Wo adarí ìlú mẹ́jọ tíjọba rán lọ sílé torí àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú agbébọn

Ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara ti ni ki Emir Birnin, Yandoton Tsafe lọ rọọkun nile fẹ́sùn wí pé ó yan gbajúgbajà agbébọn gẹ́gẹ́ Emir àwọn Fulani ní agbègbè náà.
Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Yandoton Tsafe yan Adamu Aliero gẹ́gẹ́ bí Emir àwọn Fulani tó wà ní agbègbè rẹ̀ níbi ayẹyẹ ńlá kan.
Ìròyìn ní àwọn lóókọ lóókì nínú ìjọba ló báwọn kópa níbi ayẹyẹ náà.
Ẹ̀wẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà, tí wọ́n sì ní ìwà àìtọ́ bí Emir náà ṣe fi ẹni tí àwọn ènìyàn mọ̀ wí pé ajínigbé ni jẹ oyè.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Katsina tó pààlà pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Zamfara ní àwọn ti ń wá Adamu Aliero ní ọjọ́ pípẹ́ fẹ́sùn wí pé ó lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Katsina, Gambo Isa sọ fún BBC wí pé Adam Aliero wà lára àwọn ajínigbé tó máa ń pa ènìyàn tí wọ́n sì tún máa ń fi wọ́n sí àhámọ́ láti bèrè owó ìtanràn.
Isa ní àwọn ti ń wá Aliero tipẹ́ fún ìwà ìgbéṣùmọ̀mí tó hù ní Kadisau níbi tó ti pa ènìyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún.
Wọ́n ti máa ń fẹ̀sùn kan àwọn olóyè wí pé wọ́n máa ń ran àwọn agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí lọ́wọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ láabi wọn.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina àti Zamfara ti bẹ̀rẹ̀ sí ní yọ àwọn olóyè tí wọ́n bá ti kẹ́fín wí pé wọ́n ṣàtìlẹyìn fún àwọn ọ̀daràn.
Yàtọ̀ sí Emir Birnin tí wọ́n yọ nípò, àwọn Emir tí wọn ti rọ nípò fẹ́sùn wí pé wọ́n ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn agbébọn nìyí:
Emir mẹ́jọ tó ǹ najú nílé torí ṣíṣe ọ̀rẹ́ pẹ̀lú agbébọn
Emir Zurmi

Emir ìlú Zurmi, Atiku Abubakar jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Emir tí ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara to n naju nile wí pé ó ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn agbébọn.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara ní gómìnà Bello Matawalle ti gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ lábẹ́ ìdarí igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Ibrahim Wakkala láti ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí ọba náà lọ́rùn.
Lẹ́yìn ìgbà náà ni ìjọba ní kí Bello Suleiman gba àkóso ìlú náà tí wọ́n sì póró òfin gbé Abubakar.
Emir Dansadau

Ní ọjọ́ kìíní, oṣù Kẹfà ni gómìnà Bello Matawalle ti ìpínlẹ̀ Zamfara ní kí Emir ìlú Dansadau lọ rọ́kún nílé fún ìgbà kan ná.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn kan ọba náà wí pé ó ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn agbébọn.
Bákan náà ni ìjọba ti gbé ìgbìmọ̀ tó ma ṣèwádìí ọba náà lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án dìde.
Emir ìlú Maru

Séríkí ìlú Maru ni ọmọọba tí ìjọba PDP ní ìpínlẹ̀ Zamfara kọ́kọ́ rọ̀ lóyè lórí ipa tó kó lórí ọ̀rọ̀ ààbò ní ìpínlẹ̀ náà.
Ní oṣù kẹjọ ọdún 2019 ni ìjọba rọ Emir Maru, Abubakar Chika lóyè fẹ́sùn wí pé ó jà àwọn ènìyàn tó jọba lé lórí lulẹ̀ nípa bó ṣe ń dọ̀rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn agbébọn tó ń ṣekúpa wọ́n.
Àmọ́ Emir náà jìyàn àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án.
Olóyè Kanoma
Lára àwọn tí ìjọba Zamfara rọ̀ lóyè pẹ̀lú Emir Maru ni baálẹ̀ ìlú Knoma, Alhaji Lawal Ahmad.
Ìgbìmọ̀ tó ṣèwádìí wọn ní àwọn ajínigbé ń lo ọba náà láti gba owó lọ́wọ́ àwọn ènìyàn.
Ní ìlú Nasarawa Mailayi
Dagacin ti ìlú Nasarawa Mailayi, Bello Kiyawa wà lára àwọn tí ìjoba rọ̀ lóyè papọ̀ pẹ̀lú Emir Zurmi.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n ní wí pé wọ́n lẹ̀dí apopọ̀ pẹ̀lú àwọn agbébọn.
Emir Kanwa War àti Marafan Bakura
Nínú oṣù kìíní ọdun 2020ni ìjọba rọ Alhaji Bello Garba Kanwa tíí ṣe Emir Kanwa war àti Alhaji Muhammad Bello Yusuf tó jẹ́ Marafan tí Bakura lóyè.
Ìjọba ní wọ́n lòdì síòfin ìpínlẹ̀ náà lórí ọ̀rọ̀ ààbò ni àwọn ṣe yọ wọ́n.
Emir Fawa
Ní oṣù Karùn-ún, ọdún 2021 ni ìgbìmọ̀ Katsina lápapọ̀ rọ Emir Fawwa, Alhaji Yusuf Lawal lóyè fún ìbáṣepọ̀ tó ń ní pẹ̀lú àwọn agbébọn tó ń da ìpínlẹ̀ Katsina láàmú.
Wọ́n ní àwọn gbé ìgbésẹ̀ yìí láti fi han ìjọba wí pé àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìwà àwọn oníṣẹ́ láabi náà.
Emir fi òyè dá afurasí ajínigbé lọ́lá, ló bá wọ́ gàù lọ́dọ̀ ìjọba
Ìjọba Zamfara gba láwàní lórí Emir, ó ní kó lọ rọọ́kún nílé

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ijọba ipinlẹ Zamfara ti kede pe ki Emir ti ilu Birnin Yandoto, nijọba ibile Tsafe, Aliyu Marafa lọ rọ kun nile fun igba diẹ.
Idi ni pe Emir naa fi afurasi ọga awọn agbegbọn kan jẹ oye.
Akọwe ijọba ipinlẹ Zamfara, Kabiru Sardauna lo fi ọrọ naa sita fun awọn akoroyin lọjọ Aiku.
Afurasi agbegbọn naa ti orukọ rẹ jẹ Aleru ni Emir fi jẹ oye Sariki Fulani gbogbo agbegbe Yandoto.
Ayẹyẹ ifinijoye naa, ti fọtọ rẹ ti bọ si lori ayelujara lo gbodi lara awọn ọmọ orilẹede Naijiria, ti ọpọ eeyan si bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ Emir naa.
Ọpọlọpọ awọn afurasi agbebọn ni wọn wa nibi ayẹyẹ ifinijẹoye Aleru, lati ṣe ajọyọ pẹlu ọga wọn ti o jẹ oye.
Sardauna ni lẹyin ti awọn ni ki Emir naa lọ rọ kun nile fun igba diẹ, Gomina Bello Matawalle ti fi ọwọ si igbimọ kan lati ṣe iwadi lori idi ti Emir Marafa fi igbe igbesẹ naa.
Ninu awọn ọmọ igbimọ naa la ti ri Yahaya Goro tii se Alaga igbimọ naa ati Musa Garba to jẹ Akowe igbimọ pẹlu awọn ọmọ igbimọ miran.
Ijọba ipinlẹ Zamfara ti wa yan Alh Mahe Garba Marafa lati ma tukọ isakoso gẹgẹ bi olori abule Yandoto, titi iwadi yoo fi pari.
“Ki iwadi to pari, Alh Mahe Garba Marafa ni a yan lati ma tukọ gbogbo agbegbe Yandoto gẹgẹ bi Emir.”















