Egungun Oloolu ti ilẹ̀ Ibadan fojú han aráyé! Gbọ́ àwọn ǹkan tó ń dẹ́rù ba ni nípa rẹ̀ àti èèwọ̀ rẹ̀
Eku ò ké bí eku n'Ibadan lọ́jọ́ tí èmi Egungun Oloolu dé”.
Ẹni kò ó, kò mọ̀ ọ́, ẹni mọ̀ ọ́ ò kò ó... Egungun Oloolu funrarẹ rẹ, loju aye ara rẹ, ijaya lo jẹ ni gbogbo ilu Ibadan to si jẹ akanda eeyan tabi ti wọn n pe ni Ara Ọrun ti gbogbo ara Ibadan n wariri fun.
Oloolu funrarẹ ti wa foju han lori itakun BBC Yoruba bayii, bẹẹ ba fẹ gbọ isẹda rẹ, ohun to duro fun ni Ibadan eewọ rẹ ati ohun ti ẹyin funrayin ko gbudọ ṣe sii, ẹ wo fidio to wa loke yii.


“Nígbà tí Oloolu dé ní wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ni jẹ́ Olubadan, Báàlẹ̀ ni wọ́n ń jẹ tẹ́lẹ̀”. Oloolu funra rẹ sọ.
Ọkan pataki ni gbajugbaja egungun yii jẹ laarin gbogbo eegun to n bẹ nilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo.
O da yatọ, ọdọọdun ni awọn eeyan maa n ṣe ayẹyẹ lati yẹẹ si ni asiko ti wọn ba n ṣe ọdun egungun ni Ibadan.
BBC Yoruba tan ina sọna lati wa Egungun yii kan tabi ka ni ọkunrin to fi ara rẹ ji lati maa gbe egungun Oloolu.
Anfani naa de, BBC pade Oloye Ojetunde to si ni ki awọn eeyan ma bẹru niwọn igba ti oun ti bọ Ẹku Egungun oun silẹ amọ awọn eewọ kan ṣi tun wa bi oun ko ṣe wọ aṣọ.

















