"Kìí ṣe èké bíṣọ́ọ́bù ló wa sibi àfihàn Shettima, wọn kò tí ì di gbajúmọ̀ lẹ fi dá wọn mọ̀"

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat
Ikọ ipolongo idibo aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti fesi lori ọrọ to n ja rain pe awọn ayederu biṣọọbu ni wọn gbe wa sibi afihan oludije fun igbakeji aarẹ, Kashim Shettima.
Tinubu ati Shettima ni wọn jijọ n dije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress.
Musulumi si ni awọn mejeeji jẹ.
Ninu ọrọ ti oludari eto iroyin ati ibaraẹnisọrọ ikọ naa, Bayo Onanuga fi sita, o ni awọn iranṣẹ Olorun to wa sibi afihan naa kii ṣe ayederu biṣọọbu, gẹgẹ bawọn kan ṣe n sọ kaakiri.
O ni ''ẹgbẹ APC ṣe afihan Sẹnẹtọ Shettima ati awọn ẹka ipolongo wa fun araalu nibi ayẹyẹ tawọn eeyan peju si''
O fi kun pe gbogbo eeyan lo lanfaani lati wa sibi ayẹyẹ naa eleyi to mu ki ọpọ eeyan wa, ''to fi mọ awọn iranṣẹ Ọlọrun ati awọn mii tawọn alatako n tabuku bayi''.
''A fẹ fi to yin leti pe awọn biṣọọbu to wa kii se ayederu, wọn kii ṣe mọkaliiki tabi awọn to n ta iṣu lọja gẹgẹ bi awọn alaburu ṣe n sọ seti awọn araalu''
''Lootọ wọn kii se eekan ninu ẹsin ṣugbọn awọn naa n gbiyanju lati mu idagbasoke ba iranṣẹ wọn''
Lakotan, Onayiga sọ pe olori ijọ ni wọn, ti wọn si ni igbagbọ pe Naijiria gbọdọ yago fun oṣelu itara ati ẹlẹsinmẹsin.
O wa rọ awọn to n tabuku Tinubu lori isẹlẹ yii pe ki wọn tẹwọgba oṣelu alaafia ati idagbasoke orileede.
Òṣèré tíátà lẹ gbé àṣọ Bíṣọ́ọ́bù wọ̀ níbi ayẹyẹ àfihàn Shettima - CAN

Oríṣun àwòrán, @olaniranfaith
Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN, ti sọ pe awọn biṣọọbu to lọ sibi ayẹyẹ ti wọn ti kede Kashim Shettima gẹgẹ bii oludije igbabkeji Aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ki ṣe ara awọn.
CAN ni awọn eeyan naa ko lọ ṣoju awọn ọmọlẹyin Kristi rara, bi ko ṣe apo ara wọn.
Igbakeji CAN ni ipinlẹ mọkandinlogun lapa iha Ariwa to fi mọ Abuja, alufaa Joseph John Hayab, to tun jẹ Aarẹ CAN ni Kaduna lo sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin.
Ṣaaju ni CAN ti kọkọ tako aba ki oludije sipo Aarẹ ati igbakeji rẹ jẹ Musulumi, eyii ti wọn ni ko bojumu ni Naijiria ti oniruru ẹsin wa.
Wọn ni lootọ ni Bola Tinubu, to n du ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC le lọ ran aṣọ alufaa, ko si gbe wọ oniruru eeyan lọrun, eyii ko sọ pe o tọna.

Oríṣun àwòrán, @Thenichenews
Awọn alawada ni wọn gbe aṣọ biṣọọbu wọ lọrun – CAN
Hayab ni “Awọn ti wọn pe ara wọn ni biṣọọbu ti a ri nibi ti wọn ti fi Shettima han bii igbakeji Tinubu ko mọ bi wọn ṣe n wọ aṣọ biṣọọbu, oṣere tiata lasan ni wọn.”
“Iyalẹnu nla ni iru iwa ti wọn wu yii jẹ fun CAN; lakọkọ, wọn ni alaga CAN ni Borno ṣatilẹyi fun wọn, to jẹ irọ nla, ẹlẹẹkeji, wọn tun parọ pe Bola Ahmed Tinubu ati igabkeji rẹ n lọ ṣepade pẹlu alaga CAN lalẹ ọjọ kan.”
“Alẹ ọjọ yii si jẹ alẹ ọjọ ti alaga CAN yii lọ siluu Alabama l’Amẹrika fun ipade miran.”
Hayab tẹsiwaju pe “Wọn tun parọ pe awọn ṣe ipade pẹlu Baba Adeboye ti ijọ RCCG.”
“T i awọn ọmọ lẹyin Kristi ko ba ṣe pataki, kilode ti wọn fi n pa oniruru irọ bayii?”
“Tinubo le lọ ko aṣọ biṣọọbu si awọn mẹkaniiki atawọn oniṣẹ ọwọ mii lọrun o, ṣugbọn iyẹn ko yi ohun ti an fẹ pada, tii ṣe ootọ ati ododo fun gbogbo ẹsin.”
Lẹyin naa lo ni inu CAN dun pe asiko ijọba awarawa ree amọ ko tọ ki awọn eeyan Tinubu maa pa oriṣiriṣi irọ bayii lati tan awọn ọmọ Naijiria jẹ, nitori irufẹ iwa bẹẹ yoo lẹyin.












