Eedris Abdulkareem tó kọ ‘Naijiria Jagajaga’ ń kojú àìsàn kídìnrín tí kò ṣiṣẹ́ mọ́

Oríṣun àwòrán, Google
Olorin takasufẹ, Eedris Abdulkareem to kọ orin ‘Naijiria jagajaga’ ti kede pe oun koju aisan kidinrin to kọ iṣẹ silẹ , eleyii ti awọn oloyinbo n pe ni ‘kidney failure.’
Loju opo ikansiraẹni Instagram rẹ ni agbẹnusọ rẹ, Myke Pam ti kede idojuko naa.
Pam ni ipari Oṣu keje yii ni wọn yoo siṣẹ abẹ fun Abdulkareem, ti o si kesi awọn ọmọ Naijiria lati maṣe gbagbe rẹ ninu adura lasiko yii.
Abdulkareem to tun jẹ ajafẹtọ ni Naijiria ni wọn ni o ti n gba iwosan dialysis lati igba ti aisan naa ti han si gbangba.
Amọ o fikun un pe ki awọn eniyan ma mikan nitori ohun gbogbo ti wa ti yoo mu ki iṣẹ abẹ naa lọ ni irọwọrọsẹ, ti yoo si dide laipẹ.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ mọlẹbi rẹ kan to ṣetan lati yọnda kidinrin rẹ silẹ lati fi rọpọ ti Abdulkareem to ti kọ iṣẹ silẹ.
Agbẹnusọ rẹ naa ni ki awọn ololufẹ rẹ ma mikan nitori kokoko ni ara rẹ le, ti yoo si pada sipo laipẹ.
O rọ awọn eniyan lati maṣe dawọ adura duro fun un nitori o nilo rẹ lasiko yii.
Wọn ni to ba ṣe n lọ ni awọn yoo maa fi to awọn ọmọ Naijiria ati gbogbo ololufẹ rẹ leti, pẹ̣lu adura wi pe aabo Ọlọrun yoo daju lori gbogbo eniyan.
Kete naa ni awọn ololufẹ rẹ ti bẹrẹ si ni fi ifẹ ranṣẹ si, ti wọn si n gbadura fun un pe alaafia yoo jẹ ti rẹ, ti wọn si kesi pe ko mu ara le.












