Ọwọ́ ọ̀lọ́pàá tẹ obìnrin tó jí ọmọ òòjọ́ gbé l'Okitipupa níbí tó tí ń sọmọ ọ̀hún lórúkọ ní Sagamu

afurasi naa

Oríṣun àwòrán, ondo police

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti fi panpẹ ofin gbe obinrin kan lori ẹsun pe o ji ọmọ gbe.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni obinrin naa ti ọjọ ori rẹ to ọdun marundinlogoji ji ọmọ naa gbe lagbegbe Sabo nilu Okitipupa, o si gbe ọmọ naa lọ si ilu Sagamu nipinlẹ Ogun.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ni arabinrin naa gbe ọmọ oojọ naa salọ nigba ti iya ọmọ naa gbe e fun pe ko ba oun gbe e dani, ki oun le sara bu omi sara.

Lasiko tawọn ọlọpaa n fi ọrọ wa a lẹnu, wọn ni arabinrin naa jẹwọ pe eyi kii ṣe akọṣe oun.

O fikun pe oun ti kọkọ ji ọmọ kan gbe loṣu kinni ọdun 2021, ṣugbọn ọmọ naa ku lẹyin ọjọ diẹ.

Ninu ọrọ rẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami sọ pe nibi ti wọn ti n ṣeto isọmọlorukọ fun ọmọ ti wọn ji gbe naa, ni ọwọ awọn ọlọpaa ti ba wọn.

“Arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Abass Issah to n gbe ni agbegbe Arikawe nilu Okitipupa lo wa si agọ ọ̀lọpaa lati fi to awọn ọ̀lọpaa leti pe awọn kan ti ji ọmọ ti oun ṣẹṣẹ bi gbe salọ.

Awọn ọtẹlẹmuyẹ lagọ ọlọpaa nilu Okitipupa bẹrẹ iṣẹ iwadii eleyii to mu ki ọwọ tẹ arabinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Funmi Mogbojuri.

Obinrin yii si lo gbe ọmọ naa salọ si Makun Ṣagamu nipinlẹ Ogun.”

Atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa lori ayelujara

Oríṣun àwòrán, screenshot

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ondo ni arabinrin naa jẹwọ pe ile ọkọ oun loun gbe ọmọ naa lọ.

Nibi isọmọlorukọ ọmọ yii ni awọn ọ̀lọpaa ti de ba a, ti wọn si mu u.

Bakan naa ni wọn tun gbọ pe o ti figba kan ri naa gbe ọmọ ọlọmọ kan ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kinni ọdun 2021.

O gbe ọmọ to kọkọ ji gbe naa lọ si ilu Igbọkọda, nibi to ti gbe e fun arakunrin kan to n jẹ Lucky, ki ọmọ naa to ku lẹyin ọjọ diẹ.

Nibi isọmọlorukọ lọwọ ọlọpaa ti tẹ afurasi naa

Atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa lori ayelujara

Oríṣun àwòrán, screenshot

Obinrin naa bẹbẹ lati sun mọ́jú nílé wa tori o ti maa n wa ọkunrin kan wa sibẹ tẹlẹ

Iya ọmọ ti wọn ji gbe naa, Binta Hassan ṣalaye pe arabinrin ajọmọgbe naa wa si ile awọn nitori pe kii ṣe alejo si ile awọn mọ.

O ni obinrin naa si bẹbẹ lati sun mọju lọjọ ti oun bimọ.

Arabinrin Hassan ṣalaye pe arabinrin ajọmọgbe naa “ni ọrẹ kan ni ile awọn to maa n bẹwo loorekoore, ki arakunrin ọhun to jade laye.

Bi a ṣe gba mọ ara niyi. O wa lalẹ ọjọ ti mo bimọ pe ilẹ ṣu oun si Okitipupa, oun o si ri ibi ti oun le sun.”

A gba a laye lati sun ọkan lara awọn iyara to ṣofo, a fun un ni ounjẹ ljẹ lalẹ ọjọ naa laimọ iṣẹ to fẹ wa ṣe.

Si iyalẹnu mi. Ni aarọ ọ̀jọ keji ti mo fẹ lọ wẹ arabinrin naa ti poora pẹlu ọmọ ti mi o tilẹ tii fun ni ọmu nigba naa.

Lẹyin ọ̀jọ karun un lawọn ọ̀lọpaa mu u.”