2022 Sango Festival: Ìpalẹ̀mọ́ Aṣékágbá ọdún Sango lágbàńlá ayé ti bẹ̀rẹ̀ nílù Oyo báyìí

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Odun Sango yatọ ninu gbogbo ọdun ibilẹ ni gbogbo agbaye.

Odun Sango jẹ odun kan ti wọn n ṣe ni gbogob agbaye lati bu ọla fun Oba Sango.

Aafin Oba Oyo ni Ilu Oyo ni ipinle Oyo ni Iwo oorun guusu Naijiria ni won ti maa n ṣe e pẹlu agbara wọn.

Titi odun yii ni akọkọ ti wọn yoo ṣe lẹyin ti Oba Alaafin Lamidi Adeyemi ti waja.

Eyi naa si ni wọn yoo kọkọ se laisi Oba Alaafin kankan lori apere awon baba nla won ṣugbọn sibẹ ọdun Sango jẹ ko ṣe e maṣe.

Asekagba Ayajo odun Sango lagbaye ni yoo waye ni gbagan Aafin Kabiyesi Iku Baba Yeye, Oba lamidi Olayiwola Adeyemi III ni ola, ogunjọ, oṣu kẹjọ, ọdun 2022.

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Eto ayajo odun Sango ti odun yi ni yoo je akoko leyin iku Kabiyese Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi III.

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Nibẹ ni gbogob eto si ti to bayii ti ohun gbogbo ti n lọ deede de ipalẹmọ Asekagba odun naa ni ọla.

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Ayajo odun Sango ti o ti beere lati ojo kokanla, osu kejo, ọdun 2022 yii lo ti n waye nibiti awon elesin Ogun ti rubo labe igi Ose ninu Aafin Oyo.

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere
Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Kini awọn eto miran ti yoo waye ninu odun Sango?

Awon eto miran ti o waye lati se ayajo odun Sango agbaye ni:

  • Ebo riru lati odo Ogun fun Yemoja nibi ti arugba Osun ni ipinle Oyo lodo Alaafin Oyo yoo ti ru igba lati eti odo Ogun ni ilu Oyo wa si inu Aafin Kabiyesi Iku Baba Yeye, Oba lamidi Olayiwola Adeyemi III ti o waja.

.

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Awon wo ni won n reti ni Oyo?

Pelu bi eto Ayajo odun Sango ti fe wa si ipari yii,

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

O sese ki Minisita fun eto iroyin Lai Muhammed wa ni ikale pelu asoju Gomina ipinle Oyo.

Ọpọ awọn Oyinbo lati ile okeere lo ti n de si ilu Oyo fun ayeye ọdun Sango ti ọdun 2022 yii.

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Bakan naa ni wọn ti bọ Ogun Ajọbọ ni Aafin Alaafin Oyo lati fi bẹrẹ ayajọ ọdun Sango 2022 yii.

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, paula Gomez

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Àkọlé fídíò, Emeritus Ayo Bamgbose: Ibánújẹ́ ni ojú yẹpẹrẹ tí ìjọba fi n wo olùkọ́ báyìí jẹ́ fún mi
Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Àkọlé fídíò, Oba Francis Olusola Alao: Agbófinró, Fijilanté àti Amotekun ń gbìyànjú ṣùgbọ́n...
Odun Sango

Oríṣun àwòrán, paula Gomez

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Orisa Sango ti jẹ Alaafin Oyo ri nigba laelae.

Odun Sango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Àkọlé fídíò, Ifọrọwerọ pẹlu obinrin Naijiria to n gbe Morocco
Odun Sango

Oríṣun àwòrán, paula Gomez