Ilé ẹjọ́ ti gbà pé arákùnrin tí aṣòfin àgbà Nàìjíríà kan gbé lọ UK láti lo ẹ̀yà ara rẹ̀ kìí ṣe ọmọdé

Oríṣun àwòrán, other
Aṣofin kan lorilẹede Naijiria ati iyawo rẹ fara han niwaju ile ẹjọ loni lori ẹsun gbigbimọ pọ lati gbe eeyan kan wa si orilẹede UK lati yọ ẹya ara rẹ fun lilo.
Adajọ to gbọ ẹjọ naa nile ẹjọ Majisireeti Westminster Magistrates Court nilu London ti tẹwọ gba awijare pe olupẹjọ ninu ẹjọ naa kii ṣe ọmọde rara.
Gbagbagba ni ile ẹjọ naa kun pẹlu awọn ololufẹ aṣofin naa, aṣoju ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede Naijiria ni UK pẹlu awọn mọlẹbi aṣofin agba naa ati iyawo rẹ.
Ni ọjọ karun un oṣu karun un ọdun 2022 ni ọrọ naa de ọdọ ọlọpaa nigba ti olupẹjọ de agọ ọlọpaa.
Laarin ogun iṣẹju ti igbẹjọ naa fi waye, Onidajọ Tan Ikram to gbọ ẹjọ naa ti taare rẹ si ẹkun Old Bailey fun itẹsiwaju igbẹjọ naa lọjọ kẹrin oṣu kẹjọ.
Amọṣa, aṣofin agba naa ati iyawo rẹ yoo ṣi wa ni ahamọ awọn agbofinro titi di igba ti igbẹjọ naa yoo fi tẹsiwaju.
Adajọ Ikram tun gbẹsẹ kuro lori ofin [ẹ maa kọ iroyin nipa rẹ’ ti ile ẹjọ fi de olupẹjọ naa nitori bi wọn ṣe n fi oju majeṣin wo o tẹlẹ bi o tilẹ jẹ pe nitori irufẹ ẹjọ ti ipẹjọ naa da le lori, wọn ko gbọdọ darukọ rẹ.








