Ìdí tí mo fi ń wọ Adeleke lọ sí ilé ẹjọ́ rèé...Oyetola

Oyetola ati Adeleke

Oríṣun àwòrán, Oyetola and Adeleke/Facebook

Agbẹjọ́rò gómìnà Gboyega Oyetola, Kunle Adegoke ti ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fẹ́ fi mórílé ilé ẹjọ́ lórí èsì ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun.

Kunle Adegoke, lasiko tó bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ lónìí ní nígbà tí àwọn rán àwọn ènìyàn káàkiri ibùdó ìdìbò ní ọjọ́ ìdìbò, ìròyìn tí wọ́n mú wá fún àwọn ló fa ìgbésẹ̀ tí àwọn fẹ́ gbé yìí.

Adegoke ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló gbà wí pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọ̀wọ́ rọsẹ̀, ó ní ibi tí oníkálukú dúró sí nìkan ló mọ̀ mọ, wọn kò lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ibòmíràn.

Ó ní àwọn ní ìgbágbọ́ wí pé àwọn àìṣedédé kan wáyé èyí tí àwọn ní ẹ̀rí fún, tí àwọn yóò si gbé kalẹ̀ nílé ẹjọ́ láìpẹ́.

Ó fi kun pé àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí ni òun àti àwọn akẹgbẹ́ òun ń ṣàgbéyẹ̀wò lọ́wọ́, kí àwọn tó gba ilé ẹjọ́ lọ.

Ó ní àwọn ẹ̀rí yìí fi hàn pé àwọn àìṣedédé yìí ló ṣe àkùdé tí kò jẹ́ kí ètò ìdìbò náà lọ bó ṣe yẹ kó lọ nítorí rẹ̀ ni gómìnà fi rò ó wí pé ó yẹ kí àwọn lọ sílé ẹjọ́.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣèrú ìbò

“Àwa tí a rán ènìyàn káàkiri ìgboro, láti ojúlé dé ojúlé, ìletò dé ìletò, láti àpótí ìdìbò kan sí òmíràn, a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìròyìn tí ó wà lọ́wọ́ wa.”

“Ó ṣeéṣe ká tún ní ìwé tó fìdí ẹ múlẹ̀ tí gómìnà ní ìgbàgbọ́, tí àwa ọmọ náà ni ìgbàgbọ́ pé àwọn àìṣe dédé kan wáyé nínú ètò ìdìbò náà.”

Adegoke tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló ṣèrú ìbò ní àwọn ibùdó ìdìbò kọ̀ọ̀kan, tí àwọn sì ní àwọn ẹ̀rí tó fi ìdí èyí múlẹ̀.

Amofin Kunle Adegoke

"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbẹjọ́rò wa ló rí àwọn kùdiẹ̀kudiẹ tó wáyé lọ́jọ́ ìdìbò"

Bákan náà ló tún ní àwọn kò ì tíì le sọ pàtó iye agbẹjọ́rò tí yóò bá àwọn lọ sí ilé ẹjọ́ nítorí àwọn ṣì ń ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn èsì ìdìbò lọ́wọ́.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbẹjọ́rò ló ti ń fi ìfẹ́ hàn láti lọ ṣojú gómìnà Oyetola nílé ẹjọ́.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbẹjọ́rò yíì ló rí gbogbo àwọn kùdiẹ̀kudiẹ tó wáyé níbi ètò ìdìbò náà.

ìdí nìyẹn tí gbogbo wọn sì ṣe ń fi ìfẹ́ hàn láti ṣẹjọ́ fún Oyetola.

Adegoke ní àwọn ti kọ orúkọ àwọn àádọ́ta agbẹjọ́rò kalẹ̀ báyìí tí yóò ṣojú Oyetola àt pé ó ṣeéṣe kí àwọn tún rí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Bẹ́ẹ̀ náà ló tún ní àwọn agbẹjọ́rò tí yóò máa tẹ̀lé àwọn lọ sí ilé ẹjọ́ le má tò bẹ́ẹ̀ tí àwọn bá ri wí pé ilé ẹjọ́ náà kéré àti wí pé àwọn máa nílò àwọn tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì.

Ó dámi lójú wí pé a máa borí

Adegoke tẹmpẹlẹ mọ́ wí pé ó dá òun lójú wí pé àwọn yóò borí, nígbà tí àwọn bá dé ilé ẹjọ́ nítorí gbogbo ẹ̀rí tó wà níwájú àwọn fi hàn wí pé Oyetola pegedé níbi ètò ìdìbò náà.

Ó ní ìdúnnú ni àwọn ń bá lọ sí ilé ẹjọ́ báyìí pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí tí àwọn ti ní.

Oyetola ń wọ́ Adeleke relé ẹjọ́ lórí ìbò gómìnà l‘Osun

Gboyega Oyetola àti Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Oyetola and Adeleke Facebook

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe àwọn agbẹjọ́rò tí yóò ṣojú gómìnà Gboyega Oyetola ní ilé ẹjọ́ kò ní dín ní àádọ́ta.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bó ṣe fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò sípò gómìnà tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Osun lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Keje, ọdún 2022.

Oyetola ní ìjáwé olúborí ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP níbi tí ètò ìdìbò náà níbi tí INEC ti kéde Ademola Ademola bí gómìnà tí wọ́n dìbò yàn.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ọ̀kan lára àwọn ikọ̀ amòfin Oyetola, Kunle Adegoke ní àwọn ti ń ṣe àgbéyẹ̀wó gbogbo àwọn èsì ìdìbò náà.

Adegoke ní láìpẹ́ ni àwọn yóò mórí lọ sílé ẹjọ́ ní kété tí àwọn bá ti parí gbogbo ìwádìí àwọn lórí bí INEC ṣe kéde Ademola Adeleke bí ẹni tí àwọn ènìyàn dìbò yàn.

Ó ní ikọ̀ àwọn amòfin àwọn ti ń ṣiṣẹ́ takuntakun lọ́wọ́ láti ṣàgbéyẹ̀wò èsì ìdìbò náà.

“A ṣì ń ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn èsì ìdìbò náà lọ́wọ́. Ní irú ìdìbò bí èyí àwọn nǹkan tó rọ̀ mọ pọ̀ púpọ̀ tó sì gba kí ènìyàn fara balẹ̀ dada kí a tó gbé ìpinnu wa jáde.”

Ó ṣàlàyé pé agbẹjọ́rò àgbà, Biodun Layonu ni yóò ṣaájú ikọ̀ agbẹjọ́rò náà tí àpapọ̀ agbẹjọ́rò tí yóò kópa níbi ẹjọ́ náà yóò lé ní àádọ́ta.

“Ṣẹ mọ̀ wí pé ẹjọ́ ìdìbò kìí ṣe nǹkan yẹpẹrẹ nítorí náà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbẹjọ́rò ló bá ṣtán láti jà fún wa la ma gbà, ó ṣeéṣe kó tó àádọ́ta tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ.”

Ẹ ó rántí wí pé ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹtàdínlógún ní àjọ elétò ìdìbò, INEC kéde Ademola Adeleke gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ọjọ́ Àbámẹ́ta nígbà tó ní ìbò 403,371.

Gómìnà Gboyega Oyetola tó ń wá ìyànsípò fún sáà kejì ló gba ipò kejì nígbà tó ní ìbò 375,027 gẹ́gẹ́ bí INEC ṣe kéde.

Lẹ́yìn ìkéde INEC ni Oyetola gba tẹnu agbẹnusọ rẹ̀, Ismaila Omipidan fi àtẹ̀jáde síta láti rọ àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ láti ṣe sùúrù wí pé àwọn ń ṣe àyẹ̀wò àwọn èsì ìdìbò náà lọ́wọ́.

Ó ní ẹgbẹ́ àwọn máa fèsì lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe àgbéyẹ̀wó gbogbo èsì ìdìbò náà tán láti mọ ìgbésẹ̀ tí wọ́n máa gbé.

Ohunkóhun tí Oyetola bá ti ṣe, ló bá wa lára mu – APC

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìpinnu Oyetola láti pé èsì ìdìbò náà lẹ́jọ́, agbẹnusọ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Osun, Kola Olabisi ní gbogbo ìgbésẹ̀ tí Oyetola báti gbé lórí ọ̀rọ̀ náà ni àwọn fara mọ́.

Olabisi ní ohun tí Oyetola bá ti sọ, ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà ló sọ àti pé ìpinnu ẹgbẹ́ kò le yàtọ̀ sí ohun tí Oyetola bá sọ.

Ẹ ò gbọdọ̀ jẹ́ kí APC yí èsì ìdìbò mọ́ ọ yín lọ́wọ́ – Adeleke ṣèkìlọ̀ fún INEC

Gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Ademola Adeleke ti ṣèkìlọ̀ fún àjọ INEC láti má gbìyànjú àti tọwọ́ bọ ohunkóhun nínú èsì ìdìbò ìpínlẹ̀ Osun.

Ó ní wọ́n kò gbọdọ̀ gbà láti jẹ́ kí ẹgbẹ́ APC mú àyípadà kankan bá èsì ìdìbò náà láti fi mú kí èsì náà fì sí ọ̀dọ wọn.

Àtẹ̀jáde kan tí alága ikọ̀ ìròyìn Adeleke, Ọmọọba Diran Odeyemi fi síta ní àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ òṣèlú APC kan ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú INEC láti yí èsì ìdìbò tó gbé Adeleke wọlé.

Odeyemi fẹ̀sùn kan INEC ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan wí pé àwọn APC ti ń sùgbá wọn láti yí èsì ìdìbò.

Adeleke wá rọ alága àjọ INEC, Mahmood Yakubu láti darí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láti kó gbogbo èsì ìdìbò náà lọ sí oríkò wọn ní ìpínlẹ̀.

Àmọ̀ APC ti ní kí Adeleke mú ẹ̀rí wí pé àwọn fẹ́ yí èsì ìdìbò jáde tó bá jẹ́ wí pé bẹ́ẹ̀ lórí àti wí pé kò yẹ kí ẹ̀rù máa bà wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n ti wọlé ìbò tí wọn kò bá ní ẹbọ lẹ́rù.

Ṣíṣe àkójọ àwọn agbẹjọ́rò kò tu irun kan lára wa – PDP

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ìpínlẹ̀ Osun ti ní gbogbo ìgbìyànjú APC láti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbẹjọ́rò jọ kò tu irun kan lára àwọn.

Akọ̀wé ikọ̀ amòfin PDP ìpinlẹ̀ Osun, Hashim Abioye ní ẹ̀tọ́ APC ní láti pé PDP lẹ́jọ́ ṣùgbọ́n digbí ni àwọn náà wà láti jẹ́ ìpè wọn.

Abioye ni ẹ̀rù kò ba àwọn rárá àti pé àwọn náà ti ń múra kalẹ̀ dè wọ́.