Àwọn àgbẹ̀ yarí fún ìjọba Ondo lórí bó ṣe ń ta ilẹ̀ oko wọn

Ọrọ̀ ajé dẹnukọlẹ̀ ní Idanre nígbà táwọn àgbẹ̀ fi ẹ̀hónú hàn lórí bí ìjọba ṣe ń ta ilẹ̀ oko wọn

Awọn agbẹ to n fi ẹhonu han

Eto ọrọ aje lo dẹnu kọlẹ nilu Idanre nipinlẹ Ondo loni ọjọ iṣẹgun nibi awọn agbẹ ati pupọ ninu olugbe ilu naa ṣe tu jade lati ṣe iwọde ifẹhonu han tako bi wọn ṣe ni ijọba ta ilẹ ti wọn fi n dako.

 Awọn opopona to gbajumọ ni Alade, Odode ati Atọṣin Idanre ni wọn di pa ti ko si si igbokegbodo ọkọ lakoko ifẹhonu han ọun.

 Awọn iwe ilewọ ti wn gbe lọwọ, ti wọn ṣe afihan rẹ nibi ifẹhonu han naa lo ni awọn ọrọ wọnyii.

“ijọba ipinlẹ Ondo, ẹ fi oko wa silẹ fun wa”, “iṣẹ agbẹ nikan ni a fi n ṣ'aye”, “ki la o maa jẹ tẹẹ ba le wa kuro loko” ati bẹẹ bẹẹ lọ.

A ko ni gba ki ileesẹ ijọba kankan sisẹ ni Idanre l‘Ọjọru - Awọn agbẹ

Agbẹnusọ awọn agbẹ naa, ọgbẹni Smart Aribigbola, ni lati bi ọgbọn ọdun sẹyin lawọn ti n dako ninu igbo ọhun, ti ajọṣepọ to munadoko si wa laarin awọn ati gbogbo ijọba to ti n jẹ nipinlẹ naa.

 O ni “ko si ijọba ti a ki n ba ṣe lati ọdun taa ti wa lori ilẹ yi. A le ni ẹgbẹrun lọna ogun, to si jẹ pe gbogbo wa lo n san gbogbo owo ti ijọba ni ka san.

Ohun iyalẹnu lo jẹ pe ijoba le fun awọn kan laṣẹ lati le wa kuro lori ilẹ naa, ki wọn si maa ba awọn nkan ti a gbin jẹ”.

Aribigbola to ni ijọba ko pe wọn si ipade apero kankan ṣaaju akoko yii fikun pe lati ọla lọ, awọn ko nii gba ki ileeṣẹ ijọba kankan ṣiṣẹ nilu naa.

Bẹẹ lo ni wọn ko nii gba ki ẹnikẹni san owo ori mọ nilu naa.

Iya agba kan, Roseline Akindana Johnson, to dari awọn obirin nibi ifẹhonu han naa wipe ọgbin koko ni awọn mọ gẹgẹ bi iṣẹ ti wọn ko si ni ọna miran lati gbọ bukata wọn.

Aw agbẹ to n fi ẹhonu han

Roseline ni “lati igba ti ọkọ mi ti ku soju ogun ni mo ti lọ n dako lori ilẹ yii, ti mo si n san gbogbo owo to tọ fun ijọba.

Bi awọn ọmọ wa ṣe n ṣetan ileewe naa ni wọn n darapọ mọ wa.

A ko fẹ ki jagidijagan ati idigunjale o pọ laarin ilu la ṣe n rọ ijọba ki wọn fun wa nilẹ wa, ki wọn ma si ba awọn nkan ọgbin wa jẹ”.

Ifẹhonu han naa, ti wọn ni ko nii dopin ayafi ti ijọba ba dawọn lohun, ni yoo tẹsiwaju lọla.

Atunto la fẹ se, a ko gba ilẹ yin - Ijọba Ondo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, oluranlọwọ agba fun gomina ipinlẹ Ondo lori ọrọ to nii ṣe pẹlu iṣẹ agbẹ ati idokowo nipa ere oko, Alufa Akin Olotu ti wa fesi fawọn agbẹ naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Olotu ni ijọba ko nii le ẹnikẹni kuro lori ilẹ ti wọn n dako si ninu igbo ọba lagbeegbe naa.

O ni ahesọ lasan ni pe ijọba fẹẹ le awọn agbẹ kuro nigbo ọba tori wọn ti ta ilẹ naa.

Amọ o ni ṣe ni ijọba fẹẹ ṣe atunto ti yoo mu ki awọn to n gbin irufẹ eso kan naa wa ni agbeegbe kan, bi wọn ti n ṣe lawọn ilu to ni idagbasoke jakejado agbaye.

Amugbalgbẹ gomina naa ni eyi yoo jẹ ki ijọba le ṣe ohun to tọ fun wọn, yoo si jẹ ki awọn olulanilọyẹ nipa eto ọgbin le ṣe iṣẹ wọn doju ami.

Olotu wipe “ọpọ igba la ti ba wọn ṣe ipade lofiisi gomina ati ni aafin Ọwa ti ilu Idanre.

Alaye lẹkunrẹrẹ la si ṣe fun wọn lori gbogbo igbesẹ ti ijọba n gbe, bo tilẹ jẹ pe ọna ti ko tọ ni awọn agbẹ naa ba wọ igbo ọba.

Ijoba gomina Akeredolu lo si ni ki gbogbo wọn waa fi orukọ silẹ.

Kii si ṣe ilu Idanre nikan ni ijọba ti ṣe eyi, saaju niru igbesẹ yi ti waye ni ilu Ọwọ, Ọsẹ, Akoko, Odigbo ati Okitipupa.

Awọn to n gba owo lọwọ alejo lati fun wọn nilẹ ni Idanre lo n fa laasigbo yi, ijọba o si nii gba ki wọn di eto ti yoo maye dẹrun fun awọn araalu lọwọ”.

Awọn agbẹ to n sewọde
Buhari, ẹnu lásán kò tó dín àkàrà ààbò tó péye, di àmùrè láti ṣe ohun tó yẹ - Afẹnifẹre
Aworan aarẹ Buhari nibi to ti n ba awọn ọmọ ogun Naijiria to kẹkọ jade sọrọ ni Jaji

Oríṣun àwòrán, Facebook/Armiyau Shuaibu

Ẹgbẹ to n wa idagbasoke ọmọ Yoruba nni, Afenifere ti tun paroko ọrọ ransẹ si aarẹ Muhammadu Buhari pe ko wa wọrọkọ fi ṣada lori ipenija aabo to n koju ilẹ naa.

Afẹnifẹre ni eyi ti aarẹ n fẹnu lasan doju ija kọ awọn agbesunmọmi to gẹ, ko gbe igbesẹ ti yoo dẹkun ipenija aabo ni kiakia.

Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Jare Ajayi ni asiko to bayi ki aarẹ sinmi fifi ọrọ aṣẹ nikan ranṣẹ fawọn ologun, ko gbe igbesẹ lati fi koju agbesunmọmi.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ọrọ aṣẹ pipa lati ẹnu aarẹ ko jẹ tuntun mọ si awọn ọmọ Naijiria nitori ko ṣẹṣẹ maa sọ fun awọn ologun lati fofin si agbesunmọmi, ti eleyi ko si mu iyatọ kankan wa.

Koko ọrọ ti ẹgbẹ yii n ta mọ eti aṣọ aarẹ ko ṣẹyin bo ti ṣe tun fẹnu paṣẹ fawọn ọga ileesẹ ologun laipẹ yii, nibi ayẹyẹ ikẹkọ jade awọn ọmọ ologun agba labẹ eto idanilẹkọ Course 44 ti ileẹkọ ọmọ ogun Naijiria to wa ni Jaji ni ipinlẹ Kaduna.

Lasiko ti aarẹ n ba awọn to kẹkọ jade yi sọrọ, o ni ''O foju jọ pe awọn agbesunmọmi lati ẹyin odi ti wọn fẹ da wahala silẹ ni Naijiria, ni wọn wa nidi ikọlu to waye laipẹ yi''

Iru ọrọ yii ko ṣẹṣẹ maa jade lẹnu aarẹ gẹgẹ bi ẹgbẹ Afẹnifẹrẹ ti ṣe sọ, ti nkankan ko si tẹyin rẹ bọ lẹyin ti aarẹ ba ti sọ tan.

Afẹnifẹre tẹsiwaju pe ko yẹ ki Naijiiria koju ipenija agbesunmọmi kanni pe awọn to wa ni ijọba mojuto ojuṣe wọn bo ṣe yẹ.

O ni lootọ ni ijọba Buhari gbiyanju lati koju ipenija aabo to koju Naijiria ṣugbọn ọwọ yẹpẹrẹ ti wọn fi mu awọn agbesunmọmi ti mu ki ipa ma ka wọn rara.

O ni eleyi lo mu ki wọn gbalẹ lawọn agbegbe kan ni ariwa Naijiria ni paapa Sokoto,Kaduna, Borno, Niger, Zamfara ati awọn ibomiran.