Ìjọba Eko tún ti gbẹ́sẹ̀ lé ìgbòkègbodò Okada láwọn ìjọba ìbílẹ̀ míràn

Oríṣun àwòrán, lagos monitoring/twitter
Ijọba ipinlẹ Eko ti fẹ oju ofin rẹ to gbẹsẹle igbokegbodo alupupu ọkada de awọn ijọba ibilẹ mẹrin ati ẹkun idagbasoke LCDA mẹfa miran ni ipinlẹ ọhun.
Gomina Babajide Sanwo-Olu paṣẹ pe aṣẹ naa yoo bẹrẹ ni ọjọ kini oṣu kẹsan an ọdun 2022.
Kọmiṣọnna fun igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Ọmọwe Frederick Ọladẹinde to kede igbesẹ tuntun yii lọjọbọ sọ pe ijọba ipinlẹ Eko ṣe agbeyẹwo aṣẹ to pa tẹlẹ lati fofin de gigun ọkada lawọn ijọba ibilẹ mẹfa kan, lo fi tun gbe igbesẹ lati fẹ oju ofin naa.
Gẹgẹ bi kọmiṣọnna fun irinna ọkọ nipinlẹ Eko ṣe sọ, igbayegbadun araalu ati idaabobo bo awọn eeyan ipinlẹ Eko lo mu ki ijọba gbe igbesẹ naa.
Awọn ijọba ibilẹ ti ọrọ naa tun mu mọra bayii ni ijọba ibilẹ Koṣọfẹ, Ijọba ibilẹ Oshodi-Isọlọ, ijọba ibilẹ Shomolu pẹlu ijọba ibilẹ Mushin.
Bakan naa laṣẹ naa tun fofin de igbokegbodo ọkọ ni awọn ẹkun idagbasoke agbegbe bii ẹkun idagbasoke LCDA Ikosi-Isherri, ẹkun idagbasoke LCDA
Ati Agboyi-Ketu, ẹkun idagbasoke LCDA Isọlọ LCDA, ẹkun idagbasoke LCDA Bariga, ati ẹkun idagbasoke LCDA Odi- Olowo.
Awọn ijọba ibilẹ wo ni ijọba Eko ti kọkọ sọ ọkada gigun di eewọ tẹlẹ?
Lẹyin ti awọn ọlọkada kan ṣigun da sẹria ọwọ fun awọn ọdọmọkunrin meji kan eyi to la iku lọ fun ọkan ninu wọn ti orukọ rẹ n jẹ David Imoh,
Gomina Babajide Sanwo-Olu paṣẹ tuntun lati fi ofin si igbokegbodo ọkada lawọn agbegbe kan lọjọ kejidinlogun oṣu karun un ọdun 2022.
Awọn agbegbe ti ofin naa ba nigba naa ni ijọba ibilẹ Eti-Osa, Ikeja, Surulere, Lagos Island, Lagos Mainland ati Apapa.
Gbogbo awọn ẹkun idagbasoke LCDA mẹsan to wa labẹ awọn ijọba ibilẹ yii ni ofin yii bawi pẹlu.
Awọn igba marun ọtọọtọ ti ijọba Eko ti gbẹsẹle le ọkada gigun ṣaaju asiko yii

Oríṣun àwòrán, Lagos monitoring/twitter
Fifofinde ọkada gigun kii ṣe igba akọkọ nipinlẹ Eko.
Ni ọdun 2007 ni gomina tẹlẹ Bọla Tinubu kọkọ gbẹsẹ le ọkada ninpinlẹ Eko.
Loṣu kẹta ọdun 2012, gomina Babatunde Fashola to gba iṣejọba lọwọ rẹ naa ṣe bẹẹ.
Bakan naa ni Akinwumi Ambọde to jẹ gomina lẹyin rẹ pẹlu tun gbẹsẹ le wọn lọdun 2017.
Pẹlu gbogbo awọn igbesẹ wọnyii, ọkada gigun ko dẹkun ni ipinlẹ Eko.
Nigba ti gomina Sanwo-Olu pẹlu de ori oye oun pẹlu ti kọkọ gbẹsẹle ọkada gigun ni oṣu keji ọdun 2020.
Nigba to tun di oṣu karun un ọdun 2022 lo ti gbe aṣẹ yii kalẹ pẹlu.
Lọdun 2019, lo gbẹsẹ le awọn ileeṣẹ ọkada igbalode bii Opay, Gokada ati Max.












