A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ẹ̀sùn ìṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ Ọwọ Poly- Akeredolu

Ijọba ipinlẹ Ondo lo ti ṣe ileri lati wadii ẹsun iṣekupa akẹkọọ kan ni ile ẹkọ Gbogboniṣe Rufus Giwa to wa ni ilu Ọwo, Folarera Ademola, latọwọ awọn oṣiṣẹ ikọ amọtẹkun. Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Ayedatiwa, lo sọ ọrọ yi lakoko to n ba awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa to ṣe iwọde ifẹhonu han wa si ọfiisi gomina sọrọ nilu Akurẹ. Ayedatiwa to wi pe ohun ibanujẹ ni iroyin iku ọdọmọkunrin ọhun jẹ fun ijọba ipinlẹ Ondo.

O rọ awọn akẹkọọ naa ki wọn fun ijọba laaye lati ṣe ohun to tọ lori iṣẹlẹ ọun. Ninu ọrọ rẹ, o ni “mo ba mọlẹbi oloogbe naa ati ile ẹkọ Rufus Giwa kẹdun lorukọ gomina ati ijọba ipinlẹ yi.

Mo si n fi daa yin loju pe ijọba yoo gbe igbesẹ to tọna ni kiakia”.

Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, @Akeredolu

Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ tẹlẹ?

Ṣaaju ni aarẹ awọn akẹkọọ nile ẹkọ naa, Olorunda Oluwafemi, to ko awọn akẹgbẹ rẹ sodi lati wa gbe oku odọmọkunrin naa si ẹnu ọna ọfiisi gomina ti beere fun ohun mẹta lati ọdọ ijọba.

Eyi ti igbakeji gomina si fesi pe ijọba yoo boju to gbogbo ibeere ọhun. Awọn ohun ti Oluwafemi beere fun ni pe ki ijọba ṣe eto isinku oloogbe naa lọna ti yoo tẹwọn lọrun.

Ki ijọba san owo ìrọ̀jú fun mọlẹbi oloogbe naa, ki ijọba si rii pe aṣekupani ọmọ ikọ amọtekun naa fi oju wina ofin. Ifẹhonu han ọhun to bẹrẹ lati ilu Ọwọ ni ojo to rọ fun bii wakati meji ko di awọn akẹkọọ naa lọwọ ni bi wọn ṣe kọrin aro pẹlu ara oloogbe ọun lati ile ẹkọ wọn de iwaju ọfiisi gomina nilu Akurẹ. Folarera Ademola ni wọn wi pe ọmọ ikọ Amọtekun kan ta nibọn ni ile rẹ nilu Isuada nijọba ibilẹ Ọwọ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa ọdun yi.

Aworan Amotekun

Oríṣun àwòrán, Google

A kò ṣèsì pa akẹ́kọ̀ọ́ Owo Poly, bí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe wáyé rèé- Amotekun

Ikọ Amotẹkun nipinlẹ Ondo ti salaye bi akẹkọọ ileẹkọ Gbogboniṣe Rufus Giwa Polytechnic, Folarera Ademola ṣe doloogbe ati ipa ti wọn kọ ninu iṣẹlẹ naa.

Eyi ko ṣẹyin bi ifẹhọnu ṣe bẹ silẹ ni ileẹkọ Owo Poly lati tako isekupani akẹkọọ wọn.

Amọ ninu atẹjade ti ikọ Amọtẹkun fi sita ni wọn ti salaye ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa.

Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Adetunji Adeleye ni ikọ naa fi aidunnu wọn han si iku akẹkọọ naa.

Adeleye ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa lati mọ iru iku to pa akẹkọọ naa.

Amọtẹkun sọ ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ iku akẹkọọ Poly Owo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‘’ O ṣe pataki fun ikọ amọtẹkun lati salaye ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa nitori aabo ara ilu jẹwọn logun.

‘’Lọna ati gbogun ti iwa ọdaran nipinlẹ Ondo ni ikọ amọtẹkun fi n ṣe iwadii awọn ti wọn fẹsun kan wipe wọn ma n ṣekọlu si awọn ọlọkada ti wọn a si gba owo ati ọkada wọn lọwọ wọn.

Lọna ati mu awọn ọdaran naa ni wọn ri pe o sa wọ wọ inu ile kan ni Ọwọ, ti wọn si ba awọn gende marundinlogun nibẹ pẹlu ọpọlọpọ eefin ninu yara, ti wọn si ba ọkada mẹrin ninu yara ọhun.

Lẹyin ti wọn salaye iru eniyan ti wọn jẹ ni awọn gende naa yabo wọn ti ibọn ọkan ninu wọn si ṣesi yin, ti ọkan ninu wọn ati ọkan ninu ikọ amọtẹkun naa si farapa.’’

Lẹyin naa ni wọn ko wọn lọ si agọ wọn amọ ti wọn fi afurasi naa silẹ nitori egbo rẹ, to si kuro ni ọdọ wọn ni ọjọ kẹjidinlọgbọn, osu kẹfa, ọdun 2022’’

Amọ ikọ Amọtẹkun ni o ṣeni laanu pe lẹyin ọjọ mọkanla ti arakunrin naa kuro ni ikawọ wọn lo jade laye.

Ti wọn si ba ẹbi ati ara oloogbe naa dẹkun, pẹlu adehun pe iwadii yoo bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ìfẹ̀hónúhàn bẹ̀rẹ̀ ní Owo lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ Rufus Giwa Poly tí Amotekun ṣèèṣì pa

Awọn akẹkọọ ile ẹkọ Gbogbonise Rufus Giwa ni ilu Owo ti fariga lori iku ọkan ninu wọn.

AAwọn akẹkọọ ile ẹkọ gbogboniṣe Rufus Giwa naa nipinlẹ Ondo ni wọn ti bẹ̀rẹ́ un ifẹhonu han lori ẹsun pe ọkan lara awọn ọmọ ikọ mọtẹkun yin ibọn pa akẹkọọ kan.

Rufus Giwa Polytechnic

Bawo ni ọ̀rọ̀ ṣe ṣẹlẹ̀?

Aarẹ awọn akẹkọo nile ẹkọ naa, Olorunda Oluwafemi, ṣalaye fun ileeṣẹ BBC New Yoruba ni kikun.

O ni pe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa ọdun yi ni awọn ọmọ ikọ Amọtẹkun ṣe ìkọlu si ile awọn akẹkọọ nilu Isuada nijọba ibilẹ Ọwọ nibi ti wọn ti yin akẹkọọ kan nibọn ti wọn si ko awọn mẹta miran si ipamọ.

Oluwafemi wi pe ana ọjọ Eti ni ọdọmọkunrin naa dagbere faye latari airi itọju to peye.

Nitori bi awọn Amọtẹkun ọhun ṣe gbe e pamọ sinu ile kan ko too di pe iya ọmọ naa ke gbajare. Iwọde ifẹhonu han naa ni o bẹrẹ niwaju ile ẹkọ Gbogbonise Rufus Giwa titi de aafin Ọlọwọ ati ọfiisi gomina ipinlẹ Ondo.