Ọlọ́pàá tó fi ipá bá ọmọ àbúrò rẹ̀ lòpọ̀, tún fún un lóyún ti kó sí gbaga Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu isipẹkitọ ọlọpaa kan, ti wọn fi ẹsun kan pe o fi ipa ba ọmọ aburo rẹ lo pọ, to tun fun un loyun, nipinlẹ Nasarawa.
Ọmọ ọdun mẹẹdogun ni ọmọbinrin naa.
Iroyin sọ pe igba pupọ ni ọkunrin ọhun fi ipa ba ọmọbinrin ọhun to n gbe pẹlu oun ati ẹbi rẹ lopọ, ati pe ọmọ naa darapọ mọ ẹbi ọhun lẹyin ti baba rẹ ku.
Ẹgbẹ awọn agbẹjọro obinrin ni Naijiria, FIDa, to tu aṣiri iṣẹlẹ naa sọ pe oun yoo ri daju pe gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ lo jẹ iya labẹ ofin.
Iroyin to tẹ BBC lọwọ lati olu ileeṣẹ ọlọpaa nilu Lafia, olu ilu ipinlẹ Nasarawa, ni pe ọlọpaa naa to ti wa ni ipo isipẹtọ, n ṣiṣẹ pẹlu ẹka ọtẹlẹmuyẹ.
Olori ẹgbẹ FIDA nipinlẹ naa, Amofin Rabi’atu Ibrahim Addra, sọ pe ajọ alaanu kan lo fi iṣẹlẹ naa to waọn leti.
Lẹyin ti wọn gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn gbe ọmọbinrin naa lọ sileewosan, nibi ti esi ayẹwo ti fihan pe o ti loyun oṣu marun-un.
O ni awọn sare gbe ọmọbinrin naa lọ silewosan, nibi ti dokita ti fidirẹ mulẹ pe wọn ti kọkọ gbiyanju lati ṣẹ oyun naa, ti ọmọ naa si ti ku sinu iya rẹ.
“Gbogbo igbiyanju awọn oṣiṣẹ ileewosan lati gbe oku ọmọ naa jade lo ṣoro, nitori pe o ti bẹrẹ si ni jẹra, to si n rùn jade lati ara ọmọbinrin naa.
“Wọn ni lati lo oogun ati abẹrẹ fun ni, ki oku ọmọ naa to jade fun’ra rẹ.”
Lẹyin eyi ni wọn bẹrẹ ayẹwo DNA, lati mọ ẹni to fun ni oyun ọhun, ‘nitori pe ọmọbinrin naa n tẹnumọ pe ibatan rẹ ọhun lo fun ni oyun.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Nasarawa, DSP Ramhan Nansel sọ pe ọwọ ti tẹ isipẹtọ ọlọpaa, ti awọn si n duro de esi ayẹwo DNA, lati fidi okodoro mulẹ.
















