'Ẹni tí kó bá wà ní mímọ́ kò lè sin Sango, bí Olúkòsò ṣe máa ń búyọ l'óru láti kọ̀yà f'éèyàn rèé'
Ọdun nla ti ọpọ bu iyi fun ni ọdun Sango jẹ nilẹ Yoruba lati bu ọla fun Oriṣa ti wọn maa n ki ni abina loju abina lẹnu.
Ọdun yii a maa waye kaakiri gbogbo awọn orilẹede agbaye ti wọn ti n sọ ede Yoruba ti awọn ẹlẹsin ibilẹ si wa.
Ni orilẹede Benin Republic ni ayẹyẹ ọdun Sango eleyi ti waye ni ilu Iyoko.
BBC Yoruba ṣe ifọrọwanilẹwo pẹlu awọn adari awọn to n bọ Sango naa.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
"Ẹni ti ko ba mọ ko lee ṣe Sango tori Sango ko mọ ẹni to n sin in".
Ìyáàfin Amusa sọrọ nibi ọdun Sango to waye ni orilẹede Benin Republic lọdun yii.
O ṣapejuwe Sango gẹgẹ bii akọya gidi ti ko fẹran ibi ti wọn ba ti n dana irọ.
"Gbogbo ẹni to ba fẹ ba ni lorukọ jẹ tabi fẹ wa ṣe eeyan ni jamba ni Sango maa n ba gbogbo aburu yii jẹ".
Amusa fi ọdun iṣẹṣe naa gbadura fun oniṣẹṣe, ẹlẹsin Kristẹni ati ẹlẹsin Musulumi.






