Europe Heatwave: London wà lára ìlú tó móoru jùlọ lágbàyéé lónìí, kódà ó gbóná ju Caribbean lọ

Iná tó ṣẹ́yọ látàrí ooru tó mújù

Àwọn orílẹ̀ èdè ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù ti ń gbóná tayọ ààlà bí afẹ́fẹ́ gbígbóná ṣe ń wọ́ lọ sí ẹkùn árìwá.

Wọ́n ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè France àti United Kingdom láti múrá digbí de ooru tí yóò mú.

Ẹkùn árìwá Spain ní òhun ti ń gbóná tayọ bí òdiwọ̀n ojú ọjọ́ rẹ̀ ṣe ti wọ 43C báyìí.

Iná ńlá ti bẹ́ sílẹ̀ ní àwọn apá ibì kan ní France, Portugal, Spain àti Greece ní èyí tó ti ń mú kí àwọn ènìyàn sá kúrò nílé wọn.

Orílẹ̀ èdè Britain ni ìrètí wà pé ooru tí yóò mú níbẹ̀ lónìí yóò lágbára ju ti àtẹ̀yìnwá lọ gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ṣe sọ àti pé France yóò gbóná gidi gan.

Ènìyàn méjì ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn lẹ́kùn Zamora ní ìwọ̀ oòrùn árìwá Spain sọ́wọ́ iná tí wọ́n si ti ṣe ìdádúró ọkọ̀ ojú irin ní wíwọ̀ nítorí ọ̀nà tí yóò gbà súnmọ́ iná púpọ̀.

Obìnrin kan àti ọkọ̀ rẹ̀ náà pàdánù ẹ̀mí nígbà tí wọ́n fẹ́ sa kúrò ní ilé wọn nítorí bí iná tó ń fa ooru púpọ̀ ní Portugal.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló ti sá kúrò ní ilé wọn ní orílẹ̀ èdè yìí.

Bákan náà ọ̀pọ̀ ẹranko ni wọ́n ti kó kúrò ní ibùgbé wọn.

Amin iyasọtọ kan

Ooru àmújù bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ UK, ó gbóna janjan ju Sahara lọ

Awọn obinrin to n fi abẹbẹ fẹ ara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn onimọ nipa bi oju ọjọ se ri nilẹ United Kingdom ti kede pe oju ọjọ yoo mooru pupọ nil naa, ti odiwọn boju ọjọ se ri yoo si jẹ 41C.

Ileesẹ to n tọpinpin bi oju ọjọ se ri ti wa fi ewe ọmọ mọ awọn olugbe ilẹ gẹẹsi leti pe ilẹ naa yoo gbona janjan lonii ọjọ Aje ati ni ọla ọjọ Isẹgun.

Bakan naa ni wọn kede pe oju ọjọ naa yoo mooru pupọ bẹrẹ lati ilu London titi de York ati Manchester.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Odiwọn 38.7C ni oju ọjọ to tii gbona julọ nilẹ UK eyi to waye lọdun 2019.

Ikede yii si ni wọn tun fi n sekilọ fun gbogbo awọn agbegbe to wa nilẹ Gẹẹsi, Wales ati Scotland pe oju ọjọ yoo mooru pupọ lagbegbe tiwọn naa.

Obinrin to n mu omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nibayii, o ti foju han pe ilu London ni yoo jẹ ọkan lara awọn agbegbe to mooru julọ lagbaye nitori bi odiwọn oju ọjọ rẹ se gbona ju agbegbe Sahara ati Caribbean lọ.

Bakan naa ni awọn onimọ nipa oju ọjọ tun ti sọ asọtẹlẹ pe ilu London ju ilu Dakhla lagbegbe iwọ oorun Sahara lọ eyi ti odiwọn oju ọjọ rẹ jẹ 24C.

Awọn agbegbe miran ti London yoo tun mooru julọ ni Nassau to wa lagbegbe Bahamas to jẹ 32C, Kingston nilẹ Jamaica to jẹ 33C, Malaga lorilede Spain to jẹ 28C ati Athens ni Greece tii se 35C.

Amin iyasọtọ kan

Ọwọ́jà iná tó lágbára bẹ̀rẹ̀ ní Portugal, Spain àti France, ènìyàn 300 pàdánù ẹ̀mí wọn

Iná tó bẹ́ sílẹ̀

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn panápaná ti ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti fòpin sí iná ńlá tó ṣẹ́yọ nítorí ooru tó ń bá wọn fínra ní orílẹ̀èdè Portugal, Spain àti apá kan France.

Ní ẹkùn àríwá Portugal, awakọ òfurufú kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ òfurufú tó fi ń fi omi pa iná náà já lulẹ̀ ní Foz Coa lẹ́bàá ẹnubodè Spain.

Kò dín ní ẹgbẹ̀rún méjìlá ènìyàn ló ti sa kúrò ní agbègbè Gironde ní France bí iná tó lágbára ṣe ń báwọn fínra níbẹ̀ náà.

Ní gúúsù Spain, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Costa del Sol àwọn ènìyàn tó ti sá kúrò níbẹ̀ ti tó 2,300 nítorí bí iná tó lágbára ṣe ń yawọ orí òkè Mijas.

Ashley Baker, ọmọ orílẹ̀èdè Britain tó ń gbé ní Mijas sọ fún BBC pé ọwọ́jà iná náà pọ̀ gan ní ọjọ́ Ẹtì tó sì ń yàbọ̀ sí ọ̀nà ọ̀dọ̀ òun ṣùgbọ́n tí ìjì líle bá òun le lọ.

Agbègbè Mijas ní ẹkún gúúsù Spain

Baker ní àwọn ọkọ̀ òfurufú ti ń sọ àwọn ohun èlò ìpaná sí agbègbè náà tí wọ́n sì ń bu omi ọ̀sà láti pa á.

"Kò dín ní ogójì ilé tó wà ní agbègbè wa tí gbogbo ènìyàn sì wà ní inú fu, àyà fu báyìí.

Karyn tó ń gbé ní Teste-de-Buch ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn gúúsù France sọ fún àwọn akọ̀ròyìn wí pé òun kò tíì rí irú iná bẹ́ẹ̀ rí.

Àwọn ènìyàn ń fi ilé wọn sílẹ̀

Manon Jacquart

Bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn ènìyàn ló ti fi ibùgbé wọn sílẹ̀ tí ohun tí wọ́n rí mú kúrò kò ju aṣọ tó wà ní ọrùn wọn lọ.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Manon Jacquart ní ọjọ̀rú ni òun kúrò ní ibùdó tí òun ti ń ṣiṣẹ́ tí òun sì ti dèrò Teste-de-Buch ní France.

Jacquart ní òun ń gbìyànjú láti mú ọkàn òun le ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń ba òun nítorí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ náà.

Láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni gbogbo ìlú ti ń gbóná janjan ní Portugal àti Spain.

Àwọn tó ti ku ní orílẹ̀ èdè méjéèjì ti lé ní 300.

Bákan náà ni ìjọba Italy ti kéde pé nǹkan kò rọgbọ ní agbègbè Po Valley.

Ní ẹkún àríwá Morocco, àwọn ènìyàn ti ń fi ìlú sílẹ̀ nítorí bí iná ṣe ti gba Larache, Ouezzane, Taza àti Tetouan.

Ìlú kan parun tán ní agbègbè Ksar El Kebir sọ́wọ́ tí ènìyàn kan sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.