'Mo lérò pé yóò yé àwọn agbésùnmọ̀mí pé ìṣòrò tó ń kojú Nàìjíríà ni dídi aṣíṣẹ́kárakára tó ń pèsè ohun rere'

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sọ ọrọ gba awọn agbesunmọmi to n ṣiṣẹ ibi kaakiri orilẹede pe oun lero pe wọn yoo ni oye pe ibi ti bata iṣoro ti n gbe ta orilẹede yii lẹ sẹ ni didi aṣiṣkara to n pese nkan rere.

Aarẹ n sọ eyi lọ́jọ́ Abamẹta ni ilu rẹ, Daura nibi to ti gbalejo awọn agunbanirọ to wa kii ku ọdun.

Nibẹ ni Buhari ti sọ pe bi orilẹede Najiia ba ṣe ni afojusun nla si bi ipa ibaṣepọ yoo ṣe ri paapaa laarin awọn ọdọ.

O wa gba awọn agunbanirọ to wa kii sọhun niyanju pe wọn woye tayọ ọrọ aṣa, ẹya ati ẹsin ninu biba ara ẹni ṣe to si rọ sii pe yan rinrin irinajo, didarapọ, ifarada ati idunadura laayo lati mọ riri awọn nkan daadaa to wa ni Naijiria.

Aarẹ Buhari ati awọn agunbanirọ

Oríṣun àwòrán, Presidency

“Mo lero pe awọn ọmọ Naijiria to ku to n da wahala silẹ, awọn agbeesunmọmi ati irufẹ wọn yoo ni oye pe iṣoro Naijiria ni pe ki awọ́n eeyan maa so eso ohun rere ni awọn ẹka bii ipese ounjẹ taa n jẹ”.

Aarẹ ṣapejuwe igba ti wọn ti awọn ẹnu ibode Naijiria mọ kiko ounjẹ ilẹ okere wọle bo ṣe mu ki ipese ounjẹ labẹle buyari sii to si ni oun ko kabamọ rẹ oun yoo si tun ṣe amuṣẹ rẹ.

“Iṣoro kan ṣoṣo ti mo ni ni pe awọn kan ṣi n janfani lara pipa awọn eeyan ati lilọ ni lọwọ gba”.

Amọ o rọ awọn agunbanirọ naa lati bojuwo nini imọ to fẹ sii ki wọn ma ssi jẹ ki aṣa, ẹya tabi ẹsin di wọn lọna.

O ni “lasiko ti a wa yii, ti ẹ ni lati fọwọ sowọpọ pẹlu imọ ẹrọ tori iṣẹ ijọba ko si nita mọ”.