Mọ̀ síi nípa al-Zawahiri, olórí ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí al-Qaeda tí Amẹ́ríkà ṣẹ̀ṣẹ̀ pa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ igba ni wọn maa n tọka si Ọgbẹni al-Zawahiri, ẹni ti ohun ija oloro ofurufu drone ti ilẹ Amẹrika pa ni orilẹede Afghanistan lọjọ Aiku gẹgẹ bi ọlọpọlọ ikọ agbesunmọmi al-Qaeda.
Akọṣẹmọṣẹ iṣegun nipa oju ni ko to darapọ gẹgẹ bi ọkan lara awọn to ṣe idasilẹ ẹgbẹ agbesunmọmi naa.
al-Zawahiri di olori ẹgbẹ al-Qaeda lẹyin ti awọn ọmọogun Amẹrika pa olori ẹgbẹ naa, Osama Bin Laden loṣu karun un ọdun 2011.
Ṣaaju eyi lọpọ ti mọọ si ọwọ ọtun ati korikosun Bin Laden, ti ọpọ si tun rii gẹgẹ bii ẹni to wa lẹyin agbekalẹ gbogbo ikọlu igbesunmọmi ọjọ kọkanla oṣu kẹsan an, 9/11 ọdun 2001 lorilẹede Amẹrika.
Zawahiri lo wa ni ipo keji lara awọn eeyan mejilelogun ti ikọ alaabo Amẹrika n wa julọ lagbaye eyi ti ijọba Amẹrika kede lọdun 2001 pẹlu ẹbun owo miliọnu marundinlọgbọn dọla gẹgẹ bi ẹbun owo fun ẹnikẹni to ba fun ijọba ni iroyin lati mu u.
Lẹyin ikọlu oṣu kẹsan an ọdun 2001, 9/11, Zawahiri di ogbontagi agbẹnusọ fun ikọ al-Qaeda.
Fidio ati fọnran ohun ikasilẹ mẹrindinlogun lohun nikan ti fara han lọdun 2007 nika.
Eyi ju iye igba ti Osama Bin Laden funra rẹ han ni ilọpo mẹrin lọdun naa.
Ni opin ọsẹ to kọja ni wọn pa a, ṣugbọn eyi kọ ni igba akọkọ ti ilẹ Amẹrika lepa ẹmi rẹ.

Oríṣun àwòrán, fbi
Ni ọdun 2006, orilẹede Amẹrika yin ado oloro kan si ibi kan ti wọn wo pe o wa ni ala orilẹede Pakistan ati Afghanistan.
Ọmọ ẹgbẹ al-Qaeda mẹrin ni ikọlu naa ran lọ sọrun, ṣugbọn Zawahiri ru u la, ki o to tun fara han ninu fidio kan lẹyin ọsẹ meji nibi to ti paroko ikilọ ranṣẹ si aarẹ Amẹrika nigba naa, George W Bush pe, yala oun, tabi “gbogbo agbara lorilẹ aye” ko lee sun ọjọ iku oun mọle “pẹlu iṣẹju kan” bi o ti wulẹ o mọ.
Ipilẹ Idile rẹ
Ilu Cairo tii ṣe Olu ilu Egypt ni wọn ti bi al-Zawahiri ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹfa ọdun 1951 si idile kan to kun fun ọpọ ọmọwe ati awọn akọṣẹmọṣẹ iṣegun oyinbo.
Baba-baba rẹ ti orukọ rẹ n jẹ Rabia al-Zawahiri ni imaamu agba al-Azhar, aringbungbun ilana ẹkọ ijọ ẹsin Musulumi ti Sunni ni agbegbe Middle east,bẹẹni ọkan lara mọlẹbi baba rẹ ni akọwe agba ajọ orilẹede arabu, Arab League.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lati igba to ti wa ni ileewe ni Zawahiri ti n kopa ninu awọn ọrọ oṣelu to nii ṣe pẹlu Islam, wọn si fi panpẹ ofin mu u nigba to jẹ ọmọ ọdun marundinlogun lori ẹsun pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin kan ti ko bofinmu, iyẹn ẹgbẹ Muslim Brotherhood to jẹ ẹgbẹ ẹlẹsin musulumi to pẹ julọ to si tun pọ julọ lorilẹede Egypt.
Igbesẹ rẹ lati maa kopa ninu ẹgbẹ alakatakiti ẹsin ko dii lọwọ lati lọ kọ ẹkọ gboye imọ ijinlẹ ninu iṣegun oyinbo ni fasiti ilu Cairo lọdun 1974.
Lọdun 1995 ni baba rẹ, Mohammed, ẹni to jẹ Ọjọgbọn ninu imọ nipa oogun oyinbo nileẹkọ giga fasiti ilu Cairo nigba aye rẹ.
Nigba ti wọn da ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Egyptian Islamic Jihad ni ọdun 1973, al-Zawahiri dara pọ.
O si wa lara awọn ti wọn fi panpẹ ofin gbe lọdun 1981 lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ alakatakiti ẹsin naa mura bi ọmọ ogun lati pa aarẹ Anewar Sadat nilu Cairo.
Ẹgbẹ alakata kiti ẹsin naa pa Sadat nitori adehun alaafia to tọwọ bọ pẹlu orilẹede Israel.
Bi o tilẹ jẹ pe ile ẹjọ ni ko jẹbi lilọwọ ninu iku Aarẹ Sadat, ṣugbọn o ṣẹwọn ọdun mẹta fun nini ohun ija oloro ni ikawọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, screenshot
Lẹyin itusilẹ rẹ lọdun 1985, Zawahiri gba Saudi Arabia lọ. Nibẹ lo gba lọ si Peshawar lorilẹede Pakistan ati Afghanistan nibi to ti da ẹka ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Egyptian Islamic Jihad silẹ nigba to n ṣiṣẹ nibẹ gẹgẹ bi dokita oniṣegun oyinbo.
Ni ọdun 1997 ni Zawahiri lọ tẹdo si ilu Jalalabad lorilẹede Afghanistan nibi ti Osama bin laden wa nigba naa.
Ẹrọ ibanisọrọ Zawahiri wa lara ẹri ti awọn ọtẹlẹmuyẹ orilẹede Amẹrika ri lati fi mọ pe ẹgbẹ agbesunmọmi al-Qaeda lo wa nidi ikọlu to waye ni ileeṣẹ aṣoju ijọba Amẹrika ni Kenya ati Tanzania nibi ti wọn ti ran eeyan igba ati mẹtalelogun lọ sọrun.
Lẹyin iku Osama Bin Laden, awọn ikọlu ọmọ ogun ofurufu Amẹrika ti pa ọpọlọpọ awọn amugbalẹgbẹ al-Zawahiri eleyi to mu adinku bva ijafafa rẹ lati maa tẹ waya ikọlu igbesunmọmi kaakiri agbaye.
Wo bí ọwọ́ Amẹ́ríkà ṣé tẹ olórí ìkọ agbésùnmọ̀mí al-Qaeda tí wọ́n tún fi Díróònù pa á

Oríṣun àwòrán, AFP
Diroonu wa ti pa olori ikọ agbesunmọmi al-Qaeda,Ayman al-Zawahiri,ni Afghanistan.
Ikede ree ti Aarẹ Amẹrika Joe Biden fi sita eyi to fi sọ fun araalu pe ọwọ Amẹrika ti ba ẹni to gba akoso ikọ agbesunmọmi al-Qaeda lọwọ Osama bin Laden lẹyin iku rẹ ni 2011.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ọjọ Aiku lawọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ CIA ṣeku pa Zawahiri ni ilu Kabul.
O ni Zawahiri ti la oju ọna isekupani ati idunkoko mọ awọn ọmọ orileede Amẹrika.
''Ni bayi a ti fi idajọ ododo lelẹ,agbesunmọmi yi ko si si laye mọ'
Zawahiri ati Osama Bin Laden ni wọn jijọ pete pero ikọlu 9/11 o si wa lara awọn ogbologbo agbesunmọmi ti Amẹrika n wa kaakiri.
Awọn alaṣẹ sọ pe Zawahiri wa nita ile rẹ to sapamọ si nigba ti diroonu yin ado oloro meji lu.
Wọn lawọn mọlẹbi rẹ wa nibẹ nigba iṣẹlẹ yi ṣugbọn wọn ko farapa.
Zawahiri nikan ni wọn lawọn ribi ṣeku pa.
Biden lo paṣẹ pe ki wọn ṣeku pa Zawahiri

Aarẹ Amẹrika Joe Biden sọ di mimọ pe oun loun paṣẹ pe ki wọn yin ado oloro lu agbesunmọmi ẹni ọdun mọkalelaadọrin yi lẹyin ọpọ oṣu tawọn ti n tọ pinpin rẹ.
O ni iṣekupa Zawahiri yoo mu ifọkanbalẹ ba mọlẹbi awọn to to ẹgbẹrun mẹta ti wọn padanu eeyan wọn ninu ikọlu 2011.
O ni "B o ti le wu ko pẹ to, ibi o ba wu ko sa pamọ si,bo ba n dunkoko mọ Amẹrika, a o wa ọ kan taa si ri pe a gbẹmi rẹ''
O fi kun pe Amẹrik ko ni yẹ, ko ni gbo nibi didaabo bo awọn eeyan ilẹ wọn.
O ni arakunrin Zawahiri lo wa nidi ikọlu tawọn kan ti ba ọkọ oju omi Amẹrika USS Cole jẹ lọdun 2000.
Ọmọ ogun oju omi Amẹrika mẹtadinlogun lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ yi.
Bẹẹ lo fi kun agbesunmọmi yi lo pete ikọlu si olu ileesẹ Amẹrika to wa ni Tanzania ati Kenya ni 1998 nibi ti awọn eeyan 223 i padanu ẹmi wọn.
O tẹnumọ pe Afghanistan ko ni jẹ ibuba fawọn agbesunmọmi mọ laelae.
Kini Taliban sọ si ikọlu Amẹrika yi?
Agbẹnusọ ijọba Taliban lorileede Afghanistan kan ti ṣapejuwe ikọlu ti Amẹrika ṣe yi gẹgẹ bi ohun to tako ofin agbaye.
''Iru iwa bayi safihan igbesẹ ikunna bi tati ogun ọdun sẹyin ti o si wa ni itako ohun ti yoo ṣe Amẹrika,Afghanistan ati agbegbe yi lanfaani''
Amọ awọn alasẹ Amẹrika ṣi tẹnumọ pe awọn gbe igbesẹ ti o wa ni ibamu pẹlu ofin ni.
Iṣekupa Zawahiri n waye ni nkan bi ọdun kan lẹyin igba ti Amẹrika ko awọn ọmọ ogun rẹ kuro ni Afghanistan ni ibamu pẹlu aṣẹ aarẹ Biden.
Ogun ọdun gbako l'Amẹrika lo ni Afghanstan ki wọn to kẹru lọ silẹ wọn pada.
Labẹ adehun alaafia ti Taliban buwọlu pẹlu Amẹrika ni 2020, Taliban gba
pe awọn ko ni faaye gba al-Qaeda tabi awọn ikọ agbesunmọmi miran ni abẹ akoso wọn.
Sugbọn Taliban ati al-Qaedah jijọ ni ajọṣepọ ọlọjọ pipẹ ti awọn alaṣẹ Amẹrika si sọ pe wọn mọ pe Zawahiri wa ni olu ilu Afghanistan, iyẹn Kabul.
Minisita fun ilẹ okere Amẹrika Antony Blinken sọ pe nipa gbigba Zawahiri lalejo ti wọn si tun daabo bo, ijọba Taliban ti tapa si adehun tawọn jijọ ṣe.












