Ọwọ́ tẹ̀ Abubakar tó wà ní JSS 3 lẹ́yìn tó jí ọmọ ọdún mẹrin ìbátan rẹ̀ gbé ní Katsina

Abubakar afursai

Oríṣun àwòrán, @Others

Ariwo nibo ni ile aye n lọ ni o gba ẹnu ọpọ kan ni kete ti iroyin yii jade.

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni ipinle Katsina lo fi sita pe ọwọ ti tẹ ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan nibẹ.

Abubakar Abdulbashir ni wọn kede pe o wa ni ipele iwe kẹta JSS 3 ti giram ni Katsina.

Oun ni won lo ji aburo rẹ nidi iya, Halima to jẹ ẹni ọdun mẹrin pere gbe to si tun n beere fun owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọrin naira ni ilu Marabar Kankara ni ijoba ibile Malumfashi ni Katsina.

Won ni leyin to ji ibatan rẹ ẹni odun merin naa gbe tan lo lọ fi pamọ sinu ile akópati ni Marabar Kankara to si n pe fun owo itanran bi gbogbo ẹbi ṣe n daamu lati wa ọmọdebinrin naa kiri.

Bawo ni ọwọ agbofinro se tẹ Abubakar?

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina salaye pe obinrin kan ni Olorun lo ti asiri fi tu.

wọn ni obinrin naa sakiyesi pe nise ni ọmọdebinrin ti Bashir ji gbe naa n sunkun ninu ile akopati naa eyi to mu ki oun ya sibẹ beere ohun to sele.

O ni pe Bashir so pe awon kan jọ n sere nile akópati naa ni.

Eyi lo mu ifura dani ti oun si lọ sile lọ pe baba re wa ti won si ke si awon agbofinro to wa nitosi ile akopati naa.

Leyin ti ọwọ agbofinro tẹ Obi Bashir ni oun naa ṣẹṣẹ wa yọju si agọ ọlọpaa lati fi ara rẹ han nigbẹyin.

O jẹwo pe tootọ ni oun ji Halima ọmọ aburo iya oun gbe.

Ati pe nitootó ni oun fi Halima pamọ si ile akóti nibi ti oun ti n beere N70, 000 naira owo itanran lọwọ obi Halima ibatan rẹ.

Àkọlé fídíò, Abdulazeez Olajide Adediran Jandor: O ṣeni láànú pé owó Eko kò ṣiṣẹ́ fún ará Eko

Bashir ni kete ti oun pe won tan pe ki wọn wa owo itanran naa lo ni eri ọkan bẹrẹ si ni jẹ oun ni eyi to si lodi si ẹsin Islam ti oun gbagbọ ninu rẹ.

O n beere fun idariji ẹṣẹ rẹ bayii pe ki awọn Obi Halima gba pe oun ti ronupiwada lori aṣise oun.

Àkọlé fídíò, Ọdọbinrin Iyeyemi Adediran sọ iriri rẹ ni idi iṣẹ awakọ epo tirela ati bi o ṣe bẹrẹ.

Kini ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ yii?

Agbenuso ileeṣẹ ọlọpaa Katsina, SP Isah Gambo salaye pe lootọ ni iṣẹlẹ naa.

Ati pe arakunrin Sanusi Abubakar to jẹ baba Halima ti wa fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa lati igab ti o ti n daamu wa ọmọ rẹ kiri.

O ni nitootọ lo gba ipe lati san N70, 000 owo itanran ti ko ba fẹ ki wọn pa ọmọ rẹ, Halimatu Sanusi.

Agbenusọ ọlọpaa ni kete ti wọn kẹfin ibi ti ọrọ naa n lọ ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ to jẹ ki owọ wọn tẹ Abubakar Abdulbashir to jẹ afurasi ibatan Halima Sanusi.

Bakan naa ni o fidie mulẹ pe afursai naa ti jẹwọ ẹṣẹ rẹ, igbesẹ to yẹ si ti bẹrẹ labẹ ofin.

Amotekun

Oríṣun àwòrán, @Amotekun

N30 mílíọ̀nù ní wọ́n ṣèlérí láti fún mi tí mo bá ri orí òkù kan gbé ní Ondo- Afurasi sọ fún Amotekun

Owọ ikọ Ondo State Network Agency, ti ọpọ mọ si Amotekun ti tẹ arakunrin afurasi kan ti orukọ rẹ n jẹ Timothy Odeniyi.

Timothy Odeniyi to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji ni ọwọ tẹ pẹlu ẹya ara ẹsẹ ati ọwọ oku ni ipinle Ondo.

Odeniyi salaye fun awon Amotekun pe ipinlẹ Eko ni onibara oun wa to n beere fun eya ara oku naa.

Lọjọ Aje ni wọn safihan ọkunrin naa to jẹwọ pe oun ge ẹsẹ ati ọwọ oku kan ni iboji agbegbe Sabo ni ilu Ondo nibi to sunmo olu ileese ijoba ibile Ondo West ni ipinle Ondo.

Ọwọ ikó Amọtẹkun Ondo ló tẹ Timothy Odeniyi lẹyin tó ti ge ẹsẹ àti ọwọ oku kan ni itẹ́.

Timothy Odeniyi ti ọwọ tẹ yii lo sọ pe oun n sisẹ gẹgẹ bi awakọ ajagbe pelu ileeṣẹ to n po ọti ta kan tẹlẹ.

O ni ọga agba fun oun lasiko ti oun n siṣẹ nibẹ lo ran oun niṣẹ ẹya ara oku yii.

Timothy ni pe: Oga mi fẹ lo eya ara naa fun oogun owo ni

Lẹyin ti mo ti ge ọwọ ati ẹsẹ oku yii tan ni mo pinnu lati lọ gbe e fun eni to ran mi ki ọwọ to tẹ mi lẹyin ti mo jade kuro niboji oku naa.

Oga mi sọ pe ọgbọn miliọnu ni owo iṣẹ mi ni kete ti mo ba ti ko awọn ẹya ara naa de ọdọ rẹ.

Bakan naa ni afurasi yii salaye fun awọn Amotekun pe oun ko pa enikẹni ati pe igba akọkọ re e ti oun a ji ẹya ara oku ta.

Oga agba iko amotekun Ondo, Akogun Adetunji Adeleye sọ pe irọ ni afurasi naa n pa pe ko pa eeyan.

O ni pe ọwọ tẹẹ pẹlu ẹṣe ati apa eeyan to ti fi pépà we ni.

Àkọlé fídíò, '500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

Ati pe léyin ti iya jẹ afurasi naa daadaa lo wa mu won lọ si ibi ti ara oku naa to ṣẹku ṣi wa ninu iboji kan ti ko jin rara ni agbegbe naa.

o ni pe iṣẹ n lọ lọwọ lati fa afurasi naa le agbofinro lọwọ fun igbese to kan