Ṣé Nigeria yóò fìyà jẹ Morocco bí ti àtẹ̀yìnwá láti dé àṣekágba WAFCON 2022?

Awọn agbabọọlu Super Falcons ati Morocco

Ẹgbẹ agbaboolu obinrin Naijiria, Super Falcons yoo wako pẹlu ikọ Atlas Lionesses ti orlẹede Morocco.

Loni, ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ni ifigagbaga naa yoo waye fun ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to kangun si asekagba idije WAFCON 2022.

Papa ìṣeré Prince Moulay Abdellah ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo tì waye laago mẹsan-an alẹ n'ilu Rabat.

Iko Super Falcons lo gbọdọ bori ifẹsẹwọnsẹ yii lati wọ ipele aṣekagba idije naa.

Lionesses of Atlas ile Morocco ni o bori ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ti wọn ti kopa ninu idije naa, ti iko Super Falcons si padanu ẹyọ kan ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn ti wọn gba pẹlu iko Bayana Bayana ti ile South Africa.

Ki lo ṣe e ṣe ko waye nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa?

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yii ni yoo gbe ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons de ipele aṣekagba idije naa, ti wọn ba fi borí Morocco.

 Bakan naa ni yoo jẹ fun Morocco, to ba jẹ pe awọn lo bori.

 Ki wọn o to koju ẹlòmíì ni aṣekagba idije.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

 Orile-ede Naijiria n ja lati gba ife idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa, WAFCON, fun igba kẹwaa, ninu ìgbà mejila to ti waye.

 Morocco n jà lati gba a fun igba akọkọ.

 Botilẹ jẹ pe Super Falcons ni ọpọ n fi ojú si lara gẹgẹ bi akọni, ẹgbẹ́ agbabọọlu Atlas Lionesses naa kò ṣe e fi ọwọ rọ́ sẹyin.

 Idi ni pe lati igba ti idije WAFCON 2022 ti bẹ̀rẹ̀, ni wọn ti n fakọyọ.

 Wọn ò si tíì padanu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kankan.

Yatọ si eyi, Morocco lo gbalejo idije naa, wọn o si ni fẹ ki ife ẹyẹ bọ wọn lọwọ.

 Nitori naa ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons nilo lati fi ọkàn si nkan ti wọn n ṣe lori papa lati ìbẹ̀rẹ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa.

 Iye igba ti Morocco ati Super Falcons ti pade lori papa

 Ọdun 1998 ni ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji kọkọ pade ni WAFCON 1998.

 Iya kekere kọ ni Super Falcons fi jẹ Atlas Lionesses ni ilẹ baba wọn.

 Ami ayo mẹjọ si odo ni wọn fun wọn.

 Ọdun 2000 ni wọn tun pade ni WAFCON 2022 to waye ni South Africa.

 Ami ayo mẹfa si odo ni Naijiria tun fi lù wọ́n ni aludojubolẹ.

 Sugbọn laarin ìgbà naa si asiko yii, ẹgbẹ́ agbabọọlu Morocco fihan pe nkan ti yatọ, paapaa lati igba ti WAFCON 2022 ti bẹ̀rẹ̀.

Ki ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu Morocco tumọ si fun Naijiria?

Nigba ti o gba ni yanju, Aarẹ, ajọ to risi kokari ere bọọlu nile wa, NFF, Amaju Pinnick ni gbogbo nkan ni iko Super Falcons ni lati ṣe lati gba ifẹyẹ ijide naa gba kẹwa.

Amaju ni oun kọkọ ki awọn agba bọọlu naa fun bi wọn ṣe fakọyọ ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti ko pa ninu, ti wọn si bori awon akẹẹgbẹ wọn.

“Mo kọkọ ki awọn agbabọọlu naa fun bi wọn fakọyọ ninu ifẹsẹọnsẹ pẹlu awọn akẹẹgbẹ wọn.”

“Wọn ti fi ran wa pe orilẹede Naijiria ni oga ti a ba sọrọ ere bọọlu obinrin ni ile adulawọ, bi wọn ṣe fakọyọ ninu awọn ifesewọn wọn,”

“Ifẹsẹweọnsẹ pẹlu ikọ Morocco ko le yipada sugbọn yoo lagbara pupọ gan nitori ikọ Morocco naa jẹ ẹgbẹ agbabọọlu ti muṣemuṣe wọn da muṣe.”

“Mo ni igbagbọ pe a bori wọn, mo ti sọ fun awọn agbabọọlu naa lati ranti ibi ti wọn wa, ki wọn si fi ọkan gbe orilẹede Naijiria larug\]e nibi ijide WAFCON.” 

“Ninu mi dun si awọn agbabọọlu pupọ.”

Aworan Ashleigh Plumptre

Oríṣun àwòrán, others

Bi igbaradi Super Falcons ṣe rí?

Aarẹ, ajọ to risi kokari ere bọọlu nile wa, NFF, Amaju Pinnick ni oun ni igbagbọ ninu iko Super Falcons lati bori orilẹede Morocco to ba di ago mẹsan oni ni papa iṣerẹ Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat lorilẹede Morocco.

 Amaju ni awọn agbabọọlu Naijiria ti sẹtan lati jẹ orilẹede Naijiria bọ si oke nibi ti o ko wa.

O ni o ti ṣeṣe fun Ikọ agbabọọlu Super Facons lati kopa ninu ifẹsẹwọmsẹ aṣe kagba to ba di ọjọ aiku ọse to bo yi

aworan agbabọọlu ọmọ orilẹede Morocco

Oríṣun àwòrán, others

Nigeria vs Burundi match: Ṣé àlá Quarter Finals yóò ṣẹ fún Super Falcons?

Bi ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons ti Naijiria ṣe n gbaradi lati koju Swallow ti Burundi lonii, ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo ipa ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni.

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni eyi to kẹhin ni abala akọkọ fun awọn orile-ede to the wa ni ipin C ninu idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco.

Ẹgbẹ agbabọọlu to ṣe ipo kinni, ikeji, ati ikẹta ni ipin C, yoo bọ si ipele quarter finals. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu Burundi si ni yoo sọ ibi ti ori n gbe Super Falcons lọ, ti Burundi ba fi lu wọn.

South Africa ati Botswana lo na Burundi. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ti ọjọ́ Aiku, ti yoo waye ni papa ìṣeré Prince Moulay El Hassan, Rabat, ni igba àkọ́kọ́ ti orile-ede mejeeji koju ara wọn nilẹ okeere.

Orile-ede Burundi ti padanu ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn meji akọkọ, Naijiria padanu ẹyọkan sọwọ South Africa.

Kin ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu Burundi tumọ si fun Naijiria?

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ laarin orile-ede mejeeji la le fi we ija laarin Dafidi ati Golayaati. Igba àkọ́kọ́ re e ti Burundi n kopa ni idije WAFCON, àmọ́ Naijiria ti kopa ninu mọkanla, o si ti gba ife ni igba mẹsan-an.

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹta ni orile-ede kọọkan to n kopa ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco, WAFCON 2022, gbá ni abala akọkọ.

Ninu meji to ti kọkọ gbá, Naijiria padanu ẹyọkan sọwọ South Africa, o bori ikeji nigba to na Botswana ni ami ayo méjìlá si odo. Lọwọlọwọ, Naijiria lo wa ni ipo keji ni ipin kẹta (C), pẹlu ami mẹta.

Orile-ede Burundi lo wa ni ipo to kẹhin, ko ni ami kankan lẹyin ti South Africa ati Botswana lu u. Botilẹ jẹ pe ami mẹta ni Naijiria àti Botswana ni lori tabili igbelewọn, wọn fi Naijiria si ipo kejì, nitori 'iru' goolu ti wọn gbá wọ awọn.

Sugbọn o, dandan ni fun wọn lati bori Burundi, ki wọn o le bọ si ipele quarter final.

Báwo ni igbaradi Super Falcons ṣe rí?

Olukọni ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin Naijiria, Randy Waldrum, sọ fun awọn akọroyin n'ilu Rabat, lọjọ Abamẹta pe, àwọn ko le foju kere Burundi.

O ni "ao le foju di ẹgbẹ́ agbabọọlu Burundi."

A n gbaradi lati tun ṣe daadaa ju bi a ṣe ṣe lọ ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wa to kọja. Erongba wa si ni lati wọ ipele quarter finals lọjọ Aiku."