Kíni ẹ̀yin rò nípa bí iléesẹ́ Ọlọ́pàá ṣe ń gbẹ̀wù lọ́rùn àwọn Ọlọ́pàá tó bá wù ìwà ìbàjé?

N jẹ kani ifẹhonuhan ‘End Sars’ to waye lọdun 2020 ti bẹrẹ sini ma ni ipa ninu ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria?
Lati oṣu karun un ọdun 2022, ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe awọn ti gbẹwu lọrun awọn ọlọpaa kan ni amọye igba nitori iwa ibajẹ kan tabi omiran.
Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Usman Alkali Baba, nigbati o ranṣe ikilọ si awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria, o ni iṣe ijóba oun ko ni fi aye gba iwa ibajẹ kankan lati ọdọ ọlọpaa.
O ni gbogbo ọlọpaa lorilẹede Naijiria ṣe isẹ wọn bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ fun awọn ara ilu.
Sugbọn ikilọ yii ni awọn ọlọpaa kan kuna lati tẹle, ti o si gbẹwu lọwọ ọpọlọpọ wọn.
Wó àwọn Ọlọ́pàá tí wọ́n gbẹ̀wù lọ́run wọn nítorí ìwà ìbàjé

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Mohammed Alidu
Ẹsun ifipa ba ọmọkekere lo, ẹni ọdun mẹsan ni wọn fi kan Mohammed Alidu ni ipinlẹ Eko.
Alidu ni ba ọmọdebinrin naa sun ni ile igbe awọn ọlọpaa. Ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn ti gbẹwu lọrun ọlọpaa, ti wọn si tun gbe lọ si ile ẹjọ.
Ile ẹjọ wa ti ran Alidu lọ si ẹwọn imọye ọdun.
Liyomo Okoi

Oríṣun àwòrán, ThePoliceNG
Liyomo Okoi ni ileeṣẹ ọlọpaa gbẹwu lọrun rẹ lẹyin ti fọran kan bọ si ori ayelujara nibi ti o ti ada naa arakunrin kan ni ipinlẹ Cross River.
Iwa naa ni ileeṣẹ ọlọpaa sapejuwe gẹgẹ bi iwa ibajẹ, ti wọn si gbẹwu lọrun ọlọpaa naa.
Opeyemi Kadiri

Oríṣun àwòrán, ThePoliceNG
Opeyemi Kadiri ni ileeṣẹ ọlọpaa fi ẹsun ki kọ eti kun si ofin ati ilana ileeṣẹ ọlọpaa kan lẹyin ti wọn kẹfin rẹ nibi ti o wo foonu arakunrin kan.
Iwa wiwo foonu ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ofin de pe ọmọ ileeṣẹ ọlọpaa kankan ko gbọdọ ba nibi o ti gba foonu ẹnikẹni lati wo.
Richard Gele

Oríṣun àwòrán, ThePoliceNG
Ninu fọran kan lo safihan, Richard Gele nibi ti o gba owo lọwọ awọn awakọ kan, ti o si ni Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa mọ pe awọn irufẹ iwa naa.
Richard ni ọga oun ti ni ki awọn gba owo to ṣe pin laarin awọn mejeeji
Iwa yii lo bi awọn ileeṣẹ ọlọpaa ninu ti wọn gbẹwu lọrun Richard Gele, pe ki o lọ rọ kun nile.














