Davido, Falz, Zlatan darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀dọ́ láti bu ọlá ìkẹyìn fún Mohbad

Awọn gbajugbaja olorin takasufe lorilẹede Naijiria lo peju si ibi eto iranti ati iwọde ti awọn ọdọ ṣe fun gbajugba olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba to di oloogbe lọsẹ to kọja.
David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido pẹlu awọn eekan bi Falz ati Zlatan lo darapọ mọ awọn ọdọ ni agbegbe Victoria Island nipinlẹ Eko.
Mohbad lo jade laye ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni ipinlẹ, ti iku rẹ si ti fa ọpọlọpọ awuyewuye.

Lati igba ti Mohbad ti jade laye ni awọn ọdọ lorilẹede ti n bere fun idajọ odoodo lori ohun to ṣekupa Mohbad, ti iwọde si waye kaakiri orilẹede Naijiria.
Ago meje kọja isẹju mejidinlogun ni iwọde naa bẹrẹ, ti ogunlọgọ ọdọ si farahan lati bu ọla ikẹyin olorin naa.
Irufẹ iwọde yii naa waye niluu Gẹẹsi ni Peckham, ti gbogbo awọn eeyan si n kọrin oloogbe naa ninu fọnran kan to wa lori ayelujara.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Àwọn Iléeṣẹ́ Rédíò kan ti fi òfin de lílo orin Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Instagram/Naira Marley
Awuyewuye to rọ mọ ipapoda olorin takasufee, Ilerioluwa Oladimeji Aloba, ti ọpọ eeyan mọ si "Mohbad" tun ti fẹju sii o.
L'ọjọ Aje ni awọn oludasilẹ ileeṣe redio ni ẹkun iwọorun guusu fi aṣẹ lelẹ ti wọn si kede wi pe gbogbo orin Naira Marley ati awọn isọgbe rẹ ti di eewọ lori ikanni redio wọn.
Ileeṣẹ orin, ‘Marlian Music’ ni Mohbad wa tẹlẹri nigba aye rẹ, ki ọrọ to ṣe bi ọrọ laarin oun ati Naira Marley. Lẹyin ti wọn tuka tan ni iroyin ati awọn ọrọ ikẹyin Mohbad fi idi rẹ mule wi pe niṣe ni Marley n dunkoko mọ oloogbe naa titi ti ọlọjọ fi de.
Redio akọkọ ti a ri pe o kede ofin ti wọn fi de gbogbo orin Naira Marley ni 'Splash ati Lagelu FM' niluu Ibadan.
Atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ naa fi ranṣẹ si gbogbo oṣiṣẹ wọn tọka rẹ wi pe iwadii to n lọ lọwọ lori iku Mohbad ati ofintoto iwa ọdaran ti ọlọpaa n ṣe lọwọ lo mu ki ofin de gbogbo orin Naira Marley lori redio.
Gbogbo oṣiṣẹ ileeṣẹ redio naa ni wọn fi to leti wi pe lẹsẹkẹsẹ ni ofin ti wọn fi de awọn orin naa ti fi idi mulẹ.
Lori afẹfẹ ni oludasilẹ ileeṣẹ redio 'Agidigbo Fm' Ibadan, Alhaji Oriyọmi Hamzat ti kede pe ileeṣẹ naa ko ni lo orin Naira Marley mọ ni akoko yii.
Lori eto kan to n ṣe lọwọ lọjọ Aje, Hamzat ni,
"A paa laṣẹ lati oni lọ, gbogbo orin ti o ba jade lọdọ awọn Marlian patapata, o di eewọ nileeṣẹ redio Agidigbo lati oni lọ.
Awa ko sọ pe awọn ni wọn paa o, ṣugbọn gbogbo orin ti o ba jade lati ọdọ awọn Marlian patapata, a ko gbudọ loo mọ nileeṣẹ redio Agidigbo lati oni lọ."












