Àwọn agbéṣùmọ̀mí ṣèkọlù sí ọkọ̀ Buhari, pa ọlọ́pàá méjì ní Katsina

Ọkọ̀ Ààrẹ Buhari

Iléeṣẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tí àwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ọkọ̀ ikọ̀ Ààrẹ Muhammadu Buhari tó ń lọ sí ìlú Daura tíí ṣe ìlú abínibí Ààrẹ ní ìpínlẹ̀ Katsina ṣaájú ayẹyẹ ọdún Iléyá.

Ní agbègbè Dutsinma, ìpínlẹ̀ Katsina ni àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ti ṣe ìkọlù sí àwọn ènìyàn náà.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ olùrànlọ́wọ́ agbẹnusọ Ààrẹ Buhari, Garba Shehu ní lọpẹ́lọpẹ́ àwọn ọmọ ogun, ọlọ́pàá àti ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó kojú àwọn àwọn agbéṣùmọ̀mí náà.

Shehu ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà ṣe gudugudu méje àti yàyà mẹ́fà tí wọ́n sì lé àwọn agbéṣùmọ̀mí náà wọ igbó jìnà.

Ó fi kun pé àwọn kò pàdánù ẹ̀mí kankan nínú ìkọlà náà àmọ́ àwọn ọlọ́pàá méjì fara ṣèṣe nínú ìkọlù náà tí wọ́n sì ti ń gba ìtọ́jú.

Ó ní gbogbo àwọn ènìyàn yòókù ló balẹ̀ sí Daura ní ayọ̀ àti àláfíà.

Ẹni tí ìkọlù náà ṣojú rẹ̀ ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí

Ó ṣojú mi kòró tí ìkọlù náà ṣojú rẹ̀ sọ wí pé nígbà tí àwọn ń lọ sí Dutsinma láti Kankara ní àwọn kàn déédé rí àwọn agbébọn tí wọ́n ya wọ títì lórí ọ̀kadà.

Ó ní àwọn agbébọn náà pọ̀ púpọ̀ tí àwọn sì sáré sí abúlé Turare láti sá àsálà fún ẹ̀mí ara àwọn kí àwọn ológun tó wá dóòlà àwọn kúrò níbẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Katsina, Gambo Isah ti kéde wí pé igbákejì Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Katsina, Aminu Umar ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ àwọn agbébọn ní ìpínlẹ̀ náà.

Aminu Umar ni ọ̀gá ọlọ́pàá ní agbègbè Dutsinma ní ìpínlẹ̀ Katsina ní agbègbè ibi tí àwọn agbéṣùmọ̀mí ti ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ Ààrẹ Muhammadu Buhari.

Aminu Umar

Oríṣun àwòrán, @Katsina Polics

Umar ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ rẹ̀ nígbà tó ṣáájú ikọ̀ ọlọ́pàá láti lọ gbọn inú igbó Zakka ní ìjọba ìbílẹ̀ Safana yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ lọ́wọ́ àwọn agbébọn.

Isah ní kò dín ní àwọn ọ̀ọ́dúnrún agbébọn ni Umar àti àwọn ọlọ́pàá náà kojú àmọ́ ó ṣeni lá]àánú wí pé Umar àti ọlọ́pàá mìíràn pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjà náà.