Marburg Virus: Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa àrùn pọ̀jẹ̀-pọ̀jẹ̀ tó ṣekúpa èèyàn mẹ́fà ní Rwanda

Iléeṣẹ́ ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè Rwanda ni èèyàn mẹ́fà ló ti pàdànú ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àìsàn "Marburg virus".
Sabi Nsanzimana ní ọ̀pọ̀ àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn náà ló jẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ìlera.
Èèyàn ogún ni iléeṣẹ́ ìlera náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti ní àìsàn ọ̀hún láti ìgbà tí wọ́n ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì.
Marburg jẹ́ àìsàn tó wà tó fara jọ Ebola. Èèyàn lè ko látara èso, ẹyẹ àdán àti ti omo ara ẹni tó bá ní àìsàn náà bá kan èèyàn lára.
Lára àwọn àmì àti àpẹẹrẹ rẹ̀ tí èèyàn tó bá ni le ní ni ibà, ara ríro, ìgbẹ́ gbuuru, èébì.
Bákan náà ni ó le ṣekúpa èèyàn nígbà tí èèyàn bá ti pàdánù ẹ̀jẹ̀ púpọ̀.
Àjọ ìlera àgbáyé, World Health Organization, WHO ní kò ì tíì sí oògùn láti fi tọ́jú àìsàn Marburg àmọ́ wọ́n ní iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣe oògùn tí yóò kojú rẹ̀.
Rwanda ní àwọn ti ń ṣe ìwádìí láti túnbọ̀ mọ àwọn tó bá ní àìsàn náà lójùnà àti dènà ìtànkálẹ̀ rẹ̀.
Wọ́n rọ àwọn èèyàn láti wà ní tojú tìyẹ́, máa fọ ọwọ́ wọn lóòrè kóòrè pẹ̀lú omi tó mọ́ àti ọṣẹ tàbí sanitáísà.
Bákan náà ni wọ́n ní kí wọ́n fi ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n bá rí tó bá jọ àìsàn Marburg tó àwọn aláṣẹ létí.
Ní ọdún 2023, Tanzania ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ àjàkálẹ̀ àìsàn náà, tí èèyàn mẹ́ta sì pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ rẹ̀ lọ́dún 2017 ní Uganda.
Àwọn nǹkan tó yẹ ko mọ̀ nípa Marburg
Bi ajakalẹ arun Coronavirus to ba ilẹ Afirika finra se n palẹmọ kuro, arun mii ti wọn n pe ni Marburg, tun wọle de.
Awọn oṣiṣẹ eleto ilera lorilẹede Guinea ti fidi rẹ mulẹ pe arun Margurg ti gba orilẹede naa wọ apa iwọ oorun Afirika.
L.ọwọlọwọ bayii, ijọba orilẹede Ghana ti fi eeyan bii ọgọrun si ipamọ lẹyin tawọn osisẹ eleto ilera fidi rẹ mulẹ pe eeyan meji ti ko kokoro arun iba asekupani Marburg yii.
Idi ree ti BBC Yoruba fi se akọjọpọ koko pataki to jẹ kẹ mọ ni[pa arun asekupan Marburg, ohun to n faa, ami idamọ rẹ ati ibi to ti sẹ wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nibo ni arun Marburg ti ṣẹ̀ wá?
Ilu kekere kan ti wọn n pe ni Marburg to wa ni orilẹede West Germany ni wọn ti kọkọ kẹẹfin arun asekupani naa ldun 1967.
Awọn eeyan to kọkọ fori sọta arun yii ni wọn jẹ osisẹ ileesẹ nla kan to n se abẹrẹ ajẹsara nilu Marburg naa.
Akọsilẹ ni lasiko ti awọn osisẹ naa n sisẹ lọwọ, ni wọn se alabapade ẹjẹ tabi isan lati ara awọn ọbọ to wa lati agbegbe ila oorun Afirika.
Awọn ọbọ naa si ni wọn ni wọn ti ni arun asekupani kan to fara pẹ arun Ebola.
Lẹyin o rẹyin, eeyan mejilelọgbọn lo ko arun naa laarin awn osisẹ yii, ti meje si dagbere faye laarin wọn.
Wọn ni ẹbi kan naa ni arun Marburg ati Ebola to ti ṣọṣẹ sẹyin l'Afirika jẹ, amọ arun Margurg tete maa n tan kalẹ bi ina inu ọyẹ.
Ajọ eleto ilera lagbaaye, WHO ni kokoro arun yii ko ṣe wo loju rara nitori bi o ti maa n ṣọṣẹ.
Arun Marburg ni a gbọ pe o maa n ran awọn eeyan lati ara ẹyẹ adan to n jẹ eso.

Awọn ami ta le ri lati da arun Marburg mọ:
Arun Marburg yii, to ti ran eeyan to le ni ogoje sọrun lorilẹede Angola lo ni awọn ami idamọ ta gbọdọ tete fiyesi.
Arun yii si ni iwadi sọ pe o wọpọ lara ẹyẹ adan ati oniruuru ọbọ bii aaya, inaki, lanbẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lara awọn ami idamọ arun Marburg ni ori fifọ, iba, otutu, ara riro, egbo ni ọna ọfun ati ki ara maa rẹ eeyan.
Awọn ami idamọ yoku ni igbẹ gbuuru, eebi ati inu rirun.
Bakan naa ni awọn eeyan miran to ba ni arun Marburg ni oju wọn maa n pọn bii ẹjẹ,ti wọn yoo si maa se esuke.
Koda, iwadi imọ ijinlẹ nipa arun naa ni o seese ki ẹni to ni arun Marburg maa pọ ẹjẹ sinu tabi sita.
Lọwọ bayii, ko tii si abẹrẹ ajẹsara to le dena arun naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bawo ni arun Marburg se de ilẹ Afirika:
Ọdun 1975 ni arun Marburg tun sẹyọ nilẹ Afirka, lorilẹede Kenya nigba ti ọkunrin kan dero ile iwosan pẹlu awọn arun naa to suyọ lara rẹ.
Se lo ni arun iba, ẹyin riro, ti ko si le mi daada, to si tun n pọ ẹjẹ eyi to mu ko ku laarin makati mẹfa ti arun naa mu.
Lẹyin ọjọ kẹsan ti alaisan naa ku, ni dokita to se itọju rẹ naa bẹrẹ aisan to fara pẹ arun Marburg yii bi o tilẹ jẹ pe ori ko yọ ni tiẹ.
Bi o se le kiyesara nipa arun Marburg:
Arun Marburg maa n ran lati eeyan kan si ẹlomiran nipa omi ara bii oogun, itọ tabi ikun.
Arun yii maa n fa ailera to lagbara, iba, koda o maa n jẹ ki ẹjẹ jade lara ẹlomiran.
Ayẹwo ẹjọ ti wọn ṣe fun ẹnikan to ku nile iwosan lorilẹede Guinea fihan pe arun Marburg lo ṣekupa ẹni naa.
Dokita ajọ WHO kan, Matshidiso Moeti ṣalaye pe arun Marburg lagbara lati tan kalẹ kaakiri debi to jina.
Iwadii n lọ lọwọ lati mọ awọn eeyan ti ẹni ti arun Marburg yii ni ibaṣepọ pẹlu ki o to dagbere faye.
Ijọba orilẹede Guinea ti ṣe itaniji awọn ilana ati dẹkun Ebola nibẹ lati le koju arun Marburg.
















