Obìnrin tó jí ọmọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ nílú Ibadan ní Ọgbẹ́ ìfipábánilòpọ̀ tí òun kojú lọ́dún mẹ́tàlá kún ara ohun tó ń da òun láàmú

Ni ọjọ Ẹti ni BBC news Yoruba gbe fidio iroyin kan jade nibi ti arabinrin kanMonsurat Lateef ti sọrọ lori bi arabinrin kan to fi ara mọ ọ gẹgẹ bi ọrẹ ṣe ji ọmọ rẹ gbe lọ lagbegbe Ogbere nilu Ibadan.
Arabinrin afurasi ajọmọgbe naa ti orukọ rẹ n jẹ Itunu Adepọju pada wa bọ sinu panpẹ awọn ọlọpaa to si ti n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ati idi to fi hu iwa ika yii.
Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ lolu ileeṣẹ ọlọpaa nilu Ibadan, arabinrin Itunu Adepọju, ṣalaye pe lati igba ti oun ti jẹ ọmọ ọdun mẹtala loun ti koju ipenija ifipabanilopọ eleyi to si ti da ọpọlọpọ ọgbẹ si oun lọkan.
Afurasi Itunu Adepọju, ẹni ọdun mẹtalelogun naa ni ọkọ mẹrin loun ti fẹ, oyun mẹrin ọtọọtọ loun si ti ni fun wọn bi o tilẹ jẹ pe ọkan ninu awọn ọmọ ti oun bi ti ṣe alaisi.
O ni oyun ti oun ni fun ọkọ ti oun wa lọdọ rẹ bayii loun gbe rinrinajo lati lọ gbe ọmọ oun ti oun gbe ti awọn obi oun ti oun fi ni ijamba ọkọ. Ijamba ọkọ yii lo ni o fa ọgbẹ inu fun oun ti ọmọ naa si ku lẹyin ti oun bii nitori eyi.
O ni oun ko lee ṣalaye ọrọ naa fun ọkọ oun nitori wahala ti awọn mọlẹbi rẹ gbe koo loju.

“Ni ọjọ ileya, mo pe ọkọ mii lati sọ fun un pe mo ti bimọ obinrin gẹgẹ bi ayẹwo inu oyun (Scan) ti mo ṣe ti oun naa si mọ si tẹlẹ. O ni awọn maa ṣe eto bi wọn a ṣe wa gbe ọmọ naa, ṣugbọn mo sọ fun un pe awọn obi mi ko ni gba nitori pe mi o tii jẹ ko ri awọn obi mi ṣaaju asiko yii.”
Pẹlu wahala ti baba mi naa n fun mi lati fi ile oun silẹ, pẹlu ọmọ mi obinrin ni mo fi gba ile iwosan lọ lati tọju inu mi to ṣi n dun mi. Bakan naa ni mo dẹ tun pe ọkọ mi pe maa gbe ọmọ rẹ wa fun un.
O ṣalaye siwaju sii pe ni ile iwosan ni oun ati Arabinrin Lateef ti pade ara ti oun si sọ fun un pe oun nile ile ti oun lee maa ya gbe pẹlu ọmọ oun obinrin ti oun gbe lọdọ awọn obi oun.
“Mo ṣakiyesi pe o ṣẹṣẹ bi ọmọ ni, emi ati ẹ si tun pade ni irọlẹ ọjọ naa to jẹ ọjọ Iṣẹgun.”

Oríṣun àwòrán, other
Ni Ọjọru to ni oun gbero ati kuro ni ile wọn ni ọkọ oun tun ti pe oun ti o si n beere nipa ọmọ ti oun gbe oyun rẹ kuro nile lai mọ pe oun ti padanu ọmọ naa lẹyin ti oun ni ijamba ọkọ loju ọna irinajo oun lati lọ gbe ọmọbinrin oun kekere ni ọdọ awọn obi oun.
“Lasiko ti ọkọ mi pe yii, ọmọ arabinrin Lateef wa lọwọ mi nibi ti mo ti fẹ gba owo lẹnu ẹrọ isanwo PoS. Eyi lo mu mi roo pe ki n kuku lo anfani naa lati fi gbe ọmọ naa lọba ọkọ mi ni ilu Ikorodu nipinlẹ Eko.”
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, irufẹ iṣẹlẹ yii naa ti waye lọsẹ diẹ sẹyin nigba ti arabinrin kan pẹlu ji ọmọ tuntun gbe nilu Okitipupa to si gbe e lọ si ipinlẹ Ogun.
Ni ibi ti wọn ti n ṣe isọmọlorukọ ọmọ naa ni ipinlẹ Ogun ni ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ obinrin naa.












