Àwọn aṣaájú Mùsùlùmí báwọn Krìsítẹ́nì jọ́sìn ní ṣọ́ọ́sì

Awọn musulumi to jọsin ni sọọsi

Oríṣun àwòrán, Today News

Kayeefi ati iyalẹnu nla lo waye ni ọjọ Aiku ana nipinlẹ Kaduna nigba ti awọn musulumi darapọ mọ awọn Kristiẹni lati bawọn jọsin nile isin wọn.

Ni ile ijọsin ECWA to wa lopopona Lemu nilu Kaduna, ti isin alajumose naa ti waye, ni awọn musulumi atawọn asaaju awujọ nipinlẹ naa peju si.

Igbesẹ yii si ni wn se lati mu ki okun ajọsepọ ẹsin laarin awọn ẹlẹsin mejeeji yi daindain si saaju ibo gbogbo gbooo ti yoo waye lọdun 2023.

Ki lo de ti musulumi lọ ba Kristiẹni jọsin ni sọọsi?

Nigba to n salaye eredi isẹlẹ naa, alaga fun igbimọ alajọsepọ lagbegbe naa, Sẹnetọ Haruna Azeez Zego ni wọn fi iwe pe awọn musulumi lagbegbe naa wa bawọn jọsin ni.

Igbesẹ yii si lo salaye pe o waye nitori bawọn se n fẹ ki ibagbepọ alaafia fẹsẹ mulẹ laarin awọn ẹlẹsin mejeeji ni.

Zego wa se sadankata si awọn musulumi ti wọn pe, to si jẹ ipe wọn ọhun.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Today ti gbe iroyin naa sita, Zego ni “Ijọ wa lo fi iwe pe wọn lati wa ba wa jọsin, eyi si lo jẹ ki wọn wa.

Ọpọ awọn musulumi to si ba wa jọsin naa ni wọn jẹ ọmọ Naijiria to n gbe layika ibi ti ile isin wa kalẹ si.

Igbesẹ naa si la ro pe yoo mu ki ibagbepọ alaafia tubọ gbopọn si laarin awa ẹlẹsin mejeeji lai fi ti ẹsin ta n sin se.”

Lara awọn asaaju ẹsin Islam to bawọn jọsin ninu ijọ ECWA naa, lo sọrọ lori idi ti ibagbepọ alaafia se gbọdọ wa.

Bakan naa ni wọn gba pe ko si idi kankan fun awọn ẹlẹsin mejeeji lati maa doju ogun kọ ara wọn nitori ẹsin ti koowa wọn n sin.

A pàdánù ọmọ Naijiria mẹ́ta sí Hajj ọdún yìí – NAHCON
Aworan Hajj

Oríṣun àwòrán, Google

Ọmọ Naijiria mẹta ti ku ni irinajo lọ si ile mimọ Hajj, ti ọdun 2022.

Alakoso ikọ eto ilera ti ileeṣẹ National Hajj Commission, Dokita Usman Galadima lo kede bẹẹ lasiko to n jiyin fun awọn eniyan ohun to ṣẹlẹ ni irinajo si ilẹ mimọ paapaa lasiko Arafat.

Galadima ni obinrin meji to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji ati ẹni ọdun mejilelọgọta, ti wọn wa lati ipinlẹ Kaduna ati Nasarawa ni wọn ba asiko naa lọ.

O fikun un pe arakunrin, ẹni ọdun mejidinlọgọta lo ku ni Hajj ọdun yii, ti o si wa lati ipinlẹ Borno.

Galadima ni arinrinajo lati ipinlẹ Borno naa ku si Muna, nigba ti arinrinajo lati Kaduna ku si Arafah, ti eleyii to wa lati ipinlẹ Nasarawa si ku si ilu Makkah.

Bakan naa lo ni gbogbo awọn to papoda yii ni wọn ti sin ni ilana ẹsin Mususlumi ni orilẹede Saudi Arabia.

Ajọ NAHCON naa ni wọn ti fi to awọn mọlẹbi awọn oloogbe naa leti nipa iṣẹlẹ ọhun.

Bakan naa ni Ajọ ọhun fikun un pe Ọjọ Karundinlogun, Osu Keje ni awọn arinrinajo naa yo maa pada wa si ile.