Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé tí Adedoyin kò fi yọjú sílé ẹjọ́ l‘Ọjọ́rùú

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke and Rahmon Adedoyin/Facebook
Igbẹjọ iku Timothy Adegoke to waye lọjọru ni afurasi gboogi ninu ẹjọ naa, Rahmon Adedoyin ko ti yọju sile ẹjọ.
Adedoyin lo n jẹjọ pẹlu awọn afurasi mẹfa miran lori ohun to se okunfa iku Adegoke nile itura Hilton, tii se ti Adedoyin.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn osisẹ ọgba ẹwọn ko awọn afurasi mẹfa yoku yọju sile ẹjọ, amọ wọn salaye pe ohun to faa, ti wọn ko fi mu Adedoyin yọju.
Awọn afurasi to yọju sile ẹjọ ni Magdalene Chiefuna, Adeniyi Aderogba, Oluwole Lawrence, Oyetunde Kazeem, Adebayo Kunle ati Adedeji Adesola.
Ara Adedoyin ko ya, ni ko se yọju sile ẹjọ - Osisẹ ọgba ẹwọn
Ọkan lara awọn osisẹ ọgba ẹwọn to ko awọn afurasi yoku wa sile ẹjọ yọ kẹlẹ sọ fun awọn akọroyin pe o nidi ti Adedoyin ko fi yọju sile ẹjọ.
Osisẹ ọgba ẹwọn naa salaye pe ara Adedoyin ni ko ya, ti ojojo si n se ogun rẹ.
Adedoyin lo sọ pe o n se aisan ti ko darukọ rẹ ni ọgba ẹwọn Ilesa ti wọn fi oun ati awọn afurasi mẹfa yoku pamọ si.
Igba keji ree ti akude yoo wọ igbẹjọ iku Timothy Adegoke:
Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kẹfa ni igbẹjọ iku Adegoke waye gbẹyin.
Lọjọ naa si ni Adajọ Adepele Ojo to n gbọ ẹjọ naa kọkọ kede saaju pe oun yoo sọ idajọ oun lori ibeere ikọ olupẹjọ ni ọjọ Kẹrinla osu keje ti wọn sun igbẹjọ naa si.
Adajọ naa ni lọjọ Kẹrinla osu Keje yii ni oun yoo sọ boya ki ikọ olupẹjọ se atunse si awọn ẹsun to fi kan awọn afurasi naa tabi da ibeere naa nu.
Ọrọ yii lo ti n fa awuyewuye laarin ikọ olupẹjọ ati olujẹjọ.
Bi o tilẹ jẹ pe ikọ olupẹjọ n beere fun asẹ ile ẹjọ lati se atunse sawọn ẹsun to fi kan awọn afurasi naa nile ẹjọ amọ ikọ olujẹjọ n tako ibeere naa.
Amọ ijoko igbẹjọ naa ko le waye ni ọjọ Kẹrinla osu Keje nitori adajọ Ojo rinrinajo lọ soke okun amọ o ti pada de bayii.
Adajọ Adepele Ojo ti wa sun igbẹjọ iku Timothy Adegoke naa siwaju di ọjọ Kẹwa osu osu Kẹwa ọdun 2022 ta wa yii.
Bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe lọ rèé lónìí

Ìgbẹ́jọ́ lórí Timothy Adegoke tẹ̀síwájú lónìí, Ramon Adedoyin kò yọjú sí ilé Ẹjọ́ lónì
Igbẹjọ si n tẹsiwaju lati se awari iku to pa Timothy Adegoke, tii se akẹkọ gboye imọ ijinlẹ keji ni fasiti Obafemi Awolowo.
Adegoke lo ku sile itura Hilton to wa nilu Ile Ife, ti awuyewuye si n lọ lori iru iku to pa ọkunrin naa lọjọ aipe.
Bi o tilẹ jẹ pe igbẹjọ iku Adegoke naa n tẹsiwaju lonii nile ẹjọ giga ilu Osogbo lonii amọ olujẹjọ gboogi lori ẹjọ naa, Ramon Adedoyin, tii se ẹni to ni ile itura ti Timothy ku si, ko yọju sile ẹjọ.
Sugbọn wọn ko awọn afurasi mẹfa yoku wa sile ẹjọ lati tẹsiwaju lori ẹjọ naa.
Falana ni àwọn iwe apilẹkọ awọn agbẹjọro lati kadi atotonu wọn nilẹ, ko tii si
Agbejoro agba, Femi Falana to n soju ikọ olupẹjọ ati mọlẹbi oloogbe yọju sì ilé ẹjọ giga ipinlẹ Osun naa.
Amọ o rọ adajọ to n gbọ ẹjọ ọhun pe igbẹjọ naa ko le tẹsiwaju nitori gbogbo awọn ọ̀rọ̀ ikẹyin to yẹ ki awọn kọ dani wa sile jọ, lati kadi atotonu awọn nilẹ, ni ko tii setan.
Falana wa rọ adajọ naa lati sun jọ ọhun siwaju fun igba diẹ, ki wn le ni anfaani lati ko gbogbo iwe to yẹ jọ lori ẹjọ naa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Falana ni awọn agbẹjọro gbogbo lori ẹjọ naa lo panupọ ba adajọ sọrọ pe ko sun ẹjọ naa siwaju.
O ni awọn ọrọ asọkẹyin to yẹ ki awọn kọ wa sile ẹjọ lati kadi igbẹjọ naa nilẹ ni ikọkan awọn agbẹjọro ọhun ko tii pari.
Falana fikun pe ile ẹjọ n lọ fun isinmi ọlọdọọdun rẹ, nitori naa ni igbẹjọ naa yoo tun se se diẹ, ko to waye.
Idi si ree ti Adajọ se sun igbẹjọ iku Timothy Adegoke naa siwaju di ọjọ Kẹwa osu osu Kẹwa ọdun 2022 ta wa yii.
Bẹẹ ba gbagbe, a ti kọkọ sọ fun yin saaju lasiko igbẹjọ to kọja pe o seese ki adajọ kede ọjọ ti yoo gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ naa, lasiko igbẹjọ toni.
Amọ eyi ko seese mọ nitori bi awọn agbẹjọro to yẹ ki wọn kọ ọrọ apilẹkọ wọn wa sile ẹjọ, lati kadi atotonu wọn nilẹ , ni ko ko awọn iwe naa dani wa sile ẹjọ.

















