Ọmọ tí ìfun rẹ̀ di àwátì nílé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ jáde láyé

Oríṣun àwòrán, LAGOSSTATEGOVT
Ọmọ ọdún méjìlá tí ìyá rẹ̀ figbe tá nígbà kan pé àwọn ìfun ọmọ òun pòórà ní ilé ìwòsàn ìjọba ti ìpínlẹ̀ Eko, Adebola Akin-Bright ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.
Ìyá ọmọ náà, Abiodun Deborah ló fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn akọ̀ròyìn létí lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Ọ̀kan lára àwọn ẹbí ọmọ náà sọ fún BBC Pidgin pé ọmọ náà ń ṣẹ̀jẹ̀ láti inú kó tó dákẹ́.
Ó ní wọ́n sáré dìgbàdìgbà lọ sí ẹ̀ka tó ń mójútó àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá burú gidi ṣùgbọ́n tí ẹ̀pa kò bóró mọ́.
Ilé ìwòsàn olùkọ́ni ti ìjọba ìpínlẹ̀ Eko, LASUTH ni ọmọ náà dákẹ́ sí.
Debola Akin-Bright ti ń gba ìtọ́jú, tó sì ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ abẹ níbi tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìfun rẹ̀ kò sí nínú rẹ̀ mọ́.
Ní ilé ìwòsàn tó jẹ́ ti aládani kan ni wọ́n ti ń ṣe ìtọ́jú Debola, tó sì ti ṣe iṣẹ́ abẹ níbẹ̀ kí wọ́n tó gbe lọ sí ilé ìwòsàn ti ìjọba Eko, LASUTH.
Ìpapòdà ọmọ náà ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ilé aṣòfin Eko ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìwòsàn LASUTH láti mọ irú ìtọ́jú tí wọ́n ń fún ọmọ náà lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Oríṣun àwòrán, @lasuthikeja
Olórí ọmọ ilé tó pọ̀jù lọ, Nojeem Adams ló ṣaájú àwọn ọmọ ilé méje tó ṣe àbẹ̀wò sí ọmọ náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi léde lórí ayélujára X.
Wọ́n ní àbẹ̀wò náà wáyé láti ṣe ìwádìí ẹ̀sùn tí ìyá ọmọ náà fi kàn pé wọn kò rí ìfun ọmọ òun mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fun.
Nojeem ní gbogbo àbọ̀ ìwádìí àwọn ni àwọn máa fi léde ní kété tí àwọn bá parí rẹ̀.
Nígbà tí ìyá ọmọ náà ń bá BBC sọ̀rọ̀, Deborah Abiodun ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun pé àwọn oníṣẹ́ ètò ìlera kò mọ bí ìfun ọmọ ṣe pòórá lásìkò iṣẹ́ abẹ.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ṣáájú ṣàbẹ̀wò sí ọmọ náà nílé ìwòsàn tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti gbé gbogbo owó ilé ìwòsàn rẹ̀.
Sanwo-Olu ṣàbẹ̀wò sí LASUTH lọ́jọ́ Àìkú.
Agbẹnusọ gómìnà, Gbenga Akosile lórí ayélujára X sọ pé gómìnà Sanwo-Olu ti ṣetán láti san gbogbo owó ìwòsàn ọmọ náà àti pé gbogbo nǹkan tí yóò mú ara ọmọ náà dá ni àwọn máa ṣe.
Ilé ìwòsàn LASUTH ní lẹ́yìn tí ilé ìwòsàn aládani ti ṣe iṣẹ́ abẹ méjì fún ọmọ náà ni wọ́n tó gbe wá sí ilé ìwòsàn àwọn.















