Ṣé lóòótọ́ ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP Eko yan Funke Akindele gẹ́gẹ́ bí igbákejì olùdíje gómìnà?

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ní àná ni ìròyìn àti àwọn gba orí ayélujára pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Eko.
Ìbéèrè tó gba ẹnu àwọn ènìyàn ni pé ṣe lóòótọ́ ni ìròyìn yìí.
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Eko tí kéde wí pé olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú náà, Olajide Adediran kò ì tíì yan gbajúgbajà òṣèré tíátà, Funke Akindele gẹ́gẹ́ bí igbákejì.

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ìpínlẹ̀ Eko, Hakeem Amode ní ẹgbẹ́ àwọn kò ì tíì ní igbákejì gómìnà báyìí.
Amode sọ èyí láti ṣe àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ lórí ìròyì tó gbòde wí pé olùdíje sípò gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ náà, Olajide Adediran ti yan Funke Akindele gẹ́gẹ́ bí igbákejì.
Ó ní láìpẹ́ yìí ni Olajide yóò fi ẹni tí yóò jẹ́ igbákejì rẹ̀ léde àti wí pé kí àwọn ènìyàn fi ara balẹ̀ nítorí kìí ṣe ẹgbẹ́ ni yóò kéde ẹni tó bá fẹ́ yàn bí igbákejì bíkòṣe olùdíje fúnra rẹ̀.
Ó fi kun pé gbogbo ìròyìn tó gba ayélujára kan kò wá látọwọ́ olùdíje àti ẹgbẹ́, fún ìdí èyí kí àwọn ènìyàn kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìròyìn náà.
Nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn bèèrè lọ́wọ́ Amode bóyá ẹgbẹ́ náà ti ní ẹnìkan nílẹ̀ tí wọ́n fẹ́ yàn gẹ́gẹ́ bí olùdíje, Agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà kọ̀ láti sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ náà.
Agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà ní òun kò le fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá olùdíje sípò gómínà ń gbèrò láti yan Funke Akindele gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀.
Bákan náà ló tún tẹmpẹlẹmọ wí pé olùdíje ló ní àànfàní láti yan ẹni tí ó máa ba ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbákejì kìí ṣe ẹgbẹ́.
Kí ni olùdíje sọ nípa yìyan Funke Akindele gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Google
Nígbà tí òun náà ń sọ̀rọ̀, agbẹnusọ Adediran, Gbenga Ogunleye sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn tó gba orí ayélujára pé ọ̀gá òun ti yan Funke Akindele gẹ́gẹ́ bí igbákejì.
Ogunleye ní lóòótọ́ ni Adediran ń ro Akindele àti àwọn mẹ́rin mìíràn ṣùgbọ́n wọn ò tíì kéde ẹnìkan ní pàtó gẹ́gẹ́ bí igbákejì.
Ó ní bóyá nítorí àwọn nǹkankan tó ń lọ nínú ẹgbẹ́ náà ló ń mú kí àwọn kan máa gbé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ náà kiri.
Bákan náà ló dárúkọ Gbadebo Rhodes-Vivour, Kolawole Vaughan, Adenike Shobajo àti Rasheed Teslim-Balogun gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí olùdíje náà ń gbèrò láti lò gẹ́gẹ́ bí igbákejì yàtọ̀ sí Funke Akindele.
Ogunleye náà sọ àrídájú rẹ̀ pé láìpẹ́ yìí ni Adediran máa fi igbákejì rẹ̀ léde.















