Egbẹ́ òṣìṣẹ́ iná mọ̀nàmọ́na ti wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì wọn lẹ́yìn tíjọba ṣèlérí pé...

Osise Oni ina

Egbe osise ina mọnamọna. ẹka tó n pin ina Oba to gunlẹ iyanṣẹlodi ni ana lẹyin iwọde ni ijeta ti pada yi ero wọn pada lori iyanṣẹlodi naa.

Iyanṣẹlodi yii ni wọn bẹrẹ kaakiri Naijiria ni ana.

Bayii, egbe naa ti orukọ won n jẹ National Union of Electricity Employees (NUEE) ati Senior Staff Association of Electricity and Allied Companies (SSAEC)

ti wọle pada sẹnu iṣẹ lẹyin ti Minista Chris Ngige da sii.

Minista to wa fun ọrọ iṣẹ ni Naijiria, Chris Ngige ti pe ipade pajawiri laarin ẹgbẹ osiṣẹ naa ati ijọba Naijiria.

Egbẹ naa salaye pe ijọba Naijiria ko mu adehun rẹ ṣẹ rarar pẹlu awọn osise naa sugbọn Chris Ngige ti ṣe aown ileri tuntun fun wọn.

Ni bayii won ti wọle iṣẹ pada pẹlu adehun gbendeke fun ijọba Naijira lati se ohun to yẹ.

Àwọn òsìsẹ́ elétò mọ̀nà-mọ́ná ti ilé-isẹ́ tó ń mójútó pípèsè iná mọ̀nà-mọ́ná, wọ́n ní kí wọ́n dá adarí àjọ náà duró

Lati ana ni àwọn òsìsẹ́ elétò mọ̀nà-mọ́ná lorilẹ-ede Naijiria, ati apapọ ọmọ ẹgbẹ wọn ti a mọ si, Senior Staff Association of Electricity ti ko sii pẹlu ijoba.

Ati akẹgbẹ wọn iyẹn Allied Companies (SSAEAC) ti ẹnu ọ̀nà ajọ tó ń mójútó pípèsè iná mọ̀nà-mọ́ná lorilẹ ede yii, Transmission Company Of Nigeria (TCN) latari èdè àyedè tó waye láàrin wọn .

Àwọn òṣìṣẹ́ náà ń fi ẹ̀hónú hàn lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn àdéhùn tí wọ́n ṣe pẹ̀lú àjọ rẹ̀ tí wọ́n sì ń ké pe kí wọ́n yọ ọ̀gá àgbà àjọ TCN, Usman Mohammed.

A ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì, àyafi tí ìjọba Nàìjíríà bá.....àwọn òṣìṣẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná

Àwọn òṣìṣẹ́ náà tun fi ẹ̀sùn kan Mohammed pé o n gbè lẹ́yìn ìjọba..

Àwọn òṣìṣẹ́ ọhun ti wọn bẹrẹ ìwọ́de wọn, nipa títi ẹnu ọna ilé- isẹ́ naa pa, ti wọn ko si jẹ ki awọn osisẹ raye wọlé si ilé isẹ́ naa.

Lára nnkan ti àwọn òṣìṣẹ́ naa n tún beere fun ni mímú adehun ọdun 2016 ti wọn fẹnuko sí, ni eyi to ni se pẹlu atunse owó osù àwọn òṣìṣẹ́ naa ati ìgbéga fún àwọn ti wọn lẹ́tọ̀ọ́ sí i.

Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ elétǒ mọ̀nàmọ́ná ti dí ẹnu ọ̀nà ilé isẹ́ àjọ tó ń mójútó pípèsè iná mọ̀nàmọ́ná nílùú Abùjá látàrí ètò ìwọ́de tí wọ́n ń se

Àwọn òṣìṣẹ́ àjọ amúnáwá yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lọla

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

O sese ki kudiẹkudiẹ ba ina monamona lorilẹede Naijiria lọla lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ osisẹ ajọ amunawa pasẹ fun awọn Osisẹ pe ki wọn bẹrẹ iyansẹlodi alia lọjọ lori awuyewuye to wa laarin ẹgbẹ naa ati ajọ to n ri si bi wọn ṣe n se pina monamona lorilẹede Naijiria (TCN).

Awọn Osisẹ ti wọn wa labẹ ajọ National Union of Electricity Employees ni wọn parapọ lati tu lọ si ofisi ajọ TCN loni lati ṣe ifẹhonuhan lori ìyabṣẹ́lódi. Akọwe ẹgbẹ naa Joe Ajaero ninu iwe kan tí akọle rẹ jẹ "Call to Action" ro awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati tẹle asẹ ẹgbẹ naa.

Ajaero ni awọn yoo ṣe idaniduro fun isẹ ajọ TCN lorilẹede Naijiria ti wọn ba ko lati ṣe ohun ti ohun ti o yẹ ki wọn ṣe.

"A n pa lasẹ fun ẹyin Osisẹ lati tu sita lọ sí ofisi ajọ TCN kakiri orilẹede Naijiria lori ìpinnu ajọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ gbọdọ ṣe idanwo ki wọn to le gba agbega lenu isẹ.

"Ifẹhonuhan yoo waye loni ọjọ isegun ti iyansẹlodi yoo si bẹrẹ lọjọru ọsẹ yìí."