A ó̀ parí pápákọ̀ òfúrufú ìpínlẹ̀ Ekiti kí n tó parí sáà mi - Fayemi
Ekiti airport: Kayode Fayemi ní ijọba òun yóò parí pápákọ̀ òfúrufú ìpínlẹ̀ Ekiti lọ́dún tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, @kfayemi
Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti sọ pe ijọba oun yoo gbiyanju lati pari papakọ ofurufu ti wọn n kọ si ipinlẹ naa ki saa oun to pari lọdun to n bọ.
Fayemi lo fi ọrọ naa lede lasiko to lọ bẹ awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba rẹ n ṣe kaakiri ipinlẹ naa wo.
Ileeṣẹ iroyin abẹle News Agency of Nigeria, NAN, ni iye owo ti ijọba Ekiti n na lori awọn akanṣe iṣẹ naa ko din ni ogun biliọnu naira.
Gomina ọhun sọ pe inu oun dun bi awọn akanṣe iṣẹ naa ṣe n lọ ati pe o da oun loju ijọba oun yoo pari awọn akanṣe iṣẹ naa ki saa oun to pari ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.
Ipinlẹ Ekiti yoo di ibi amuyangan nipa eto ọrọ aje
Fayemi ni awọn iṣẹ ti ijọba oun bẹrẹ yoo sọ ipinlẹ Ekiti di ibi amuyangan ati ipinlẹ ti ọrọ aje rẹ yoo burẹkẹ.
O ni akanṣẹ etod “Knoledge Zone” ko ṣẹyin erongba oun lati sọ ipinlẹ naa I ibugbe awọn ọlọpọlọ pipe ati ibi ti awọn ọmọwe ati amojuẹrọ yoo ti maa ṣiṣẹ.
O ni “Ayẹwo yii jẹ ọkan lara awọn ayẹwo ti a n ṣe si akanṣe eto Knowledge Zone ati papakọ ofurufu ti a n kọ, mo wa nibi pẹlu awọn adari ileeṣẹ aladani ti a jọ n ṣiṣẹ papọ, ọga agba ileeṣẹ Axxess International, Cavista, ọgbẹni John Olajide.”

Oríṣun àwòrán, @kfayemi
Nigba ti Fayemi n sọrọ loju opo Twitter rẹ lẹyin abẹwo ọhun, o ni “Papakọ ofurufu ipinlẹ Ekiti yii jẹ ọkan gboogi lara awọn ọna ti a fẹ fi sọ ipinlẹ Ekiti di ibi ti wọn yoo ti maa ko ohun ọgbin wọle-jade, eto ilera to ye kooro ati ibi ti imọ ẹrọ yoo gbinlẹ si.”
“A ti pari oju ọna oni kilomita mẹta o le diẹ ti ọkọ ofurufu yoo maa gba, iṣẹ si ti n lọ lọwọ lori awọn ọọfisi papakọ ofurufu naa.”
Fayemi fi kun pe papakọ ofurufu ọhun yoo pese aye fun ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu Naijiria lati ṣiṣẹ ati aye mii fun awọn onimọ ẹrọ.












