Wo yàrá tí Sango Olukoso gbé ní ìlú Igbeti àti ìwádìí BBC Yorùbá nípa rẹ̀
Ti a ba n sọrọ awọn akọni oriṣa ni ilẹ Yoruba, ọkan gbogi ni Sango Olukoso, ayanran ina jẹ, ẹni to tun jẹ Alaafin tẹlẹ nilu Oyo.
Yoruba ni ẹni ti yoo ba ga, ẹsẹ rẹ yoo kọkọ tiirin, bẹẹ lo ri fun Sango, nitori ko to di alaafin ilu Oyo, o la ọpọ awọn iriri nla kọja, eyi to gbe de ilu Igbeti.
Ilu Igbeti jẹ Ilu kan to wa ni ijọba ibilẹ Ọlọrunsogo nipinlẹ Oyo.
Ileeṣẹ BBC Yoruba si ṣe abẹwo si ilu naa lati mọ nipa itan to rọ mọ Alaafin Sango ati ibaṣepọ rẹ pẹlu Ilu Igbeti.
Họnọrebu Alawode Olabamiji, to jẹ ọmọ ilu igbẹti kọwọrin pẹlu BBC lati tan imọlẹ si itan yii , to dirọ mọ Sango ati Ilu Igbeti.
Olabamiji jẹ ko di mimọ pe gẹgẹ bi itan ṣe fidi rẹ mulẹ, Sango gbe ni ilu Igbeti fun ọdun meje lẹyin to kuro ni ilu Oyo Ile.

"Bi wọn se fi ẹgbọn Sango joye lẹyin iku baba rẹ lo mu ko binu kuro nilu Oyo lọ sile Ife"
Olabamiji tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba pe “Ni Ilẹ Yoruba, Alaafin Sango Olufiran Ajala Aji, ko to jẹ Alaafin, Igbẹti ni o ti ri agbara ti o lo lati jẹ Alaafin.
Idi ni pe Baba rẹ Ọranmiyan, igba ti o fẹ ku, o pe gbogbo awọn ẹmẹwa rẹ ti wọn jọ n ṣe ijọba nigba yẹn, eyii ti a mọ si Oyomesi lonii,
“O ni ti oun ba ku, oun fẹ ki ọmọ oun Sango jẹ Alaafin, sugbọn nigba ti Baba sipo pada tan, wọn ko ya si ọrọ baba yẹn mọ.
“Wọn wa fi ẹni to jẹ ẹgbọn Sango, ti wọn kii ṣe ọmọ iya kan naa, a n pe iyẹn ni Dada Ajaka-Aji, jẹ Alaafin.
isẹlẹ yii si lo mu ki Sango binu kuro niluu Oyo, to si ni oun n lọ Ile Ife.”
"Sango ba ẹbọra ninu apata to ga ju ni ilẹ Oyo, Iyẹn Oke Iya Mopo, pade ni Igbeti"
Họnọrebu Olabamiji salaye pe kete ti Sango binu kuro nilu Oyo, to ni oun gba Ile Ife lọ, ilu Igbeti lo gba kọja.
O ni nibẹ si ni Sango ti ba ẹbọra ninu apata to ga ju ni ilẹ Oyo, Iyẹn Oke Iya Mopo pade.
“Bi o ṣe de si ilu Igbeti, o ṣe alabapade ẹbọra to gbe inu oke Iya Mọpọ, oke to ga ju ninu gbogbo Ilẹ Oyo.
”Ẹbọra yii ni lati jade sii pe oun ri o, oun si ri gbogbo adojukọ rẹ, sugbọn to ba le ni suuru ko wa pẹlu oun.
O ni oun fi da loju pe awọn Ọyọ funra ara wọn ni wọn yoo wa pe ọ, pe ko wa jọba.
“Ninu itan Igbeti, o fi ye wa pe Iyamopo funra ara rẹ lo gba Sango lalejo.”
Yara meji la ba ni oke Iyamapo ni Igbeti, ọkan jẹ ti Sango,ekeji jẹ ti Iyamapo
Nigba ti BBC Yoruba de ori oke Iya Mopo, iho yara meji ni aṣe alabapade rẹ.
Awọn ọmọ ilu naa si jẹ ko di mimọ fun wa pe ọkan ninu awọn yara naa jẹ yara Sango fun odidi ọdun meje, ti ikeji si jẹ ti Iya Mopo.
Olamibiji ni lẹyin ti Iya Mopo gba Sango ni alejo, o lo ọdun meje, to si kuro lori oke yii lẹyin ọdun meje lẹyin ti awọn ara Oyo pada wa pe ko wa jọba Ilu Oyo.
“Igba ti wọn pada wa pe Sango pe ko wa jẹ Ọba, pe bi Dada Ajaka Aji ṣe n ṣe ijọba ko gba yagiyagi to bii nnkan ti awọn ara Oyo n reti.
“Awọn ara Ọyo wa rọ Dada Ajaka loye, ti wọn si ransẹ si Sango pe ko wa jẹ Ọba.
“Igba to n pada lọ si ilu Oyo, Iya Mapo ati awọn oke mẹrindinlogun to wa nilu Igbeti, ninu eyi ti iya Mapo jẹ ọkan lara wọn, parapọ lati ro Sango lagbara.
Lara awọn oke mẹrindinlogun to ro Sango lagbara naa ni oke Bata Erugba ati Ọbadimọ."



