Wọ́n tí sìn Páṣítọ́ Shuaib Busari tí àwọn adigunjale ṣekúpa niluu ibadan

Awọn afurasi adigunjale ti ṣeku pa Pasitọ kan lowurọ ọjọ satide ni iwaju sọọbu rẹ niluu Ibadan,
Pasitọ naa, Busari Shuaib Peter, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta, ni awọn adigunjale kọkọ ja ni ole, ki wọn to ṣeku pa ni kete ni o di si sọọbu rẹ nilẹ Ibadan.
Iransẹ naa ni awọn mọlẹbi ti sin si agbegbe Ologun Ẹru niluu Ibadan
Ọkan lara awọn eeyan rẹ to ba BBC New Yoruba sọrọ, Micheal Pelumi, ni ohun iyalẹnu lo jẹ fun awọn mọlebi, nitori awọn ko le sọ nkan pato ti pasitọ naa le ṣe fun awọn adigunjade naa ti wọn fi tẹlẹ e de iwaju sọọbu rẹ.
”Iku Pasitọ Busari lo jẹ ohun iyalẹnu nitori wọn jẹ ẹni ti ko ki n ba eeyan ja tabi sọrọ ẹni laida.

Bakan naa ni Michael tun ni pe: “Awọn to ṣe isẹ ibi sọ pasitọ de iwaju sọọbu rẹ lẹyin ti o gba owo to fẹ lo fi dari isẹ rẹ.
“Pasitọ Busari ku nigba ti awọn gbe wọn lo si ile iwosan Adeoyo
“Oloore ni Pasitọ Busari jẹ fun ọpọlọpọ wa nitori wọn ṣe oore fun awọn eeyan gan an
Olanipekun Jonathan sapejuwe Pasitọ Busari gẹgẹ bi oloore awọn ọdọ ati opo to nilo iranlọwọ nitori pe ko fẹ ki iya jẹ awọn opo ati ọdọ.
“Ọlọrun nikan lo mọ nkan ti o ṣokunkun si awa ọmọ ẹda.”















