Mo pàṣẹ̀ ètò aàbò tó gbóòrìn ní gbogbo iléẹ̀kọ́, iléèwòsàn lásìkò yìí- Usman Alkali Baba, olórí ọlọ́pàá Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @NPF
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti fi ikede sita nipa ibi ti eto aabo Naijiria de duro bayii.
Oga agba Usman Alkali Buba to n tuko ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria si paṣẹ lati oke wa.
O ni ki won safikun si eto aabo yika gbogbo ile ẹkọ Naijiria ati ile iwosan pelu awon ibudo to se pataki ni Naijiria bayii.
Bakan naa lo ni ki wọn maa wa ọkọ agbofinro yika awon agbegbe kọọkan ki won si maa yẹ ara awọn afurasi wo.
- Kò sí ẹlẹ́gbẹ́ Atiku láàrín Tinubu àti Obi - Dino Melaye
- Ìjàmbá iná pa olùjọ́sìn 41 lásìkò iṣẹ́ ìsìn lọ́jọ́ Àìkú
- Òjò arooroda mú èèyàn 50 lọ, àìmọye di aláinílélórí báyìí ní Jigawa
- Adeleke tẹ́wọ́ gba kọ́míṣọ́nà Aregbesola sẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Ó ní àìríkanṣèkan lẹjọ́ tí Oyetola gbé lọlé ẹjọ́
- Mo gbọ́dọ̀ ríi pé ọwọ́ tẹ̀ àwọn tọ pá Happiness MAPOLY, o tó gẹ́ ní Ogun- Gomina Dapo Abiodun
- Wọ́n tí sìn Páṣítọ́ Shuaib Busari tí àwọn adigunjale ṣekúpa niluu ibadan
Kini IGP tun sọ?
Alkali tun kilọ fun gbogbop agbofinro lati fi iwa ọmọluwabi kun iṣẹ ti wọn n ṣe.
O ni ki awọn agbofinro fi igboya ṣiṣẹ bii ọmọ akin lati gbogun ti awọn agbesunmọmi to n dunkooko mọ awọn eniyan Naijiria lasiko yii.
Alkali ni ki wọn wọ inu igbo lọ, ki wọn mase foju fo awon ile akọpati kankan bẹẹ si ni ki won gbena woju awọn kọlọrọsi gbogbo.
Kini Alkali ni ki awon eniyan Naijiria se lasiko yii lati daabo bo ara wọn?
Ni afikun ni Alkali gba awon eniyan orile-ede Naijiria ni imọran pe ki wọn maa ṣọra ṣe lasiko yii.
O ni ki wọn fọwọsowopọ pẹlu awọn agbofinro ni agbegbe wọn.
O tun ni pe ọpọ awọn ọlọpaa lo maa fọnka sita pẹlu iwa ọmọ luwabi ti wón n hu.
Alkali fi da awon olugbe Naijiria loju pe didun lọsan yoo so lori eto aabo Naijiria laipẹ.
O ni awon agbofinro yopo tésiwaju lati maa pese eto aabo fun awọn ara ilu ati dukia wọn.














