Wọ́n sọ Oníṣègùn ìbílẹ̀ méjì sí gbàga fún ẹ̀sùn jìbìtì £29,000 ni Eko

Oríṣun àwòrán, Agbo
Owopọun ile okeere ni wọn mu awọn Babalawo mejeeji si ti wọn si foju bale ẹjọ́ ni ipinlẹ Eko.
Awọn ọlọpaa ti fi ọwọ ofin mu Muhammed Samatu ati Ajani Kazeem pe wọn lu obinrin kan ni jibiti £29,000 ti o to milionu merindinlogbon owo naira.
Mohammed jé eni ogoji ọdun nigba ti Ajani Kazeem je eni ọdun mẹtadinlaadọta.
Esun mẹta ni wọn fi kan wọnpe wọn gbimọpọ huwa ibi, wọn tun parọ gba ohun ti ko tọ si wọn ati ole jija.
Sugbọn awọn mejeeji sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
- Babagana olùdámọ̀ràn lórí ètò aàbò Nàìjírà, kọ̀wé fipò sílẹ̀ tàbí kí Buhari da ẹ dúró- Arewa
- Ìjọba Eko tún ti gbẹ́sẹ̀ lé ìgbòkègbodò Okada láwọn ìjọba ìbílẹ̀ míràn
- A ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì, àyafi tí ìjọba Nàìjíríà bá.....àwọn òṣìṣẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná
- Tani ọkùnrin ọlọ́dẹ orí tí ayé ń pariwo kiri pé ó gba ìwòsàn ní Akure ni àná?
- Ìjìyà ìkọlù sí ọlọ́pàá Nàìjíríà, Njẹ́ ó mọ àwọn nkan tó lè mú aráàlú tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ lábẹ́ òfin-
- Gómìnà gbé òfin kalẹ̀, ẹ yìnbọn pa ọlọ́kadà tó bá tápà sí kónílé-ó-gbélé alẹ́
Kini awọn agbofinro sọ nipa iṣẹlẹ naa?
Oga ọlọpaa Idowu Osungbure salaye fun ile ẹjọ pe loṣu kẹta ọdun ni wọn huwa ibi yii ni agbegbe Yaba ni ipinle Eko.
O ni pe arabinrin Juliet Enwerobi lo fi ọrọ ohun to n la kọja lọ awọn babalawo yii.
Lẹyin naa ni wọn sọ fun un pe o nilo iwẹnumọ kuro ninu iṣoro naa.
Lẹyin eyi ni wọn gba owo to to milionu merindinlogun lọwọ rẹ fun iwẹnumọ kuro ninu gbogbo iṣoro rẹ.
Esun yii lo sọ pe o tako abala ofin Naijiria 314, 287 ati 411 ti iwe ofin ipinle Eko ti won tunse lodun 2015.
Odun meedogun ẹwọn ni ijiya ti abala 314 pe wọn fi oruko elomii se idanimọ nigba ti abala ti 287 jẹ ẹwọn ọdun mẹta fun ẹsun ole jija.
Adajọ agba ile ẹjọ giga ni Eko, Adajọ Adeola Adedayo sọ pe wọn le gba beeli awọn mejeeji pẹlu milionu marun un naira pẹlu oniduro meji.
Ati pe awon oniduro naa gbọdọ jẹ ibatan wọn.
Wọn gbọdọ ni iṣẹ gidi lọwọ pẹlu iwe ẹri odun mẹta ti wọn ti n san owo ori nipinlẹ Eko.
Leyin naa lo sun igbẹjọ naa siwaju.















