Ipò Aláàfin kì í ṣe fún títà- Seyi Makinde

Aworan Aga Ọba Alaafin ati Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde/Alaafin Oyo

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti ke si awọn ọmọ ilu ati awọn ọmọọba to n jijadu fun ipo Alaafin Ọyọ lati dẹkun ilepa wọn nitori ipo naa kii ṣe ohun ti ẹnikẹni le fi owo ra.

Makinde ti o sọ ọrọ naa nibi iṣide opopona tuntun Ọyọ-Iṣẹyin lọjọ Ẹti fi kun ọrọ rẹ pe ipo Alaafin ko si fun karakata.

O ni, "Mo ke si awọn ọmọọba ati awọn mii to nifẹ si ipo Alaafin Ọyọ lati jawọ ninu ijijadu lori ẹni ti yoo gun ori itẹ naa.

Ipo ọwọ naa ko ni bọ si ọwọ ẹnikẹni ti o ba fẹ fi owo raa, ẹnikẹni ti o ba si gbiyanju lati taa yoo kan idin ninu iyọ".

Ipo Alaafin Ọyọ ṣi silẹ lẹyin ipapoda Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi III, ti gbesẹ ninu oṣu kẹrin ọdun 2022.

Lẹyin ipapoda Ọba Adeyẹmi si ni ọpọlọpọ awọn ọmọọba ati idile to n fi ọba jẹ ti bẹrẹ ijijadu lori ẹni ti o kan lati de ade ọba.

Lọwọlọwọ bayii, ikede ti Gomina Makinde ni gbogbo eeyan ilu n reti lati sọ ẹni ti yoo jẹ Alaafin tuntun.