Ṣé lóòtọ́ ni pé DSS mú olórí Boko Haram ní Ogun?

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Inú fu, àyà fu ní ìlú Abeokuta wa ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2022 bí ìròyìn ṣe gbòde kan pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS nawọ́ gán afurasí olórí ikọ̀ Boko Haram níbẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀wá lọ́wọ́ ṣe sọ, agbègbè Ijaye ní Abeokuta ni wọ́n ti nawọ́ gán afurasí gẹ́gẹ́ bí olórí ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí ọ̀hún ní alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Ìròyìn náà fi kun pé afurasí ọhun jà fitafita láti mórí bọ̀ lọ́wọ́ àwọn DSS ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ náà kápá rẹ̀.
Wọ́n ní láti ìlú Katsina ni afurasí ti wá gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọdẹ ní Ijaye àmọ́ tó jẹ́ wí pé ó fẹ́ fi máa kó ìròyìn tí wọ́n fẹ́ lò láti ṣe iṣẹ́ láabi jọ ni.
Bákan náà ni wọ́n fi kun pé kìí ṣe òun nìkan ló wà ní agbègbè náà àmọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ni iṣẹ́ ń lọ gidigidi láti fi póró òfin gbé àwọn yòókù náà.
Afurasí náà ṣì wà ní àhámọ́ àwọn ọtẹlẹmuyẹ DSS gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ.
Nígbà tí àwọn akọròyìn kàn sí agbẹnusọ iléeṣẹ́ DSS, Peter Afunaya lórí ìròyìn náà, ó kọ̀ láti sọ ohukóhun.
Bákan náà nígbà tí BBC Yorùbá kàn sí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ó ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò mọ nǹkankan nípa ìròyìn ọhun.
















