Ìyàwó torí owú dánà sun ọkọ rẹ̀, ló bá fẹsẹ̀ fẹ

A fọ́ fèrèsé ilé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ká tó le yọ ọkùnrin tí àfẹ́sọ́nà rẹ̀ dáná sun - Alábàgbélé

Bolu ati Ifeoluwa Bamidele

Oríṣun àwòrán, Osun Police

Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni isẹlẹ kan to waye nigba ti iyawo ile kan, Ifeoluwa dana sun ọkọ rẹ, to n jẹ Bolu .

Ọdun to kọja ni tọkọ taya naa se igbeyawo amọ ti ko tii si ọmọ ni aarin wọn.

Ilu Koka, to wa ni ijọba ibilẹ Ibokun, nipinlẹ Osun ni iṣẹlẹ naa ti waye lẹyin ti wọn ni aṣiri tu si Ifeoluwa lọwọ pe Bamidele ti bi ọmọ kan sita.

Ọjọ Aiku, ọjọ Kẹtadinlogun osu keje ọdun 2022 si ni isẹlẹ naa waye.

Se ni inu ile naa nilu Ibokun si da paroparo lai si ẹyẹ ninu rẹ nigba ti BBC Yoruba de ile naa lai ri ọna wọle tabi ri nikẹni nitosi ibẹ.

Ki lo mu aya dana sun ọkọ rẹ, to fi jade laye?

Iroyin ni afurasi naa fi atẹjade kan soju opo WhatsApp rẹ, nibi to ti sọ pe oun mọọmọ wu iwa naa ni.

Atẹjade ori Whatsapp naa ni “Mi o ki n ṣe oni wahala o, mi o si ṣe iru nnkan bayii ri nile aye mi, amọ Teebam (iyẹn Bamidele) ti sun mi kan ogiri.”

“Nibi ti ọrọ de duro bayii, gbogbo yin ni ẹ maa foju sunkun lori ọrọ awa mejeji, ileri mi niyii.”

Lẹyin eyi ni wọn ni Ife dana sun ọkọ rẹ, ti gbogbo ilẹkun ile pa, to si jade kuro ninu ile naa.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ni lootọ ni isẹlẹ naa waye.

Ọjọ ibi aya rẹ ni ọkunrin naa wa se lati Cairo, ko to pade iku ojiji:

Ileesẹ ọlọpaa ni ọjọ ibi aya rẹ ni ọkunrin naa n se lọwọ to fi mu ọti yo, ti aya rẹ fi raye dana sun.

Yemisi Opalola salaye fun BBC Yoruba pe awọn ẹbi tọkọ taya naa salaye fun awọn pe ilu Cairo, lorilẹede Egypt ni Bolu n gbe.

Ibẹ lo si ti de laipẹ yii lati wa sami ọjọ ibi fun aya rẹ, Ifeoluwa.

O ni ayẹyẹ ọjọ ibi naa ni wọn n se lọwọ, ti Bolu si ti mu ọti yoo, eyi to mu ko rọrun fun iyawo rẹ lati dana sun mọle, ti ko si le dura lati doola ẹmi ara rẹ.

Se ni Ifeoluwa aya rẹ naa si ti gbogbo ilẹkun inu ile nigba to dana sun ọkọ rẹ, to si sa kuro nibẹ.

Bolu, ti aya rẹ dana sun ti jade laye:

Inu ile ti isẹlẹ naa ti waye

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun wa fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba pe Bolu, ọkọ ti iyawo rẹ danu sun ti jade laye.

O ni Bolu gbe ẹmi mi ni ọjọ keji to dele iwosan UCH nilu Ibadan nibi ti wọn gbe lọ lẹyin ti ile iwosan Osogbo Central Hospital, ti wọn kọkọ gbe lọ, pasẹ pe ki wọn gbe kuro lọdọ oun.

O ni awọn alasẹ ile iwosan naa sọ pe ọwọ awọn ko le ka itọju ọkunrin naa, to si daba pe ki wọn maa gbe lọ sile iwosan UCH ni Ibadan.

Opalola ni deede aago mẹrin irọlẹ ni ọkunrin naa ki aye pe o digbose ni ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun osu keje.

A n wa iyawo to dana sun ọkọ rẹ atawọn ẹbi rẹ:

Bakan naa ni Opalola fikun pe obinrin to dana sun ọkọ rẹ naa lo ti na papa bora, ti Kmisana ọlọpaa si ti pasẹ pe ki awọn kede rẹ bi ẹni ti wọn n wa.

O ni ikọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wa nigboro bayii lati se awari Ife, ko le wa sọ ohun to mọ nipa iku ọkọ rẹ naa.

Ileesẹ ọlọpa Osun fikun pe gbogbo awọn ẹbi Ife, to dana sun ọkọ rẹ naa ni wọn ti juba ehoro, ti awọn ko si ri obinrin naa tabi awọn ẹbi rẹ kankan.

“Awa ati awọn ẹbi ọkọ rẹ la dijọ n sisẹ pọ lọwọlọwọ lati mọ ibi to wa, ka si ri mu.

Ni kete ti ọkunrin naa ku, lawọn ẹbi aya rẹ ti salọ, gbogbo inu ile wọn to wa ni Ibokun lo ti da paroparo, wn ti sa kuro nibẹ.

Ọba ilu naa gangan ti fi awọn eeyan sọ ile naa, amọ titi di isinyii, a ko ri ẹnikẹni ninu wọn.”

O fikun pe aburo Ifeoluwa lo kede fun gbogbo mọlẹbi ọkunrin naa pe anti oun ti kun ọmọ wọn mọle, ti aburo obinrin naa si ti salọ.

Inu ile ti isẹlẹ naa ti waye

Alabagbe ṣalaye bi wọn ṣe kọkọ doola Bamidele

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn alabagbe Bolu Bamidele, ti iyawo afẹsọna rẹ dana sun ti ṣalaye bi wọn ṣe ri aye wọ inu ile rẹ.

Wọn ni ṣe lawọn ja ferese ile naa ki wọn to ri ye wọle lati gbe oloogbe naa jade lẹyin ti iyawo afẹsọna rẹ, Ifeoluwa, dana sun un lori ẹsun pe oju rẹ ko gbebikan.

Alabagbe Bamidele kan ni oun pade Ifeoluwa to n fẹrẹ rin lọ laarin adugbo lasiko ti oun n bọ lati ibiṣẹ ni nnkan bii aago meje abọ ọsan.

O ni “Bi mo ṣe n sunmọ ile mi, mo ṣakiyesi eefin to n jade lati inu ile ti Ife n gbe, mo woye ọrọ naa fun iṣẹju diẹ, ki n to ri daju pe ina ti sọ lati inu ile ọhun.”

“Mo tete sare lọ sibẹ, mo ba aburo Ife atawọn agbagba kan,.

Aburo rẹ wa sọ fun mi pe Ife ati ọkọ afẹsọna rẹ ni aawọ ṣugbọn nigba ti oun fẹ lọ pe awọn eeyan lati ba wọn pari aawọ naa, ina ti sọ ninu ile ọhun.”

 “Ife ti fi ibinu fi ile naa silẹ, to si ti gbogbo ilẹkun nigba ti ọkọ afẹsọna rẹ ṣi wa ninu ile ọhun”

Alabagbe naa tẹsiwaju pe “Lẹsẹ kan naa ni mo gbiyanju lati pa ina ọhun, ti mo si kesi awọn eeyan to wa layika.

A da omi ati yẹpẹ si ina naa, bẹẹ naa la n gbiyanju lati ja ferese wọle.”

“A fọ ferese mẹrẹrin to wọ ile naa ki a to ri aye wọle, lẹyin nnkan bii ogoji iṣeju ni a to ri Bamidele yọ.”