Òní ló pé ọjọ́ méje tí Mohbad jáde láyé, ẹ wo ibí tí ọ̀rọ̀ dé dúró

Aworan Ilerioluwa Aloba

Oríṣun àwòrán, Instagram/iamMohbad/STINOMIX

Ọjọ kejila oṣu kẹsan an ọdun 2023 ni gbajugbaja olorin takasufe, Ilerioluwa Aloba, ẹni ti ọpọ mọ si Mohbad jade laye, ti okiki si kan lori ọna to gba jade laye.

Ọjọ keji ti Mohbad ku ni wọn gbe wọle kalẹ niluu Ikorodu, ti ẹsẹ ko gba ero nibi eto isinku rẹ.

Ọpọ awọn olorin ati alawada lo wa ni ibẹ lọsẹ to kọja.

Bakan naa ni ọpọ ti pe fun pe ki wọn tun oku Mohbad sin nitori wọn ko fi tọwọtọwọ gbe wọ kalẹ.

Sugbọn ọrọ ko tan si ibẹ,ọpọ eeyan lo ti bu igbe taa pe awọn eeyan kan lo ṣekupa olorin naa, ti wọn si n pe fun idajọ ododo.

Aworan Ilerioluwa Aloba

Oríṣun àwòrán, Instagram/iamMohbad

Lọdun 2022, Mohbad pariwo síta pe ti oun ba ku, ki wọn di Ọga rẹ, Naira Marley ati awọn ọmọ lẹyin rẹ mu.

Mohbad jẹ ọkan lara ọmọ lẹyin gbajugbaja olorin takasufe, Azeez Fashola ti ọpọ si Naira Marley.

Ede ayede waye laarin Naira Marley ati Mohbad, ti ipinya si waye lọdun to kọja.

Ko si igba naa ni fọnran jade to ṣafihan ibi Mohbad ti sunkun lẹyin to kuro atimọle NDLEA, si ni wọn fun oun ni nnkan funfun kan mu.

Agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi ni ọrọ ko ri bẹ ati pe awọn ko mu Mohbad lọ si atimọle

Babafemi ko si nnkan to jọ pe awọn fun Mohbad ni nkan funfun mu.

Iya to bi olorin takasufe to di oloogbe, sọrọ fun igba akọkọ ti ọmọ jade laye lọjọ Aje.

Ninu fọnran kan to wa lori ayelujara, pẹlu omije ni Iya Mohbad fi ranti awọn igba igbẹyin ọmọ rẹ, to si tun fẹsun kan Afeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley ati awọn akẹgbẹ rẹ pe wọn fiya jẹ Mohbad to ko di pe o jade laye.

Aworan Poosi Mohbad

Oríṣun àwòrán, Instagram/STINOMIX

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ko si nnkan to jọ mọ pe Mohbad ni aarun ọpọlọ sugbọn o fi di rẹmulẹ pe inu ẹru ti ọmọ oun gbe titi to fi jade laye.

Bakan naa ni Baba Mohbad, Joseph Aloba ni oun lala buruku ni o ku ọjọ meji ti ọmọ oun jade laye, to si tun salaye pe oun ro pe abẹrẹ ti wọn fun Mohbad lo ṣekupa.

“Nnkan ti mo ni pe abẹrẹ ti wọn fun lo ṣekupa. N ko mọ awọn eeyan to gbe lọ si ile iwosan sugbọn gẹgẹ bi nnkan ti mo gbọ, o bẹrẹ si ni ma bi lẹyin to gba abẹrẹ, ti wọn si tun gbe lọ si ile iwosan."

O ni oun mọ nipa ede ayede to wa laarin Naira Marley ati Mohbad sugbọn oun ko gbagbọ pe Naira Marley lo ṣekupa Mohbad

"Nigba ti Mohbad ati Naira Marley ni ede ayede, mo le fi ọwọ gboya pe nkankan ko ṣe ọmọ mi nitori lọjọ naa mo lọ ba, ti mo si gbadura fun, o dẹ sọ fun mi pe oun fẹ jade.

Iyawo Mohbad, Omowunmi naa ti igbe bọ ẹnu, to si tun salaye pe ọkọ oun la ọpọlọpọ nkan kọja ko to di pe ọlọjọ de.

Omowunmi, ẹni to bimọ ọmọ kan fun Mohbad salaye pe ọpọlọpọ inira ni Mohbad ni, to si jẹ pe awọn kan tun dunkooko mọ titi to fi jade laye.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Sugbọn nibo nikan nnkan dero bayii

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Eko, Idowu Owohunwa, gbe igbimọ pataki SCID kan dide lati ṣe iwadii ohun to ṣekupa Mohbad.

Idowu sọ fun igbimọ naa lati tọ pinpin gbogbo ẹsun ati ọrọ tawọn eeyan n sọ lori ayelujara fun iṣẹ iwadii wọn.

O tẹsiwaju pe ki igbimọ naa lo ọgbọn inu ati imọ ti wọn ni lati fi ṣe iwadii ki wọn si fi otitọ ati ododo mulẹ.

Ọga ọlọpaa Owohunwa ni idajọ ododo gbọdọ waye lori iku Mohbad.

Bakan naa ni Gomina Babajide Sanwo-Olu dasi iwadii ileeṣẹ ọlọpaa lori ohun to ṣe okunfa iku to pa ọdọmọkunrin akọrin takasufe, Ilerioluwa Oladimeji Aloba ti inagijẹ rẹ n jẹ Mohbad.

Gomina Sanwo-Olu ṣeleri lati ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lori iṣẹ iwadii wọn lori ohun to pa Mohbad gan an.

Gómìnà Sanwo-Olu ìpínlẹ̀ Eko dásí ìwádìí ikú tó pa Mohbad

Aworan Mohbad ati Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X

Gomina Babajide Sanwo-Olu ti dasi iwadii ileeṣẹ ọlọpaa lori ohun to ṣe okunfa iku to pa ọdọmọkunrin akọrin takasufe, Ilerioluwa Oladimeji Aloba ti inagijẹ rẹ n jẹ Mohbad.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lo fidi ọrọ yii mulẹ loju opo ẹrọ ayelujara X rẹ.

Gomina Sanwo-Olu ṣeleri lati ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lori iṣẹ iwadii wọn lori ohun to pa Mohbad gan an.

Sanwo-Olu sọrọ yii nigba ti o kan si kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Idowu Owohunwa lori ọrọ iku Mohbad to n mi ilu titi.

Idi ti ileeṣẹ ọlọpaa fi n ṣe iwadii iku Mohbad

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Eko ti gbe igbimọ pataki SCID kan dide lati ṣe iwadii ohun to ṣekupa Mohbad ni rewe-rewe.

Ọga ọlọpaa sọ fun igbimọ naa lati tọ pinpin gbogb ẹsun ati ọrọ tawọn eeyan n sọ lori ayelujara fun iṣẹ iwadii wọn.

Kọmiṣọnna ọlọpaa tun sọ fun igbimọ naa pe ki wọn lo ọgbọn inu ati imọ ti wọn ni lati fi ṣe iwadii ki wọn si fi otitọ ati ododo mulẹ.

Ọga ọlọpaa Owohunwa ni idajọ ododo gbọdọ waye lori iku Mohbad.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa sọ pe o ṣeeṣe ki awọn hu oku Mohbad fun ayẹwo lati ran iṣẹ iwadii awọn lọwọ.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣeleri lati sọ fawọn araalu bi iṣẹ iwadii naa ṣe n lọ gẹgẹ bi ofin ti faye gbaa.

Naira Marley kò san owó orin kankan fún Mohbad fún gbogbo ọdún tó lò pẹ̀lú rẹ̀ - Iyabo Ojo

Mohbad, Iyabo Ojo àti Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Iyabo Ojo ti rọ gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu lati ri dájú pe gbogbo àwọn ìwádìí tí wọ́n ń ṣe lórí ikú gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé, Oladimeji Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad ni wọ́n ṣe dáradára, kí wọ́n sì fi èsì rẹ̀ léde fún gbogbo ayé.

Iyabo Ojo ní òun mọ̀ pé gómìnà tó fẹ́ràn àwọn ọ̀dọ́ ni Sanwo-Olu, tó sì tún gbọdọ̀ fi èyí hàn lórí ọ̀rọ̀ Mohbad yìí láti ri pé ikú rẹ̀ kò lọ lásán.

Ó ṣàlàyé pé àjọ òun ti ṣetán láti dìde sí ọ̀rọ̀ yìí àti pé àwọn agbẹjọ́rò òun ti ṣetán láti bá àwọn òbí àti ẹbí rẹ̀ ṣe ẹjọ́ náà débi tó ní àpẹẹrẹ.

Iyabo Ojo ní ìwádìí tó lóòrìn gbọdọ̀ wáyé lórí ikú Mohbad.

Ó ní gbogbo abiyamọ ayé ló yẹ kí wọ́n dìde sí ọ̀rọ̀ Mohbad nítorí kò sí ẹni tó dá sí ọ̀rọ̀ náà nígbà tó wà láyé tó ń pariwo.

Ó sọ pé ìjọba Eko gbọ́dọ̀ ri pé Sam Larry jẹ́jọ́ lórí ikú Mohbad àti bí wọ́n ṣe máa ń fi ìyà jẹ́ káàkiri gbogbo ibi tó bá lọ.

Naira Marley, Sam Larry ní ẹjọ́ láti jẹ́ – Iyabo Ojo

Gbajúmọ̀ òṣèré náà tún tẹ̀síwájú nínú fídíò kan tí ó ṣe lórí Instagram rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ni àjọ òun yóò máa pè lẹ́jọ́ lórí ikú Mohbad.

Ó fi kun pé Mohbad ti fi igbe ta nígbà kan rí pé Naira Marley fẹ́ pa òun ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni kò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí.

Ó ní Naira Marley jáde lẹ́yìn ọ̀rọ̀ náà pé irọ́ ni Mohbad ń pa àti pé ó ti ń ní ìpèníjà ọpọlọ ni àwọn ènìyàn kò ṣe ka ọ̀rọ̀ Mohbad kún.

Iyabo Ojo ní ìbéèrè tó kàn láti bi Naira Marley ni pé àwọn ìgbésẹ̀ wo ni ló gbé láti fi ran Mohbad lọ́wọ́ nígbà tó mọ̀ pé ó ní àrùn ọpọlọ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó já sí ikú.

Bákan náà ló ní ṣe àwọn tó ń kó àwọn olórin jọ ń ṣe àmójútó wọn bí ó ṣe tó àbí wọ́n kàn ń lò wọ́n láti fi wọ́n pa owó lásán.

Ó ní ó yẹ kí Naira Marley ṣàlàyé fún gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà àwọn nǹkan tí ó ṣe fún Mohbad nígbà tó wà láyé pàápàá nígbà tó mọ̀ pé ó ní ìpèníjà ìlera.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní Naira Marley tún gbọ́dọ̀ ṣàláyé àwọn ìgbésẹ̀ tó gbé nígbà tó di pé àwọn kan ń fòró ẹ̀mí Mohbad, tí wọ́n ń nà án ní àwọn ibi tí ó ń lọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Naira Marley sọ pé òun kọ́ ni òun rán wọn níṣẹ́.

Ó ṣàlàyé pé ó hàn lára Mohbad pé ẹ̀rù wà lára rẹ̀ nígbà tí àwọn pàdé níbi ètò kan ní ilẹ̀ òkèrè àmọ́ gbogbo bí òun ṣe ń bi í láti mọ̀ nǹkan tó ṣe é ló ní ó dìgbà tí àwọn bá délé kí òun tó lè sọ̀rọ̀.

“Mohbad ní ka fún òun ní àwọn ẹ̀ṣọ́ tó máa tẹ̀lé òun nígbà tó fẹ́ jáde pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn Naira Marley má ba à na òun lọ́nà àmọ́ nǹkan tó ń sọ kò yémi nígbà náà.”

Iyabo ojo tún ní Sam Larry náà ní ẹjọ́ láti jẹ́ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbé fídíò jáde pé òun kò mọ nǹkankan nípa ikú Mohbad, ó ní gbogbo bí ó ṣe ń fòró ẹ̀mí rẹ̀ náà jẹ́ àwọn nǹkan tó máa jẹ́jọ́ lé lórí.

“Kò dìgbà tí wọ́n bá gbé ọ̀bẹ sí ènìyàn lọ́rùn kí wọ́n tó pa èèyàn, níṣe lẹ pa Mohbad sáyé, tí ẹ ní kó lọ máa jíṣẹ́ lọ́run, kí ló ṣe.”

“Ìwọ Sam Larry, o mú ọmọ ọlọ́mọ, o le pa nítorí ó ní àwọn bàbá ìsàlẹ̀ àma kò sí ẹni tí Ọlọ́run kò lè mú.”

Ó fi kun pé Sam Larry gbọ́dọ̀ ṣàlàyé àwọn nǹkan tí Mohbad ṣe fun tó fi ń le kiri nínú àwọn fídíò tó gba orí ayélujára kan lẹ́yìn ikú Mohbad.

A gbọ́dọ̀ mọ ibi tí àwọn owó orin Mohbad wọlẹ̀ sí

Ó tẹ̀síwájú pé lẹ́yìn tí Mohbad kúrò lábẹ́ Naira Marley kò fun ní àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ àti àwọn nǹkan tó máa fi ní àǹfàní sí àwọn orin tó ṣe lábẹ́ Naira Marley.

Ó fi kun pé kò sí ọ̀nà tí Mohbad fi le rí àwọn owó rẹ̀ tí Naira Marley bá ṣì kó àwọn nǹkan tó jẹ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ sọ́wọ́.

Ó ní gbogbo owó tó ń wọlé láti ara orin tí Mohbad ṣe fún Naira Marley ni kò fun ní kọ́bọ̀ níbẹ̀ títí di àsìkò yìí àti pé kó má ni lọ́kàn pé òun tún máa jẹ àwọn èyí tó ń wọlé fun báyìí gbé lẹ́yìn tó kú tán.

Ó sọ pé àjọ òun máa kọ ìwé ránṣẹ́ sí Naira Marley láti ṣàlàyé bí ó ṣe ṣe owó tó ń wọlé látara àwọn orin tó ṣe fún Naira Marley.