eko, ọ̀pọ̀ sá àsálà fún ẹ̀mí wọn

Ibi ti ijamba ina naa ti waye

Ìjàm̀bá iná kan ti wáyé ní iléeṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣe ike ní ìpínlẹ̀ Eko.

Agbègbè Ilupeju, tó jẹ́ agbègbè tí àwọn iléeṣẹ́ pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ náà ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣalaye pe nǹkan bí aago mẹ́fà idájí ọjọ́ Àbámẹ́ta ni iná náà bẹ̀rẹ̀ tó sì ń jó gidi gan.

Gbogbo òrùlé ilé náà ni ìjàm̀bá iná ti bàjẹ́ tí èéfín sì gba gbogbo àdúgbò.

Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná àtàwọn òṣìṣẹ́ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti wà níbẹ̀ láti pa iná ọ̀hún.

Ìròyìn ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìfowópamọ́ àtàwọn ilé ìjọsìn ló wà ní agbègbè ilé iṣẹ́ ọ̀hún.

Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, kò sí ìròyìn pé ẹnìkankan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tàbí farapa nínú ìjàm̀bá iná náà.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí ìjàm̀bá iná kan wáyé ní ilé ìtura IBIS ní òpópónà pápákọ̀ òfurufú ní ìpínlẹ̀ Eko kan náà.

Ninu atẹjade kan ti adari ileeṣe to nn ri si ina nipinlẹ Eko, Adeseye Margaret fi lede, o ni nnkan bii aago meje abọ owurọ ọjọ Abamẹta ni ọrọ naa to awọn leti.

O ni abala ti wọn n ko awọn eroja pamọ si nileeṣẹ ni ina ọhun ti jo gurugu.

O pari ọrọ rẹ pe ko si ẹmi kanbkan to a iṣẹlẹ ọhun lọ.