Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ níbi ìfẹ̀hónúhàn l'Abeokuta lórí ikú tó pa Mohbad

Ẹsẹ ko gba ero lonii ọjọ Iṣẹgun tii ṣe Tusidee niluu Abẹokuta nigba ti awọn ọdọ, paapaa awọn ololufẹ orin takasufe jafe lọpọ yanturu lati ṣe iwọde ifẹhonuhan alaafia lori iku Ilerioluwa Ọladimeji Alọba ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mohbad.
Gbagede ere idaraya ti wọn n pe ni Skating Ground, eyi to wa ladojukọ Post Office, Ibara niluu Abẹokuta ni iwọde naa ti waye.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, nnkan bi aago mẹwaa aarọ ni eto ọhun bẹrẹ, nibi ti awọn ọdọ ti n pe fun idajọ ododo lori iku Mohbad naa.
Ọkan pataki lara awọn olorin ọmọ bibi ilu Abẹokuta nni, Adeyinka Adeboye ti ọpọ awọn eeyan mọ si Boye Best lo lewaju iwọde ifẹhonuhan ọhun.
Nibẹ ni wọn ti rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ekoo labẹ Gomina Babajide Sanwo-Olu, ọga ọlọpaa orileede Naijiria, Kayọde Ẹgbẹtokun lati ma ṣe jẹ ki iku Mohbad lọ lasan.
Boye Best ni gbogbo awọn to lọwọ ninu iku oloogbe naa ni wọn gbọdọ foju winna ofin orileede Naijiria, nitori pe ọkan pataki lara awọn ti yoo gbe ogo orileede yii soke ni wọn da ẹmi rẹ legbodo lojiji.
Ko din ni ẹgbẹrun meji awọn ọdọ ti wọn korajọ lati fẹhonuhan lonii, ti awọn oṣiṣẹ agbofinro si wa nibẹ lati daabobo awọn eeyan.
Wahala bẹ silẹ nibi ifẹhonuhan naa
Niṣe lọrọ di boolọ o yago lọna nigba ti awọn ọdọ kan bẹrẹ ija, ti wọn si da iwọde ifẹhonuhan alaafia naa ru, eyi to mu k'awọn ọlọpaa dide si wọn.
Ko si nnkan meji ti a gbọ pe o fa a, ju bi wọn ṣe sọ pe ẹnikan tẹ ọkan lara awọn ti wọn jọ n fẹhonuhan naa mọlẹ, tiyẹn si sọ ọ di ija.
BBC YORUBA gbọ pe ki oloju too ṣe ẹ, igbaju ati igbamu ti bẹrẹ sii tẹlẹ ara wọn, to si di ariwo nla.

Oríṣun àwòrán, AP

Iṣẹlẹ ọhun la gbọ pe o mu ki iwọde ifẹhonuhan han naa foriṣanpọn ni nnkan bi aago mejila ku isẹju mẹẹdogun.
Bi kii ba a ṣe awọn ọlọpaa ti wọn sare debẹ lati pana iṣẹlẹ ọhun, wọn ni ṣe lọrọ ọhun ko ba gba ibomiran yọ.
Fun bi ogun iṣẹju ni wọn sọ pe wahala naa fi ṣẹlẹ, ko to di pe onikaluku bẹrẹ sii gba ile rẹ lọ.
Wọn ni pẹlu ibinu ni Boye Best fi kuro nibi iwọde ifẹhonuhan ọhun, to si l'awọn ọdọ ko farabalẹ lati jẹ ki ipinnu ati erongba wọn wa si imuṣẹ.
Wọn ni Boye Best ko duro lati wọ mọto rẹ to gbe lọ sibẹ, nigba to fibinu kuro. Lara awọn ti wọn jọ lọ la gbọ pe wọn gbe mọto tẹle lẹyin lati pade rẹ Quarry Road, nibi to fi ẹsẹ rin gba
Gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla sọrọ lo ja si pabo titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.















