Wo àwọn ọmọ Israeli tó wà ní ìgbèkùn Hamas?

Ileeṣẹ Ologun nilẹ Israeli ni eeyan okoolerugba ati marun lo wa ni ahamọ ikọ ologun Hamas lẹyin ti wọn ṣekọlu lọjọ keje oṣu kẹwaa si orilẹede naa.
Hamas jẹ ko di mimọ pe oun tọju wọn sibi ti nnkan ko ti ni ṣe wọn niluu Gaza.
Ileeṣẹ ologun Israel ni awọn eeyan to wa ni ahamọ jẹ ogun ọmọde, ti eeyan mẹwaa si ogun si jẹ agbalagba.
Eyi ni awọn iroyin awọn eeyan ti BBC le fidi rẹ mulẹ pe wọn wa ni ahamọ Hamas.
Lọjọ Ẹti, ogunjọ oṣu kẹwaa, ọmọ orilẹede Amẹrika meji gba ominira kuro ni ahamọ Hamas, iya ati ọmọ rẹ obinrin.
(Awọn akọsilẹ yii ni a n ṣe atunṣe si lorekore , to sise ki orukọ yii pada nitori pe awọn eeyan mii si ti jade laye tabi ki wọn tu wọn silẹ.)

Oríṣun àwòrán, Yoni Asher
Doron, Raz ati Aviv Asher ni fi si ahamọ lasiko ti wọn ngba pẹlu mọlẹbi wọn ni ilu kan to wa ni ẹgbẹ ẹnu ibode Gaza. Ọkọ Yoni ri fọnran naa bi wọn n ṣe iyawo rẹ ati awọn ọmọ rẹ obinrin sinu ọkọ akero pẹlu awọn eeyan miiran. O tọtọpinpin ẹrọ ibanisọrọ iyawo rẹ wa si ilu Gaza.
Meirav Tal ati ololufẹ rẹ Yair Yaakov, pẹlu ọmọ rẹ, Yagil, 12, ati 16, wa lara awọn ti wọn jigbe to wa ni ahamọ. Iya awọn ọmọ yii, ba awọn sọrọ lori Foonu nigba ti awọn ọmọ ologun Hamas de, to si gbọ igbe ọmọ rẹ ọkunrin, "Ẹ ma mu mi lọ, mo si kekere!" Fọnran kan safihan pe awọn ọmọ naa wa pẹlu awọn to ji wọn gbe.

Amit Shani, 16, ni awọn agbebọn Hamas pasẹ fun pe ko wọ inu ọkọ lẹyin ti awọn agbebọn naa jawọle si mọlẹbi ni Kibbutz Be'eri, iya rẹ sọ fun New York Times.
Tsachi Idan ni wọn ri pẹlu iyawo rẹ gbẹyin, Gali, lẹyin ti awọn ọmọ ogun Hamas ji gbe lọ. Awọn agbebọn yii ṣekọlu si mọlẹbi rẹ ninu ile wọn ni Kibbutz Nahal Oz. Wọn gbe fọnran naa jade. Akọbi rẹ ọkunrin, to sẹẹsẹ pe ọmọ ọdun mejidinlogun ni wọn yinbọn li, Gali sọ fun BBC.

Oríṣun àwòrán, Apero Mọlẹbi
Margalit Mozes, 78, ni wọn ri ninu fọnran bi awọn ọmọ ologun Hamas ṣe n gbe lọ.
Amiram Cooper 85, pẹlu iyawo rẹ ni wọn jigbe ni ile wọn ni Nir Oz ati iyawo ọmọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Lotan Cooper
Judith Weinstein Haggai, 70, ati ọkọ rẹ Gad, 73, naa di awati ni ile wọn ni Nir Oz lẹyin ikọlu Hamas.
Adina Moshe, 72, ni awọn mọlẹbi tọka si ninu fọnran ti kan nibi to n ti awọn ọmọ ologun Hamas i wọn gbe lọ lori ọkada.
Alex Danzig, 75, ọmọwe ati olusọtan Holocaust, lo wa ni ile rẹ nigba ti ikọlu naa waye , ti oun naa siti dero ahamọ Hamas

Oríṣun àwòrán, Mati Danzig
Hagar Brodutch, 40, pẹlu ọmọ rẹ obinrin Ofri, 10, ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin Yuval, 8, ati Oria, 4, naa wa ninu ahamọ bayii
Ron Scherman, 19 jẹ ọmọ ologun Israeli ti wọn jigbe lẹnu ibode nigba to fẹ sọda.
Shiri, Yarden, Ariel ati Kfir Bibas ni igbagbọ wa pe awọn naa wa ni ahamọ Ileeṣẹ ologun Hamas.

Oríṣun àwòrán, Telegram
Yossi and Margit Silberman, awọn obi Shiri naa di awati, ti igbagbọ si wa pe awọn ti wa ni ahamọ ajinigbe.
Daphna Elyakim, 15, ati aburo rẹ Ella, 8, naa wa ninu fọnran ni bi ti wọn ji wọn gbe ni ile wọn ni Nahal Oz kibbutz,
Karina Ariev, 19, jẹ ọmọ ologun to n sisẹ lẹnu pẹlu ileeṣẹ ologun to wa ni ẹnu Gaza

Oríṣun àwòrán, Apero Mọlẹbi
Ofer, Erez ati Sahar Kalderon naa wa ni ahamọ bayii

Oríṣun àwòrán, Ido Dan
Mia Shem, 21, lati Shoham, jẹ ọkan lara awọn eeyan ti wọn jigbe ti yoo gba itusilẹ, ti Hamas si ni ibi pọpọsiinsin ni awọn ti mu.

Channah Peri, 79, ati ọmọ rẹ, Nadav Popplewell, 51, naa wa ni ahamọ Hamas.
Omri Miran, 46, ni wọn jigbe lẹyin ti mọlẹbi rẹ silẹkun lati gba ọmọ Israeli kan lati ma jẹ ki wọn le sekupa.

Liri Elbag, 18, sẹẹsẹ bẹrẹ idanilẹkọ rẹ ni ileeṣẹ ologunb nigba ti Hamas ṣe ikọlu, Baba rẹ Eli ṣo fun Associated Press.
Ọpọ eeyam ni igbagbọ wa pe wọn jigbe nibi ajọdun orin Supernova to waye guusu Gaza.
Moran Stela Yanai,
Almog Meir Jan,
Inbar Heiman,
Hersh Goldberg-
Maya Regev,

Oríṣun àwòrán, Mọlẹbi Maya ati Itay Regev
Shani Louk, arin irin ajọ lati orilẹede Germany, naa ṣe agbako ijinigbe naa, ti kudiẹkudiẹ si ti de ba ilera rẹ lẹyin to fi ori gba.

Oríṣun àwòrán, Shani Louk's Instagram
Noa Argamani, ọmọ orilẹede China ti wọn bi si Isareli naa wa lara awọn ti wọn jigbe
Bar Kuperstein, 21, ba mọlẹbi sọrọ lọjọ keje sugbọn ohun iaylẹnu lo jẹ fun awọn mọlẹbi rẹ lati ri ninu fọnran ti Hamas gbe jade.
Vivian Silver, 74, olupolongo alaafia, ọrọ igbẹyin to sọ ni pe wọn ti n kọlu ile oun.

Roni Eshel, 19, jẹ olugbe ileeṣẹ ologun to wa ni Gaza. awọn mọlẹbi rẹ ni igbati awọn gboro gbẹyin ọjọ ti ikọlu naa waye.

Oríṣun àwòrán, MỌLẸBI ESHEL
Jordan Roman-Gat, 36 jẹ ọmọ orilẹede Germany ati Israeli , pẹlu awọn eeyan to wa ni ihamọ bayii pẹlu ọkọ rẹ ati ọmọ wọn sugbọn ọkọ rẹ Alon ati ọmọ wọn moribọ lọwọ ologun Hamas

Oríṣun àwòrán, Maya Roman
Ohad and Ethan Vahalomy ni kibbutz ni wọn ti jigbe gẹgẹ iya rẹ Ohad, Esther ṣe salaye. Oni Ohad ati Ethan ni wọn gbe lọ lasiko ti awọn agbẹbọn marun run ja wọle wọn.
Ditza Heiman, 84, ni ẹni ti wọn jọ n gbe Kibbutz Nir Oz ri nigba ti wọn gbe lọ

Oríṣun àwòrán, Mọlẹbi Ditza Heiman
Dror Or, iyawo rẹ Yonat, ọmọ rẹ ọkunrin Noam and ati ọmọ rẹ obinrin Alma were ni abanijọgbepọ wọn ri lasiko ti awọn agbebọn Hamas n wọ wọn jade kuro ni ile wọn.
Dokita Shoshan Haran, ọmọ rẹ obinrin Adi Shoham, afẹsọna Tal Shoham, ati awn ọmọ wọn, Naveh ati Yahel, ni wọn jigbe ni ile wọn ni Kibbutz Be'eri
Sharon Avigdori, 52, ati ọmọ rẹ obinrin Noam, 12, ti wọn jẹ mọlẹbi dokita Haran ni igbagbọ wa pe awọn naa wa ni ahamọ ti Eviatar Kipnis, 65 ati iyawọ rẹ Lilach Kipnis, 60, ni awọn ologun Hamas ṣekupa
Yaffa Adar, 85, ni wọn jigbe ni kibbutz, ilu to sumọ Gaza.

Oríṣun àwòrán, Facebook
Awọn obi Sharone Lifschitz ati Ada Sagi, 74, ni igbagbọ wa pe awọn naa wa ni ahamọ ileeṣẹ ologun Hamas bayii

Oríṣun àwòrán, Noam Sagi
Efrat Katz ati Gadi Mozes, to jẹ iya Doron Asher ati ikeji rẹ ni jigbe lasiko ikọlu naa.
Sagui Dekel-Chen, ọmọ orilẹede Amẹrika lo ti di awati lati igbati ti Hamas ṣe ikọlu si Nir Oz kibbutz, baba rẹ sọ fun BBC.

Oríṣun àwòrán, Jonathan Dekel-Chen
Awọn mii ni Anucha Angkaew, Boonthom Phankhong, Nattawaree "Yo" Moonkan, O-wat Suriyasri, Manee Jirachat, Natthaporn Onkaew, Komkrit Chombua, Parinya Taemklang, Pattanayuth Tonsokri, Kiattisak "Top" Patee ati Mr Pongtorn (wọn ko fun wa ni orukọ rẹ) ni wọn wa akọsilẹ orilẹede Thi pe wọn wa ni ahamọ Hamas.
Awọn ti wọn ti gba itusilẹ
Ọmọ orilẹede Amẹrika meji - Judith Raanan ati ọmọ rẹ obinrin Natalie Raanan ni wọn gba itusilẹ ni ogunjọ oṣu kẹwaa lati ọwọ ileeṣẹ ologun Hamas lẹyin ti wọn ko wọn ni Kibbutz Nahal Oz, to jẹ guusu orilẹede Israel















