Ṣé lóòótọ̀ ni pé ìdìtẹ̀gbàjọba tún ti wáyé ní Congo?

Ààrẹ Denis Nguesso

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìjọba orílẹ̀ èdè Congo-Brazzaville ti jiyàn pé àwọn ológun kò dìtẹ̀ gba ìjọba orílẹ̀ èdè náà bí àwọn ìròyìn kan ṣe ti ń gbé kiri.

Ìkéde yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ìròyìn kan gba orí ayélujára pé àwọn ológun ti gba ìjọba lọ́wọ́ ààrẹ Denis Nguesso tó ti wà lórí ipò láti ọdún mọ́kàndínlógójì.

Mínísítà fétò ìròyìn orílẹ̀ èdè náà, Thierry Moungalla nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ayélujára X rẹ̀ ní kò sí ohun tó jọ ìròyìn náà.

Ààrẹ Denis Nguesso, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin, ló wà ní New York lọ́wọ́lọ́wọ́ níbi tó ti ń kópa níbi ètò àpérò àjọ ìṣọ̀kan àgbàyé.

Mínísítà náà rọ àwọn ènìyàn láti máa bá iṣẹ́ oòjọ́ wọn lọ pé ohun gbogbo ti padà bọ̀ sípò.

Bákan náà ni ìjọba Congo tún fi àtẹ̀jáde sórí ayélujára wọn láti jiyàn pé ìdìtẹ̀gbàjọba náà kò wáyé.

Ìdìtẹ̀gbàjọba ló ti ń wáyé ní ẹkùn Áfíríkà láti bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn bí àwọn ológun ṣe tún fipá ba ìjọba ní orílẹ̀ èdè Gabon.

Ní ọdún 1979 ni Nguesso di ààrẹ Congo kó tó di pé ó pàdánù ipò náà lọ́dún 1992.

Ní ọdún 1997 ló tún padà sípò ààrẹ orílẹ̀ èdè náà lẹ́yìn ogun abẹ́lé orílẹ̀ èdè ọ̀hún.

Nguesso ni ààrẹ kẹta ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó ti pẹ́ ni orí ipò jùlọ lẹ́yìn Teodoro Obiang ti orílẹ̀ èdè Equatorial Guinea àti Paul Biya ti Cameroon.