Àlàyé bí ẹyẹ Super Falcons gbé kìnnìún Cameroon mì ní quarter final ìdíje WAFCON 2022
Akojọpọ iroyin ree nipa bi ifẹsẹwọnsẹ se n lọ nibi idije bọọlu awọn obinrin nilẹ Adulawọ.
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Adedayo Owolabi, Olubusola Afolayan, Olubayode Alebiosu and Busayo James-Olufade
Àlàyé bí ẹyẹ Super Falcons gbé kìnnìún Cameroon mì ní quarter final ìdíje WAFCON 2022
Oríṣun àwòrán, CAF
Ẹgbẹ agbabọọlu obìnrin orile-ede Naijiria, Super Falcons, ti
bọ si ipele to kangun si aṣekagba, semi finals idije bọọlu àwọn obìnrin ni
Africa to n lọ lọwọ ni Morocco.
Eyi waye lẹyin ti wọn lu ẹgbẹ́ agbabọọlu Indomitable
Lionesses ti orile-ede Cameroon ni ami ayo kan si odo.
Ọjọbọ ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa waye ni papa ìṣeré Mohammed V
n'ilu Casablanca.
Ọmi odo ni ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji ta ní abala àkọ́kọ́ ifẹsẹ̀wọnsẹ̀
naa.
Sugbọn nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ isẹju mẹrindinlọgọfa,
Rasheedat Ajibade, pẹlu iranlọwọ Onumonu Chukwufunmnaya gba bọọlu si àwọ̀n
Cameroon.
Titi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa fi pari, ko si ẹgbẹ́ agbabọọlu to gba
bọọlu si àwọ̀n.
Orile-ede Cameroon ti já kuro ni WAFCON 2022, bákan náà ni wọn
o ni le kopa ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni agbaye lọdun to n bọ.
Naijiria yoo koju orile-ede Morocco ni ipele
semi final ni ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun.
Senegal àti Botswana já kúrò ní WAFCON 2022 ní 'quarter tó gba cup
Oríṣun àwòrán, cafwomenonline
Ẹgbẹ agbabọọlu orile-ede Senegal ati Botswana ti ko ẹrù wọn
kuro ninu idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco.
Eyi waye lẹyin ti orile-ede Zambia na Senegal ni ami ayo mẹta
si meji.
Ọmi ayo kọọkan ni wọn ta ni abala akọkọ àti ikeji ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀
naa. Eyi to mu ki wọn o gba pẹnariti.
Bakan naa lo ri ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Morocco ati Botswana. Ami
ayo 2-1 ni Morocco na Botswana.
Ni bayii, Zambia ti bọ si ipele to kangun si àṣekágbá
idije WAFCON 2022.
Yàtọ̀ si eyi, wọn tun ti koju osunwọn lati kopa ni idije ife
agbaye (World Cup) ti àwọn obìnrin ti yoo waye ni orile-ede Australia ati New
Zealand, lọdun 2023.
Igba ọtun gba a ni eyi jẹ fun Zambia, nitori pe igba àkọ́kọ́
niyii ti wọn n lọ fun idije ife ẹyẹ agbaye.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ abala quarter final n tẹsiwaju lonii, pẹlu
orile-ede Naijiria ati Cameroon laago mẹfa irọlẹ, South Africa ati Tunisia
laago mẹsan-an alẹ.
Àwọn meji to ba tun fidirẹmi ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mejeeji, yoo
já kuro ninu idije naa lọdun yii. Wọn ko sì ni le kopa ni World Cup lọdun 2023.
Ẹni to ba bori ninu Naijiria ati Cameroon yoo
koju Morocco ni semi final.
Quarter Finals bẹ̀rẹ ní WAFCON 2022, wo àtúpalẹ̀ agbára orílè-èdè kọ̀ọ̀kan, WAFCON 2022 quarter finals : Wo bí ìdíje quarter finals yóò ṣe lọ
Oríṣun àwòrán, cafwomenonline
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ fun ipele quarter finals ni idije bọọlu
àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco, WAFCON 2022, yoo bẹrẹ ni Ọjọru,
ọjọ kẹtàlá, oṣu Keje, yoo si pari ni Ọjọbọ.
Eyi n waye lẹyin ti orile-ede mẹrin (Burundi, Togo,
Uganda ati Burkina Faso), ti ja kuro ninu idije naa ni opin ọ̀sẹ̀ to kọja.
Àwọn orile-ede to kù ni Naijiria, South Africa,
Botswana, Zambia, Tunisia, Senegal, Morocco ati Cameroon.
Bayii ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ quarter final yoo ṣe lọ:
Zambia vs Senegal - Ọjọru laago mẹfa ni papa ìṣeré
Mohamed V n'ilu Casablanca.
Morocco vs Botswana - Ọjọru laago mẹsan-an alẹ́ ni
papa ìṣeré Moulay Abdellah, n'ilu Rabat)
Nigeria vs Cameroon - Ọjọbọ, laago mẹ́fà irọlẹ ni papa
ìṣeré Mohamed V, n'ilu Casablanca)
South Africa vs Tunisia -Ọjọbọ, laago mẹsan-an alẹ ni papa ìṣeré
Moulay El Hassan n'ilu Rabat.
Nkan to yẹ ki o mọ̀ nipa orile-ede kọọkan ti yoo gbá quarter final;
Copper Queens ti Zambia ati Teranga Lionesses ti
Senegal
Igba akọkọ niyii ti ẹgbẹ agbabọọlu orile-ede mejeeji
tayọ kọjá ipele akọkọ idije WAFCON, group stage. Ipele yii ni wọn ti má n pin
orile-ede kọọkan si isọri.
Nitori naa, o
nira diẹ lati sọ àsọtẹ́lẹ̀ nipa ẹni ti yoo bori ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn lọjọru.
Atlas Lionesses ti The Mares ti Morocco ati Botswana
Lootọ lo jẹ pe igba akọkọ niyii ti Botswana n kopa ni
idije Wafcon, amọ wọn ko ṣe e fi ọwọ rọ sẹyin.
Ẹwẹ, orile-ede Morocco naa to gbalejo idije ti ọdún
yii naa ko kẹ̀rẹ̀.
Wọn ko padanu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kankan lati igba ti idije
naa ti bẹ̀rẹ̀ ni isọri A ti wọn wa.
Ayo marun-un ni wọn ti gba wọlé. Eyi tó mu ki wọn ṣe
ipo kinni ni isọri wọn.
Super Falcons ti Naijiria ati Indomitable Lionesses ti
Cameroon
Igba mẹsan-an ni ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin Naijiria,
Super Falcons, ti gba ife idije WAFCON, ninu igba mọkanla to ti waye. Lọwọ lọwọ,
ọwọ wọn ni ife naa wa lẹyin ti wọn bori lọdun 2018.
Ninu idije ti ọdun yii, Super Falcons fidirẹmi ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀
wọn àkọ́kọ́, pẹlubi South Africa ṣe lù
wọn ni 2-1.
Wọn padà bori ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn keji, nigba ti wọn
lu Botswana ni 2-0.
Bakan naa ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn kẹta, àmì ayo 4-0 ni wọn
lu Burundi.
Cameroon ni wọn o koju ni ipele quarter final. Ẹgbẹ́
agbabọọlu mejeeji kii ṣe àjòjì si ara wọn. Ipade wọn lori pápá ma n dà bi ti
erin meji ni.
Àwọn mejeeji lo koju ara wọn ni ipele quarter final lọdun
2016, n'ilu Yaounde lorilẹ èdè Cameroon.
Ẹgbẹ agbabọọlu Indomitable Lionesses naa ko ṣe fi ọwọ
yẹpẹrẹ mu lagbo bọọlu obìnrin ni Africa, sugbọn wọn ko ti laafaani lati gba ife
WAFCON ri lati igba ti wọn ti n kopa.
Banfana Banfana ti South Africa ati Carthage Eagles ti
Tunisia
Ẹgbẹ agbabọọlu Banfana Banfana ti South Africa, lo ṣe
ipo keji ni aṣekagba idije WAFCON lọdun 2018.
Lati ibẹrẹ idije ti ọdun yii si ni wọn ti n tayọ.
Wọn ko kuna idije kankan ní isọri C ti wọn wa. Àwọn lo
si wa ni ipo kinni pẹlu àmì mẹsan-án.
Ni iwoye eeyan, Banfana Banfana lágbára jù Chartage
Eagles ti Tunisia lọ l'ori pápá.
Amọ ohunkóhun lo le sẹlẹ ninu idije bọọlu.
Àwọn ẹgbẹ́ agbabọọlu to ba yege ni ipele quarter
finals, ni yoo lanfaani lati kopa ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni agbaye, ti yoo
waye lọdun 2023 ni orile-ede Australia ati New Zealand.
Nàìjíría wọ quarter finals, orílẹ̀-èdè mẹ́rin já dànù ní WAFCON 2022
Oríṣun àwòrán, caf_online
Ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ti Naijiria ti wọ ipele quarter
finals, ni idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco.
Eyi waye lẹyin ti wọn na Burundi ni ami ayo mẹrin si odo lọjọ
Aiku
Abala akọkọ, Group stage, idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa
fun ọdún 2022, WAFCON 2022, ti pari bayii lẹyin awọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to waye lọjọ
Aiku.
Super Falcons ti Naijiria na Swallow ti Burundi, South
Africa na Botswana ni ami ayo kan si odo.
Ni ìpín C ti Naijiria wa, awọn lo wa ni ipo keji ni ori
tabili igbelewọn pẹlu ami mẹfa. South Africa lo wa ni ipo kinni pẹlu ami mẹsan-an.
Super Falcons ti bọ si ipele quarter finals bayii.
Ipo ti orile-ede kọọkan wa niyii lori tabili
igbelewọn:
Oríṣun àwòrán, caf_online
Oríṣun àwòrán, caf_online
Oríṣun àwòrán, caf_online
Bi idije quarter finals yoo ṣe lọ niyii:
Oríṣun àwòrán, caf_online
Morocco vs Botswana
Zambia vs Senegal
South Africa vs Tunisia
Cameroon vs Nigeria
Àwọn ẹgbẹ́ agbabọọlu to ti já kuro ninu idije naa ni:
Burundi, Uganda, Togo ati Burkina Faso.
Naijiria na ẹgbẹ́ agbabọọlu ti orile-ede Botswana nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn to waye l'Ọjọbọ.
Onumonu Chukwufunmnaya lo kọ́kọ́ gba bọọlu sinu awọn Botswana nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa wọ iṣẹju mọkanlelogun ni abala akọkọ.
Ko pẹ ti wọn wọle fun abala keji, ni Christy Ucheibe fi ọba le ni iṣẹju kẹtadinlaadọta.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yatọ pupọ si ti ọjọ Aje, paapaa nipa bi awọn agbabọọlu naa ṣe jara mọ isẹ tọkàntọkàn, ati awọn igbeṣẹ ti olukọni wọn, Randy Waldrum gbe nipa awọn agbabọọlu to fi bẹ̀rẹ, ati awọn to pada rọpo.
Bo tilẹ jẹ pe Super Falcons bori, wọn ṣi nilo ki wọn o na ẹgbẹ́ agbabọọlu orile-ede Burundi ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn lọjọ Aiku, ki wọn to o le bọ si ipele quarter finals.
Ko tii daju pe Botswana naa yoo bọ si ipele naa, botilẹ jẹ pe wọn na Burundi ni ami ayo mẹrin si meji, ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́.
Oríṣun àwòrán, @CAF
Wo àwọn agbábọ̀ọ́lù Nàìjíríà tí yóò kojú Botswana lálẹ́ òní
Oríṣun àwòrán, NFF
Ẹgbẹ agbabọọlu orile-ede Naijiria yoo gba ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn keji lonii ninu idije wafcon 2022 to n waye ni Morocco.
Àwọn agbabọọlu to yoo kopa niyii:
Chiamaka Nnadozie
Osinachi Ohale
Onome Ebi
Payne Antionette
Onumonu Chukwufunmnaya
Rita Chikwelu
Ngozi Okeoghene
Rasheedat Ajibade
Franscisca Ordega
Halimatu Ayinde
Alozie Chinwen
South Africa, ti wọ ìpele Quarter Finals ní WAFCON 2022
Oríṣun àwòrán, Cafwomenonline
Ẹgbẹ agbabọọlu Banfana Banfana ti orile-ede South Africa, ti tayọ si ipele quarter finals, ninu idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco.
Eyi waye lẹyin ti wọn bori ni ifẹsẹwọnsẹ meji akọkọ ni ipin C.
Orile-ede Naijiria ni wọn kọ́kọ́ lù ni ami ayo meji si ẹyọkan lọjọ Aje.
Wọn tun lu Burundi ni ami ayo mẹta si ẹyọkan lọjọbọ. Igba akọkọ niyii ti awọn agbabọọlu obìnrin ti orile-ede Burundi n kopa ni idije WAFCON.
Wo owó gọbọi tí Super Falcons Nàìjíríà yóò gbà bí wọ́n bá gba ife ẹ̀yẹ WAFCON ọdún yìí, WAFCON: CAF kéde àfikún ẹ̀bùn owó fún àwọn orílẹ̀èdè tó ń kópa ní ìdíje WAFCON ọdún yìí
Oríṣun àwòrán, caf
Ajọ bọọlu nilẹ Afirica ti fi kun iye owo ti awọn
agbabọọ̀lu obinrin to n kopa nibi idije ife ẹyẹ WAFCON lorilẹede Morocco yoo
gba.
Aarẹ ajọ ere bọọlu nilẹ Afirika,Ọmọwe Patrice Motsepe lo kede afikun naa eyi
ti yoo to ida aadọjọ ninu ọgọrun (150%).
Idije naa bẹrẹ ni ilu Rabat lọjọ Satide, ọdọ
keji oṣu keje ọdun 2022 lorilẹede Morocco.
Pẹlu afikun yii, iye owo tawọn orilẹede to
kopa yoo gba ti kuro ni ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹẹdẹgbẹrun o din mẹwaa dọla
(USD975, 000) si miliọnu meji o le ẹgbẹrun lọna irinwo dọla (USD 2, 400,000)
Aarẹ ajọ bọọlu nilẹ Afirika, CAF ati igbimọ iṣakoso
ajọ naa ni asiko fifi ọwọ gbẹfẹ mu ọrọ bọọlu awọn obinrin ati idagbasoke rẹ ni
Afirika ti di ọrọ itan.
Orilẹede to ba gba ife ẹyẹ idijẹ WAFCON tọdun
yii yoo gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta dọla (USD 500, 000) dipo ẹgbẹrun lọna igba
ti wọn n gba tẹlẹ.
Orilẹede to ba gba ipo keji yoo gba ẹgbẹrun lọna
ọọdunrun dọla (USD 300, 000).
Gbogbo awọn orilẹede to ba wọ ipele to kangun
si aṣekagba yoo gba ẹbun owo ẹgbẹrun lọna igba ati marundinlọgbọn dọla (USD
225, 000) dipo ẹgbẹrun marundinlaadoje dọla (USD 125, 000) ti wọn n gba tẹlẹ.
Ṣé Super Falcons yóò le fi Botswana tí kò kópa rí ní wafcon ra iyì padà?, Nigeria vs Botswana: Ṣé Super Falcons yóò le fi Botswana tí kò kópa rí ní wafcon ra iyì padà?
Ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ti Naijiria, yoo tẹsiwaju lonii, ninu idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa, wafcon 2022, to n lọ lọwọ ni Morocco.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ti yoo waye pẹlu orile-ede Botswana, ni anfaani kan ṣoṣo ti Naijiria ni, lati ṣe atunṣe kikuna ti wọn kùnà lọjọ Aje.
Ọjọ Aje ni wọn gba ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn akọkọ pẹlu Banfana Banfana ti South Africa, ti wọn si na wọn ni ami ayo kan si ẹyọkan.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu ẹgbẹ́ agbabọọlu Mares ti Botswana, si ni yoo sọ boya Naijiria yoo lọ si ipele quarter finals, tabi boya wọn n pada sile.
Aṣeyọri nla ni Botswana fi bẹ̀rẹ idije wọn ni wafcon 2022, botilẹ jẹ wi pe igba akọkọ niyii ti wọn n kopa ninu idije naa. Ami ayo mẹrin si meji ni wọn lu Burundi.
Àwọn si lo n leke lori tabili igbelewọn idije wafcon 2022, ni ìpín C.
Ti wọn ba si tun lu Naijiria, a jẹ pe wọn o ni anfaani lati wa lara orile-ede mẹjọ ti yoo tayọ si ipele quater finals.
Papa iṣere Prince Moulay El Hassan, n'ilu Rabat, ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo ti waye laago mẹsan alẹ.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yii kan naa ni igba akọkọ ti Super Falcons ati Mares yoo koju ara wọn.
Ọjọru ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons kede pe Ogbontarigi agbabọọlu, Asisat Oshoala, ko ni le kopa mọ ni wafcon 2022.
Eyi ko ṣẹyin ifarapa to ni lasiko ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu South Africa lọjọ Aje. Sugbọn, olukọni wọn, Randy Waldrum ti sọ pe eyi ko nii di aṣeyọri Falcons lọwọ.
O sọ nibi ipade akọroyin lọjọru pe 'atunto ati atunṣe ti wa lẹyin ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu South Africa'.
Wọ́n ti yọ Barbra banda, agbábọ́ọ̀lù Zambia kúró níbi ìdíje WAFCON
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ti juwe ọna
ile fun agbabọọlu orilẹede Zambia, Barbra Banda nibi idije WAFCON 2022 to n lọ
lọwọ lorilẹede Morocco.
Awọn alaṣẹ ajọ
ere bọọlu ni Zambia ṣalaye pe lile ti wọn le agbabọọlu naa ko ṣẹyin bi
ariyanjiyan ṣe n waye lori iru ẹya eeyan to jẹ boya akọ ni tabi abo.
Idije WAFCON jẹ
idije bọọlu fun awọn agbabọọlu obinrin ni Afirika ṣugbọn ariyanjiyan n lọ lori
boya ki wọn kaa mọ ẹya abo tabi akọ.
Aarẹ ajọ bọọlu
Zambia, Andrew Kamanga fi idi iroyin naa mulẹ.
Ohun tó yọ ọwọ́ Asisat Osoala láwo WAFCON rèé...
Oríṣun àwòrán, other
Ajọ ere bọọlu lorilẹede NAijiria, NFF sọ pe grade 2 medical collateral ligament strain ni ohun to n yọ ọ lẹnu ti ko fi nii lee gba bọọlu ninu idije WAFCON ọdun yii mọ.
Igba meji ni Oshoala farapa lasiko ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn, ko to di pe ko ba wọn parí.
Àjọ NFF sọ loju opo Twitter rẹ lọ san Ọjọ́ru pe Ọjọbọ ni yoo pada si orile-ede Spain.
Nibẹ lo tí n gba bọọlu fun ẹgbẹ́ agbabọọlu Barcelona. Sugbọn ṣa, olukọni ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons, Randy Waldrum, sọ fun awọn akọroyin pe àìsí Oshoala, ko nii mu idiwọ tabi ifasẹyin ba wọn ni WAFCON 2022.
Asisat Oshoala, atamátàsé agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà ti já kúrò ní ìdíje WAFCON 2022, WAFCON 2022: Asisat Oshoala, atamátàsé agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà ti já kúrò ní ìdíje WAFCON 2022 tó ń lọ lọ́wọ́ ní Morocco
Oríṣun àwòrán, nigeria football association
Ogbontarigi agbabọọlu obìnrin, to tun jẹ atamatase, Asisat Oshoala ti ja kuro ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco.
Gẹ́gẹ́ bi ikede ti ajọ bọọlu Naijiria fi sita, eyi ko sẹ́yìn ifarapa to ni lasiko ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Super Falcons pẹlu Banfana Banfana ti South Africa lọjọ Aje.
Àmì ayò 1-0 ni Senegal na Burkina Faso ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ WAFCON 2022
Oríṣun àwòrán, Cafwomenonline
Ẹgbẹ agbabọọlu Senegal na akẹẹgbẹ rẹ lati Burkina Faso ni ami ayo kan si odo níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ to waye ni papa ìṣeré Prince Moulay Abdellah, n'ilu Rabat.
Ọmi odo ni wọn ta ni abala akọkọ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa, sugbọn nigba ti idije naa wọ isẹju mẹrinlelọgọrin, agbabọọlu Korkal Fall gba bọọlu si àwọ̀n Burkina Babes, eyi to mu ki o jẹ 1-0.
Saaju ni ẹgbẹ́ agbabọọlu Morocco to n gbalejo idije WAFCON 2022, na Burkina Faso ni ami ayo kan si odo níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ akọkọ to ṣíde idije tọdun yii lọjọ Satide.
Igba kejì re e ti Burkina Faso n kopa ni idije bọọlu awọn obinrin ni Afrika, lẹyin ọdún mejilelogun sẹ́yìn ti wọn kọkọ kopa.
Ọjọ Ẹti ni wọn o koju Uganda ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn to kẹhin ni abala akọkọ idije yii. Àwọn ẹgbẹ́ agbabọọlu ti ami wọn ba pọju ni yoo tayọ bọ si ipele quater finals.
Senegal si ni orile-ede àkọ́kọ́ to ti bọ si ipele naa bayii.
Àmì ayò 2-1 ni South Africa fi ṣíde ìyà fún Naijiria ní wafcon 2022
Oríṣun àwòrán, Getty Images
ami ayo meji si ẹyọkan ti ẹgbẹ́ agbabọọlu Banyana Banyana ti South Africa, fi lu agbabọọlu Naijiria, Super Falcons, nibi ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn to waye ni ọjọ́ Aje.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni àkọ́kọ́ ti ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji gbá, ninu idije bọọlu alafẹsẹgba ti awọn obinrin, to ni waye lorile-ede Morocco. Agbabọọlu South Africa, Jermaine Seopsenwe, lo gba bọọlu si àwọn Super Falcons, nigba ti idije naa wọ isẹju mọkanlelọgọta.
Ko ju isẹju meji lọ nigba ti Hildah Tholakele Magaia tun gba bọọlu miran si àwọ̀n Super Falcons. Sugbọn nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ isẹju mọkanlelaadọrun, agbabọọlu Super Falcons, Rasheedat Ajibade, gba bọọlu sinu awọn South Africa.
Àwọn nkan mii to sẹlẹ nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa Igba méjì ni Asisat Oshoala farapa nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa Agbabọọlu Naijiria, Alozie Michele Chinwen, gba kaadi alawọ ofefe (yellow) nigba ti idije wọ iṣẹju mẹrinlelogoji.
Àmì ayò 2-0 ni South Africa fi ṣíde ìyà fún Nàìjíríà ní wafcon 2022
Oríṣun àwòrán, caf
Àmì ayò 2-0 ni South Africa fi ṣíde ìyà fún Naijiria ní wafcon 2022 Ko din ni ami ayo meji ti ẹgbẹ́ agbabọọlu Banyana Banyana ti South Africa, fi lu agbabọọlu Naijiria, Super Falcons, nibi ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn to waye ni ọjọ́ Aje.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni àkọ́kọ́ ti ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji gbá, ninu idije bọọlu alafẹsẹgba ti awọn obinrin, to ni waye lorile-ede Morocco.
Agbabọọlu South Africa, Jermaine Seopsenwe, lo gba bọọlu si àwọn Super Falcons, nigba ti idije naa wọ isẹju mọkanlelọgọta. Ko ju isẹju meji lọ nigba ti Hildah Tholakele Magaia tun gba bọọlu miran si àwọ̀n Super Falcons.
Àwọn nkan mii to sẹlẹ nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa Igba méjì ni Asisat Oshoala farapa nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa Agbabọọlu Naijiria, Alozie Michele Chinwen, gba kaadi alawọ ofefe (yellow) nigba ti idije wọ iṣẹju mẹrinlelogoji.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ gbéra sọ láàrín South Africa àti Nàìjíríà
Oríṣun àwòrán, other
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ akọkọ fun ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons ti Naijiria ni idije WAFCON 2022 ti n waye ni papa ìṣeré Prince Heritier Maulay El Hassan, n'ilu Rabat, lorile-ede Morocco.
Ni deede agogo mẹfa irọlẹ ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa bẹ̀rẹ̀. Lati ìbẹ̀rẹ̀ ni idije naa ti n gbóná, pẹlu bí ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji ṣe ń gbiyanju lati gba bọọlu sinu awọn.
Idije naa ko tii ju iṣẹju mẹ́jọ lọ nigba ti ọmọ ẹgbẹ́ agbabọọlu orile-ede South Africa kan ṣe Asisat Oshoala léṣe.