Ẹnikẹ́ni tó bá hu ìwà ajẹbánu yóò fojú winá òfin – Buhari sí àwọn mínísítà tuntun

Oríṣun àwòrán, Google
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kesi awọn minisita tuntun to ṣẹṣẹ yan lati ri pe igba iwa ibajẹ ati ajẹbanu ko si le wọn lori.
Buhari ni ẹnikẹni ninu wọn ti wọn ba ri iru iwa bẹẹ ni yoo foju wina ofin, to si parọwa si won lati jawo ninu iwa ibajẹ.
O ni awọn ti wọn ba yan lati ṣiṣẹ fun ara ilu gbọdọ jẹ ẹni ti ihuwasi rẹ se e mu yangan lawujọ.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Aarẹ Buhari, Femi Adesina fi lede naa lo ti ni aarẹ fi ikilọ naa lede lasiko to n bura wọle fun awọn minisita tuntun naa.
Bakan naa lo kesi wọn lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn minisita ti wọn ba ni ipo, ki ibaṣiṣẹpọ wọn le yọri si igbega orilẹede Naijiria.
Awọn minisita naa re e ati ipo wọn ni;
Ikechukwu Ikoh ni minisita abẹlẹ fun ọrọ imọ ẹrọ ati sayẹnsi (Minister of State, Science and Technology)
Umana Umana ni minisita fun ọrọ agbegbe niger delta (Minister of Niger Delta Affairs)
Udi Odum ni minisita abẹlẹ fun ọrọ agbegbe (Minister of State, Environment)
Ademola Adegoroye ni minisita abẹlẹ fun ọrọ irinna (Minister of State, Transportation)
Umar El-Yakub ni minisita abẹlẹ fun ọrọ iṣẹ ati ibugbe (Minister of State, Works and Housing)
Goodluck Opiah ni minisita abẹlẹ fun ọrọ eto ẹkọ (Minister of State, Education)
Nkama Ekumankama ni minisita abẹlẹ fun ọrọ eto ilera (Minister of State, Health.)












