Bí ọkọ mi ṣe ti èmi àti ọmọ mi méjì mọ́ ilé fún ọdún 17 leléyìí…

Aworan

Oríṣun àwòrán, Brazil Police

Arabinrin ọmọ ilẹ Brazil kan ti sọ ohun ti oju rẹ ri lẹyin ti ọkọ rẹ ti oun ati ọmọ rẹ mejeeji sinu ile kan fun ọdun mẹtadinlogun.

Ninu iroyin ti o jade ni abẹle ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ni awọn doola ẹmi arabinrin naa ati ọmọ rẹ meji to jẹ ọdọlangba amọ ti wọn ri bi ọmọde nitori airi ounjẹ jẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe Guaratiba ni Rio de Janeiro ni awọn ti doola ẹmi awọn mọlẹbi naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ ọba mu ọkọ

Inu ile

Oríṣun àwòrán, RIO DE JANEIRO MILITARY POLICE

Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti gbe ọrọ obinrin naa to ni ọkọ oun ni lẹyin ti awọn ba ku ni oun yoo to gbe wọn jade.

Ọkunrin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa darukọ rẹ pe Luiz Antonio Santos Silva.

Obinrin naa ati ọkọ rẹ ni wọn ti wa gẹgẹ bi lọkọ-laya fun ọdun mẹtalelogun.

Lẹyin ti wọn doola ẹmi wọn ni obinrin naa sọ fun awọn alaṣẹ pe igba miran awọn kii jẹun fun ọpọlọpọ ọjọ, igba miran ọjọ mẹta, ti eleyii si ti fa aisan si ara wọn ati ọkan wọn pẹlu.

Wọn ṣalaye pe aworan ile naa ti awọn ti doola ẹmi wọn ri bakan nitoripe inu ile ti wọn wa naa ni o kun fun idọti ati ina kekere.

Awọn ọmọ naa jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun ati ọdun mejilelogun.

Inu ile

Oríṣun àwòrán, RIO DE JANEIRO MILITARY POLICE/EPA

Wọn ti n gba iwosan ni ile iwosan – Ọlọpaa

Balogun William Oliveira to ba ikọ ọlọpaa ọmọ ogun ilẹ naa sọrọ ni awọn kọkọ ro pe awọn ọmọ meji naa maa doloogbe ni nitori bi wọn ṣe ri.

‘’A ro pe wọn ko le lo ju ọsẹ kan lo nitori wọn jọ ọmọde kekeeke’’

Amọ nibayii wọn ti n gba itọju ni ileewosan, ti wọn si lero pe ara wọn yoo gba alaafia laipẹ.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fikun un pe iwadii ti bẹrẹ lori idi ti awọn molẹbi naa ko fi ri idoola ẹmi ni kiakia, nitori wọn tipe akiyesi ọlọpaa si agbegbe naa ni ọdun 2020, amọ ti wọn ko ṣe nkankan si.