Kí ló ń fa wàhálà láàrín Ìlú Ifon àti Ìlú Ilobu ní Ìpínlẹ̀ Osun?

Aworan aafin Ọba ati ọkọ ti wọn dana sun

Lati ọdun 2005 ni ọrọ ilẹ ti n fa wahala laarin ilu Ifon ati Ilobu nipinlẹ Osun, to si gba ẹmi eeyan mẹsan an, ti ọpọlọpọ dukia si sofo lọdun naa.

Lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdún 2023 ni ija miiran bẹrẹ laarin awọn ìlu naa lẹyin ti awọn eeyan ilu Ifon-osun pariwo síta pe awọn ko ni gba ki ilu Ilobu fi ọwọ agbara gba awọn loju.

Oun to fa ariwo yi, ti a ri gbọ ni bii Ọga Ologun Naijiria, Taoheed Lagbaja se ran awọn ọmọ ogun kan wa si ijọba Ibile Orolu tí wọ́n sì wa wo awọn ilẹ kan to jẹ́ ti Ilu Ifon-osun.

Ti a ko ba gbagbe, Ọga Ologun ni orile-ede Naijiria jẹ ọmọ bíbí Ilu Ilobu ni ìjọba ìbilẹ Irepodun nipinlẹ Osun.

Eyi lo mu ki awọn ọmọ Ilu Ifon-osun ṣe ìwọde ni Ọjọ́ Kokandinlogbon Oṣu Kẹjọ Ọdun 2023.

Sugbọn kaka ki alaafia ko jọba nilu Mejeji lo tún wa le koko sì.

Lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹsan an ọdun 2023 ni awọ mii bẹrẹ laarin ilu mejeeji eyi to mu ki idile kan padanu ọmọ ọdun mọkanlelogun to sẹsẹ wọ ile ẹkọ gbogbo nise to wa niluu Ede nipinlẹ Osun.

Isẹlẹ naa tesiwaju ni ọjọ Kẹtadínlogun oṣu kẹsan yii, ti dukia si sofo.

Eyi lo mu ki Gomina Ademola Adeleke ko kede ofin ko nile ko gbele lati agogo mẹ́jọ alẹ sí agogo Mẹfa owuro ni awọn ilu naa.

Ikọ BBC YORUBA ṣe abewo sì ilu Ilobu ati ilu Ifon-osun lati mọ ohun to sẹlẹ nílùú Mejeji

Sugbọn Iyalẹnu lo jẹ pe a ko ri ẹnikẹni lati ba wa sọrọ nin agbegbe naa.